Itọju Ọmọde
Ni ayé àtijọ, ọmọde ṣòro lati tọju lọpọlọpọ. Ọpọlọpọ awọn oògùn oyinbo ti o wa lóde oni, kò sí ní ayé àtijó rara. Awọn oògùn tí nwọn nlo ni ayé àtijọ náà ni agbo. Oriṣiriṣi agbo ni ọ sí wa.
Agbo wọ́bọ́: Nigba ti ikun ọmọ bá bẹrẹ sí ṣe wọbọwobo, ti o sí npariwo ṣúnrúnrúnrún, nwọn yóò mọ wipe agbo wọbọ ni nwọn yóò to fun ọmọ. Ti nwọn ba sì ti to eyi lóòtó, ọmọde yóò yagbẹ wọ́rọ́wọ́rọ́, ara rẹ yóò sì dà.
Agbo jẹ̀dijẹ̀di: Nigba ti ọmọde ba fẹ yagbẹ, dipo ki o rọra yagbẹ, ti idi rẹ bá bẹrẹ sí pariwo pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀, ti igbe ko si wa, nwọn yóò ti mọ wipe jẹdi nyọ ọmọ lẹnu niyẹn. Ti won ba sì ti to agbo rẹ fun ọmọ, ara rẹ yóò tún ya gágá.