Ìranraẹnilọ́wọ́

(Àtúnjúwe láti Iranraenilowo (Ojo))

Self-Help

Iranraenilowo

Oludare Olajubu

Afolabi ojo Ìwé Àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá tí Olóyè Olúdáre Ọlájubù jẹ́ Olóòtu, Ojú-iwé 1-11, Ikẹja; Longman Nigeria Limited, 1975.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Afọlabí Òjó. Àṣà Ìran-ara-ẹni-lọ́wọ́; Ojú-iwé 158-164.

Gẹ́gẹ́ bí gbogbo wá ṣe mọ̀ láti ọjọ́ tí aláyé ti dáyé ni àwọn èèyàn ti ńran ara wọn lọ́wọ́. Bí a ba nsọrọ nipa ọjọ tí alaye ti dáyé àwọn ti nka ìwé Bíbélì lára wa á fẹ́ mú ọkàn wọn lọ si àkókò tó jẹ pe ọkùnrin kan ṣoṣo ló wa lórílẹ̀ èdè ayé yìí, èyí ni Adamu. Mo rò pé a ò mọ gbogbo iṣẹ tó ṣe nínú ọgbà tí ó wà, ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ẹni ti ó mọ oúnjẹẹ́ jẹ nib í èèyan bíi tiwa ni, ó dáni lójú wí pé yíó máa gbìyànjú láti fi ọwọ ká èso igi jẹ ni. Ounjẹ sì nìyí kì í dùn tó bẹ́ẹ̀ tó bá ṣe èèyàn nìkan ṣoṣo ló ńjẹ́ ẹ́ láarọ̀, lọ́sàán àti lálẹ́ láti ọjọ kan dé ọ̀sẹ̀ kan, dé oṣù kan, dé ọdún kan. Itan Bíbélì náà sọ fun wa pé nígbà tí o bùṣe, Olúwa fi olùrànlọ́wọ́ kan jíǹkí rẹ̀, eléyìí náà ni obinrin tí a ńpè ni Éèfà. O dà bí ẹni pe inú ọgbà Ídẹ́nì náà gbádùn si i lẹ́hin tí àwọn méjèèjì ti wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n oríṣi ìrànlọ́wọ́ ti wọ́n rí náà kì í ṣe nkan ti kò ní ní ìfàsẹ̀hìn-in tirẹ̀. Mo fi ìyókù si ọkàn ẹ̀yin tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìwée ti Bíbélì.

Ohun tí mo fẹ fàyọ nínú ifisíwájú ọ̀rọ̀ mi yìí ni pé ọwó kan kò gbé ẹrù dé orí, a sì ti mọ̀ dájú pé bi ọwọ́ ọmọdé kò ṣe tó pẹpẹ bákan náà ní ọwọ́ àgbàlagbà kò ṣe wọ akèrèbè. Bẹ́ẹ̀ náà ní àwọn olóye èèyàn ṣe máa ńsọ́ fún wa nígbà gbogbo pé ‘òsì wẹ ọ̀tun ọ̀tún wẹ òsì òun ni ọwọ́ fi ńmọ́’. Lọ́rọ̀ kan àwọn èèyàn ilẹ̀ẹ Yorùbá ti gbà á ni àṣà kan pàtàkí pé a ní láti máa ran ara wa lọ́wọ́, kó tó dip é a lè da ohunkóhun oníyebíye kankan ṣe. OríṣiríṣI iṣẹ́ ìran-ara-ẹni-lọ́wọ́ ni ó wà. Ní ìṣẹ̀dálẹ̀ẹ wa àwọn ọdọmọkunrin tó bá ti ńfẹ́ aya, wọn a máa ran òbí àfẹ́sọnà wọn lọ́wọ́. Kó tó tilẹ̀ dip e a bẹrẹ si í ná owó, eeyan yíó tin a ara ṣáájú-ṣáájú. Èyí nip é àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lè máa bá àna wọn lọ sí oko láti kọlẹ̀ tàbí láti tun ohun ọgbin-in wọn ṣe. Bákannáà ni wọn nṣe ìrànlọ́wọ́ nínú ilé láti kọ́ ilé tuntun tàbí láti tún ilé tí ó bá mbàjẹ́ ṣe, bóyá o ńjò ni, tàbí iganna rẹ̀ ńfẹ́ ki a túbọ̀ gbe oun dúró dáadáa. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, nigbakugbà tí wọn bá ti ńṣe irú iṣẹ́ bi eléyìí kìí ṣe ẹni tí o ńfẹ́ àfẹsọ́nà nìkan ṣoṣo lo ńṣe iṣẹ́ bí eléyìí....