Ìsèdálẹ̀ Ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà

(Àtúnjúwe láti Isedale Ilu Ijebu-Jesa)

ÌTÀN ÌSÈDÁLẸ̀ ÌLÚ ÌJẸ̀LÚ-JÈSÀ

Oríṣìíríṣìí ìtàn àtẹnudẹ́nu ni a ti gbọ́ nípa ìlú Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà, ọ̀rọ̀ òkèèrè sì nìyí, bí kò bá lé yóò dín.

Ọ̀kan nínú àwọn ìtàn náà sọ pé; Ọwà Iléṣà kìíní Ajíbógun àti Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà kìíni, Agígírí jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò. Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ẹ̀gbọ́n tí Ọwá sì jẹ́ àbúrò. Bákan náà, tẹ̀gbón tàbúrò ni ìyá tí ó bí wọn. Láti ọmọ omún ni ìyá Ajíbógun Ọwá Iléṣà ti kú ìyá Agígírì tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ ló wò ó dàgbà, ọmún rẹ̀ ló sì mún dàgbà. Èyí ló mú kí wọn di kòrí-kòsùn ara wọn láti kékeré wá, wọn kì í sìí yara wọn bí ó ti wù kí ó rí.

Ìgbà tí wọ́n dàgbà tán, tí ó di wí pé wọ́n ń wá ibùjókòó tí wọn yóò tẹ̀dó, àwọn méjèéji – Agírírí àti Ajíbógun yìí náà ló jìjọ dìde láti Ilé-Ifẹ. Wọ́n wá sí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà láti dó sí kí wọn lè ni àyè ìjọba tiwọn. Ajíbógun dúró níbi tí a ń pè ní Iléṣa lónií yìí, òun sì ni Ọwá Iléṣà kìíní. Agígírí rìn díẹ̀ síwájú kí ó tó dúró. Lákòókó tí ó fi dúró yẹn, ó rò wí pé òun ti rìn jìnnà díẹ̀ sí àbúrò òun kò mọ̀ wí pé nǹkan ibùsọ̀ mẹ́fà péré ni òun tí ì rín. Ṣùgbọ́n, lọ́nà kìíní ná, kò fẹ́ rìn jìnnà púpọ̀ sí àbùrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu wọn pé àwọn kò gbọ́dọ̀ jìnnà sára wọn bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn méjèè jì kò jọ fẹ́ gbé ibùdó kan náà. Lọ́nà kejì, ò lè jẹ́ wí pé bóyá nítorí pé ẹsẹ̀ lásán tó fi rín nígbà náà tàbí nítorí pé agìnjù tó fi orí là nígbà náà ló ṣe rò wí pé ibi tí òun ti rìn ti nasẹ̀ díẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àbúrò òun lo ṣe dúró ni ibi tí a ń pè ní Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí.

Kì wọn tó kúrò ni Ifẹ̀, wọn mú àádọta ènìyàn pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ìgbà tí wọ́n dé Iléṣà ti Ajíbógun dúró, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fùn un ní ọgbọ̀n nínú àádọ́tà ènìyàn náà. Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n, òun lè dáàbò bo ara òun ó sí kó ogún tó kù wá sí ibùdo rè ni Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà. Ìdí nìyí tí a fi ń ki ìlú náà pé;

“Ijẹ̀ṣà ọgbọ̀n

Ìjẹ̀bú ogún

É sìí bó ṣe a rí

Kógún a parẹ́

mọ́gbọ̀n lára”

Ìtàn míràn sọ fún wa pé ọmọ ìyá ni Agígírí àti Ajíbógun ni Ìlé-Ifẹ̀. Ajíbógun ló lọ bomi òkun wá fún bàbá wọn - ọlọ́fin tí ó fọ́jú láti fi ṣe egbogi fún un kí ó lé ríran padà. Ó lọ, ó si bọ̀. Ṣùgbọ́n kí ó tó dé àwọn ènìyàn pàápàá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ rò wí pé ó ti kú, wọ́n sì ti fi bàbá wọn sílẹ̀ fún àwọn ìyàwó rẹ fún ìtọ́jú. Kí wọn tó lọ, wọ́n pín ẹrù tàbí ohùn ìní bàbá wọn láìfi nǹkan kan sílẹ̀ fún àbúro wọn – Ajíbógun. Ìgbà tí ó dé, ó bu omi òkun bọ̀, wọ́n lo omi yìí, bàbá wọn sì ríran.

Ojú Ajíbógun korò, inú sì bi pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti fi bàbá wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì kó ohun ìnú rẹ̀ lọ. Bàbá wọn rí i pé inú bí i, ó sì pàrọwà fún un. “Ọmọ àlè ní í rínú tí kì í bí, ọmọ àlè la ń bẹ̀ tí kì í gbọ́” báyìí ló gba ìpẹ́ (ẹ̀bẹ̀ bàbá rẹ̀. Ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ fún un ní idà kan – Idà Ajàṣẹ́gun ni, ó ni kí ó máa lé awọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ pé ibikíbi tí ó bá bá wọn, kí ọ bèèrè ohun ìní tirẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ pa wọ́n. Ajíbógun mú ìrin-àjò rẹ̀ pọ̀n, níkẹhìn ó bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní padà lọ́wọ́ wọn. Pẹ̀lú iṣẹ́gun lóri àwọn arákùnrin rẹ̀ yìí, kò ní ìtẹ́lórùn, òun náà fẹ́ ní ibùjókòó tí yóò ti máa ṣe ìjọba tirẹ̀.

Kò sí ohun tí ó dàbí ọmọ ìyá nítorí pé okùn ọmọ ìyá yi púpọ̀. Agígírí fẹ́ràn Ajíbógun ọwá Obòkun púpọ̀ nítorí pé ọmọ ìyá rẹ̀ ni. Bàyìí ni àwọn méjèèjì pèrè pọ̀. Láti fi Ilé - Ifẹ̀ sílẹ̀ kí wọn si wá ibùjókòó tuntun fún ara wọn níbi tí wọ́n yóò ti máa ṣe ìjọba wọn.

Itán sọ pé Ìbòkun ni wọ́n kọ́kọ́ dó sí kí wọn tó pínyà. Ọwá gba Òdùdu lọ, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà sì gba Ilékété lọ. Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Ẹẹ̀sún. Láti Eẹ̀sún ló ti wá sí Agóró. Agóró yìí ló dúro sí tí ó fi rán Lúmọ̀ogun akíkanju kan pàtàkì nínú wọn tí ó tẹ̀ lé e pé kí ó lọ sí iwájú díẹ̀ kí lọ wo ibi tí ilẹ̀ bá ti dára tí àwọn lè dó sí. Lúmọ̀ogun lẹ títí bí ẹ̀mí ìyá aláró kò padà. Àlọ rámirámi ni à ń rí ni ọ̀ran Lúmọ̀ogun, a kì í rábọ̀ rẹ̀. Ìgbà ti Agígírí kò rí Lúmọ̀ogun, ominú bẹ̀rẹ̀sí í kọ́ ọ́, bóyá ó ti sọnù tàbí bóyà ẹranko búburú ti pá jẹ. Inú fún ẹ̀dọ̀ fun ni ó fi bọ́ sọ́nà láti wá a títí tí òun ó fi rí i. Ibi tí wọ́n ti ń wá a kiri ni wọ́n ti gbúròó rẹ̀ ni ibì kan tí a ń pè ní Òkèníṣà ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí yìí.

Ìyàlẹ́nu ńláńlá lọ́ jẹ́ fún Agígírí láti rí Lúmọ̀ogun pẹ̀lú àwọn ọdẹ mélòó kan, Ó ti para pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdẹ wọ̀nyí ó sì ti gbàgbé iṣẹ́ tí wọ́n rán an nítorí tí ibẹ̀ dùn mọ́ ọn fún ọwọ́ ìfẹ́ tí àwọn ọḍẹ náà fi gbà á. Inú bí Agígírì ó sì gbé e bú. Ṣùgbọ́n ìsàlẹ̀ díẹ̀ ni òun náà bá dúro sí. Eléyìí ni wọ́n ṣe máa ń pe Òkènísà tí wọ́n dó sí yìí ní orí ayé. Wọ́n á ní “Òkènísà orí ayé”.

Agbo ilée Bajimọn ni Òkè - Ọjà ni Agígírí kọ́kọ́ fi ṣe ibùjókòó. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́hin èyí ni ó bá lọ jà ogun kan, ṣùgbọ́n kí ó tó padà dé, ọmọ rẹ̀ kan gvà ọ̀tẹ́ ńlá kan jọ tí ó fi jẹ́ wí pé Agígírì kò lè padà sí ilée Bajimọ mọ́. Ìlédè ni Agígírí kọjá sí láti lọ múlẹ̀ tuntun tí ó sì kọ̀lé sí Ìlédè náà ní ibi tí ààfin Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà wà títí di òní yìí. Ó jókòó nibẹ̀, ó sí pe àwọn tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí i wọ́n múra láti gbé ogun ti ọmọ rẹ̀ náà títí tí wọ́n fi ṣẹ́gun rẹ̀. Níkẹhìn, ọmọ náà túnúnbá fún bàbá rè ati àwọn ọmọ - ogun rẹ̀. “Ojù iná kọ́ ni ewùrà ń hurun”. Ẹnu ti ìgbín sì fib ú òrìṣà yóò fi lọlẹ̀ dandan ni” Ọmọ náà tẹríba fún bàbá rẹ̀ ó sì mọ̀ àgbà légbọ̀n-ọ́n.

Ìtàn míràn bí a ṣe tẹ Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà dò àti bí a ṣe mọ̀ ọ́n tàbí sọ orúkọ rẹ̀ ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni ìtàn àwọn akíkanjú tàbí akọni ọdẹ méje tí wọ́n gbéra láti Ifẹ láti ṣe ọdẹ lọ. Wọ́n ṣe ọdẹ títí ìgbá tí wọ́n dé ibi kan, olórí wọ́n fi ara pa. Wọ́n bẹ̀rẹ̀sí í tọ́júu rẹ̀ ìgbà tí wọ́n ṣe àkíyèsí wí pé ọgbẹ́ náà san díẹ̀, wọ́n tún gbéra, wọ́n mú ọ̀nà-àjò wọn pọ̀n. Ìgà tí wọ́n dé ibi tí a ń pè ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà lónìí yìí ni ẹ̀jẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀sí í sàn jáde láti ojú ọgbẹ́ ọkùnrin náà. Wọ́n bá dúró níbẹ̀ làti máa tọ́jú egbò náà, wọ́n sì dúró pẹ́ díẹ̀. Nígbẹ̀hìn, wón fi olórí wọ́n yìí síbẹ̀, wọ́n pa àgó kan síbẹ̀ kí ó máa gbé e. Ìgbà tí àwọn náà bá ṣọdẹ lọ títí, wọn a tún padà sọ́dọ̀ olórí wọn yìí láti wá tójùu rẹ̀ àti láti wá simi lálẹ́. Wọ́n ṣe àkíyèsí pé ibẹ̀ náà dára láti máa gbé ni wọ́n bá kúkú sọbẹ̀ dilẹ̣́. Ìgbà tí ara olórí wọn yá tán, tí wọ́n bá ṣọdẹ lọ títí, ibẹ̀ ni wọ́n ń fàbọ̀ sí títí tí ó fi ń gbòrò sí i. Orúkọ tí Olórí wọn – Agígírí sọ ibẹ̀ ni ÌJẸ̀BÚ nítorí pe ÌJẸ ni Ìjẹ̀ṣà máa ń pe Ẹ̀JẸ́. Nígbà tí ìyípadà sì ń dé tí ojú ń là á sí i ni wọ́n sọ orúkọ ìlú da ÌJẸ̀BÚ dípò Ìjẹ́bú tí wọ́n ti ń pè é tẹ́lẹ̀. Agígírì yí ni Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà kiíní, àwọn ìran ọlọ́dẹ méje ìjọ́sí ló di ìdílé méje tí ń jọ́ba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà títí di òní.

Ṣùgbọ́n Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń pe ìlú yìí rí nítorí ẹrẹ̀ tí ó ṣe ìdènà fún awọn Ọ̀yọ́ tí ó ń gbógun ti ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà nígbà kan. Ní ìlú náà ẹrẹ̀ ṣe ìdíwọ́ fún àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ ni wọ́n bá fi ń pe ìlú náà ni Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀. Ní ọdún 1926 ni ẹgbẹ́ tí a mọ̀ sí “Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà Progressive Union” yí orúkọ ìlú náà kúrò láti Ìjẹ̀bú - Ẹrẹ̀ sí Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nítorí pé ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ni Ìjẹ̀bú yìí wa.

A níláti tọ́ka sí i pé Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀ṣà yí lè ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú Ìjẹ̀bú ti Ìjẹ̀bù – Òde. Bí wọ́n kò tilẹ̀ ní orírun kan náà. Ìtàn lè xxxxxx pa wọ́n pọ̀ nipa àjọjẹ́ orúkọ, àjọṣe kankan lè máa sí láàárin wọn nígbà kan tí rí ju wí pé orúkọ yìí, tó wu ọ̀gbọ́ni kìíní Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà nígbà tí ó bá àbúrò rẹ̀ Ajíbógun lọ bòkun, wọ́n gba ọ̀nà Ìjẹ̀bú – Òde lọ. Ibẹ̀ ló ti mú orúkọ yìí bọ̀ tí ó sì fi sọ ilú tí òun náà tẹ̀dó.

Nínú àwọn ìtán òkè yí àwọn méjì ló sọ bí a ṣe sọ ìlú náà ní Ìjẹ̀bú ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé a lè gba ti irúfé èyí tí ó sọ pé Ìjẹ̀bú – Òde ni Ọba Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà ti mú orúkọ náà wá ní eléyìí ti ó bójú mu díẹ̀. Orúkọ yìí ló wú n tí ó sì sọ ìlú tí òun náà tẹ̀dó ní orúkọ náà. Orúkọ oyè rè ni Ọ̀gbọ́ni. Ìtán sọ fún wa pé ibẹ̀ náà ló ti mú un bọ̀.

Gẹ́gẹ́ bi ìtàn àtẹnudẹ́nu, oríṣìíríṣìí ọ̀ná ni a máa ń gbà láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, ṣùgbọ́n ó kù sọ́wọ́ àwọn onímọ̀ òde òní láti ṣe àgbéyèwò àwọn ìtàn wọ̀nyí kí a sì mú eléyìí tí ó bá fara jọ òótọ́ jù lọ nínú wọn.

Nípa pé tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni Ọwá Iléṣà àti Ọba Ijẹ̀bú - Jẹ̀ṣà jẹ́ láti àárọ̀ ọjọ́ wà yìí, sọ wọ́n di kòrí – kòsùn ara wọn. Wọ́n sọ ọ́ di nǹkan ìnira làti ya ara kódà, igbín àti ìkarahun ni wọ́n jẹ́ sí ara wọn. Ṣé bí ìgbín bá sì fà ìkarahun rẹ̀ a tẹ̀ lé e ni a máa ń gbọ́. Ìgbà tí ó di wí pé àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò yí máa fi Ifẹ́ sílẹ̀, ìgbà kan náà ni wọ́n gbéra kúrò lọ́hùnún, apá ibì ken náà ni wọ́n sì gbà lọ láti lọ tẹ̀dó sí. Ọ̀rọ̀ wọn náà wà di ti a já tí kì í lọ kí korokoro rẹ̀ gbélẹ̀. Ibi tí a bá ti rí ẹ̀gbọ́n ni a ó ti rí abúrò. Àjọṣe ti ó wà láàárín wọ́n pọ̀ gan-an tí ó fi jẹ́ wí pé ní gbogbo ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà àti Ọwá Iléṣà jọ ní àwọn nǹkan kan lápapọ̀ bẹ́ẹ̀ náà si ni àwọn ènìyàn wọn.

Tí Owá bá fẹ́ fi ènìyàn bọrẹ̀ láyé àtijọ́, Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ gbọ́ nípa rẹ̀.

Tí Ọwá bá fẹ́ bọ̀gún, ó ní ipa tí Ọba Ijẹ̀bú -Jẹ̀ṣà gbọ́dọ̀ kó níbẹ̀, ó sì ní iye ọjọ́ tí ó gbọ́dọ̀ lò ní Ilèṣà. Ní ọjọ́ àbọlégùnún, ìlù Ọba Ìjẹ̀bù - Jẹ̀ṣà ni wọ́n máa n lù ní Iléṣà fún gbogbo àwọn àgbà Ìjẹ̀ṣà làti jó. Nìgbà tí Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà bá ń bọ̀ wálé lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí ó ti lọ̀ ni Iléṣà fún ọdún ògún, ọtáforíjọfa ni àwọn ènìyàn rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ pàdé rẹ̀.

Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń sọ pé;

“ Kàí bi an kọlíjẹ̀bú

Níbi an tọ̀nà Ìjẹ̀sàá bọ̀

Ọtáforíjọja ọ̀nà ni an kọlijẹ̀bú


Ọmọ Egbùrùkòyàkẹ̀”

Oríṣìíríṣìí oyè ni wọ́n máa ń jẹ ní Iléṣà tí wọn sìń jẹ́ ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. A rí Ọ̀gbọ́ni ní Iléṣà bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà ní Ìjẹ̀bú Jẹ̀ṣà. Ara ìwàrẹ̀fà mẹfà ni Ọ̀gbọ́ni méjèejì yí wa ni Iléṣà ṣùgbọ́n Ọ̀gbọ́n Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni aṣáájú àwọn ìwàrẹ̀fà náà. a rí àwọn olóyè bí Ọbaálá, Rísàwẹ́, Ọ̀dọlé, Léjòfi Sàlórò Àrápatẹ́ àti Ọbádò ni Ìjẹ̀bú-Jèṣà bí wọ́n ti wà ni Iléṣà.

Bákan náà, oríṣìíríṣìí àdúgbò ni a rí tí orúkọ wọn bá ara wọn mu ní àwọn ìlú méjèèjì yí fún àpẹẹrẹ bí a ṣe rí Ọ̀gbọ́n Ìlọ́rọ̀ ni Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà náà ni a rí i ní Iléṣà, Òkèníṣà wà ní Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà, Òkèṣà sì wà ní Iléṣà. Odò-Ẹsẹ̀ wà ní ìlú méjèèjì yí bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹrẹ́jà pẹ̀lú.

Nínú gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní Ilẹ̀ Ìjẹ̀sà, èdè tàbí ohùn ti Iléṣà àti ti Ijẹ̀bú-Jẹ̀ṣà ló bá ara wọn mu jù lọ.

Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ló máa ń fi Ọwá tuntun han gbogbo Ìjẹ̀ṣà gẹ́gẹ́ bí olórí wọn tuntun lẹ́hìn tí ó bá ti ṣúre fún un tán.

Tí ọ̀kan nínú wọn bá sì wàjà, óun ni ogún ti wọ́n máa ń jẹ lọ́dọ̀ ara wọn bí aya, ẹrú àti ẹrù

Ní ìgbà ayé ogun, ọ̀tún ogun, ni Ìjẹ̀bú-Jẹ̀ṣà jẹ́ ní ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, wọ́n sì ní ọ̀ná tiwọn yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù.

Nígbà tí ilẹ̀ Ijẹ̀ṣà dàrú nígbà kan láyé ọjọ́un, àrìmọ-kùnrin ọwá àti àrìmọ-bìnrin Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà ni wọ́n fi ṣe ètùtù kí ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó rójú ráyè, kí ó tó tàbà tuṣẹ.

Nítorí pé Ọba Ìjẹ̀bú - Jẹ̀ṣà àti Ọwá Ilẹ́ṣà jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò látàárọ̀ ọjọ́ wá, àjọṣe tiwọn tún lé igbá kan ju ti gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà tó kù lọ nítorí pé “Ọwá ati Ọ̀gbọ́ni Ìjẹ̀bú -Jẹ̀ṣà ló mọ ohun tí wọ́n jọ dì sẹ́rù ara wọn”.