Iretiola Doyle
Ìrètíọlá Doyle (tí orúkọ ìbí jẹ́ Ìrètíọlá Olúṣọlá Àyìnkẹ́ ) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2]
Ìrètíọlá Doyle | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ìrètíọlá Olúṣọlá Àyìnkẹ́ ọjọ́ 3 Oṣù Karùn-ún Ọdún 1967 Ìpínlẹ̀ Òndó |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Yunifásitì ti Jos |
Iṣẹ́ | òṣèré |
Notable work | The Wedding Party (2016) |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeA bí Doyle ní ọjọ́ 3 Oṣù Karùn-ún Ọdún 1967 ní Ìpínlẹ̀ Òndó ṣùgbọ́n ó lo àwọn ìgbà èwe rẹ̀ pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ ní Boston, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́hìn tí ó padà sí Nàìjíríà, ó lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ Christ's School ní Adó Èkìtì ó sì parí ilé-ìwé gíga Yunifásitì ti Jos pẹ̀lú oyè ní Eré Tíátà.[3]
Iṣẹ́ ìṣe
àtúnṣeFún ìgbà tó ti lé ní ogún ọdún ní ìdi iṣẹ́ eré ìdárayá ti Nàìjíríà, Ìrètíọlá ti ní lórúkọ rẹ̀, àwọn iṣẹ́ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan láti orí ìpele dé tẹlifíṣọ̀nù àti fíìmù.
Ìrètíọlá Doyle jẹ́ ònkọ̀wé, òṣèré, olùgbéréjáde àti atọ́kùn ètò. Ó ṣe àgbéjáde àti àgbékalẹ̀ ètò kan tí ó dá lóri oge ṣíṣe àti ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Oge With Iretiola" [4] fún ọdún mẹ́wàá, ó sì tún ṣe atọ́kùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ètò tẹlifíṣọ̀nù bíi Morning Ride pẹ̀lu Today lóri ìkànnì STV àti Nimasa This Week lóri ìkànnì Channels TV .[5] Ó jẹ́ ònkọ̀wé, ó sì ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré.
Ó ti rí yíyàn lẹ́ẹ̀kan rí fún ẹ̀ka ti òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Reel Awards ní ọdún 1998 fún ipa rẹ̀ nínu fíìmù All About Eré àti lẹ́ẹ̀mejì fún ẹ̀ka ti òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ AMAA Awards ní ọdún 2007 àti 2009 fún àwọn ipa rẹ̀ nínu Sitanda àti Across The Niger. Wọ́n sì tún ti kéde rẹ̀ rí gẹ́gẹ́ bi òṣèré tí ó dára jùlọ ní ipa asíwájú níbi ayẹyẹ GIAMA Awards tí ó wáyé ní ìlú Houston Texas ní ọdún 2013, àti gẹ́gẹ́ bi òṣèré tí ó dára jùlọ ní ipa asíwájú níbi ayẹyẹ Nollywood Movie Awards ti ọdún 2014 fún ipa rẹ̀ ti Ovo, nínu eré aṣaragágá Torn. Iṣé yìí tún fun lánfàní yíyàn fún àmì ẹ̀yẹòṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó dára jùlọ ní ọdún 2015 níbi African Magic Viewers' Choice Awards. Wọ́n tún yàán fún àmì ẹ̀yẹ míràn ní ọdún 2016 fún ipa asíwájú tí ó kó gẹ́gẹ́ bi Dr. Elizabeth nínu fíìmù Ebony Life aláṣeyọrí kan ti ọdún 2015 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ FIFTY.[6]
Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀
àtúnṣeFíìmù
àtúnṣe- Across the Niger
- Sitanda
- Torn
- The Therapist (2015)[7]
- Fifty (2015)
- The Arbitration (2016)
- The Wedding Party (2016)
- Dinner (2016)
- The Wedding Party 2 (2017)
- Merry Men: The Real Yoruba Demons (2018)
- Kasanova (2019)
- Merry Men 2(2019)
Eré orí tẹlifíṣọ̀ọ̀nù
àtúnṣe- Tinsel
- For Coloured Girls (2011) [upper-alpha 1]
- Gidi Up (2014–present).
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Patrick took his time convincing me to date him –Iretiola Doyle". dailyindependentnig.com. Retrieved 12 August 2014.
- ↑ "N Saturday Celebrity Interview: In Her 40s and Proud, Tinsel Star Actress Ireti Doyle Steps into Her Own! An Intimate Interview on Teenage Pregnancy, Motherhood & Family". bellanaija.com. Retrieved 12 August 2014.
- ↑ "HOW MY BOSS BECAME MY HUSBAND..........IRETIOLA OLUSOLA AYINKE DOYLE". Modern Ghana. November 2, 2008. Retrieved October 25, 2014.
- ↑ "Oge with Iretiola". TVGuide.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2017-12-22.
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2017-08-11. Retrieved 2020-10-30.
- ↑ "IRETI DOYLE – Fifty". fiftythemovie.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2017-12-05. Retrieved 2017-12-22.
- ↑ "Monalisa Chinda, Lisa Omorodion, Ireti Doyle star in upcoming movie". Pulse Nigeria. Chidumga Izuzu. 19 May 2015. Archived from the original on 20 May 2015. Retrieved 19 May 2015.
Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref>
tags exist for a group named "upper-alpha", but no corresponding <references group="upper-alpha"/>
tag was found