Iyabo Ojo
Ìyábọ́ Alice Òjó (tí a bí ní Ọjọ́ kọnkànlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1977)jẹ́ òṣèrébìnrin àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré tó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó tó àádọ́jọ. Òun náà sì ti ṣe olóòtú sinimá àgbéléwò tó tó mẹ́rìnlá. [1]
Iyabo Ojo | |
---|---|
Ìbí | 21 Oṣù Kejìlá 1977 Lagos State, Nigeria |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà èwe àti bí ó ṣe kẹ́kọ̀ọ́
àtúnṣeGẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, wọ́n bí Ìyábọ́ Òjó lọ́jọ́ kọnkànlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1977. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn ni bàbá rẹ̀, Ìlú Èkó ni wọ́n bí i sí. Ó kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní Gbàgágà nílùú Èkó, ó kàwé ní National College ní Gbàgágà kó tó tẹ̀ síwájú ní ní ilé ìwé gíga Polí ti ìpínlẹ̀ Èkó, Lagos State Polytechnic níbi tí ó ti gboyè nínú imọ̀ ètò ìkọlé, (Estate Management)[2]
Akitiyan rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré
àtúnṣeÌyábọ́ Òjó tí kópa nínú sinimá àgbéléwò tó tó àádọ́jọ. Láti ìgbà èwe rẹ̀, pàápàá jùlọ ní ilé ẹ̀kọ́. Lọ́dún 1998 ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà ní ṣàn-án. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, Bím̀bọ́ Akíntọ̀lá ló ràn án lọ́wọ́ láti dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré tíátà, (the Actors Guild of Nigeria). Ìyábọ́ Òjó kì í ṣe òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá nìkan, ó máa ń kópa nínú sinimá àgbéléwò ti èdè òyìnbó bákan náà. Lọ́dún 1998, ó kópa nínú eré èdè òyìnbó kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Satanic". "Baba Dáríjìnwọ́n" ni sinimá àgbéléwò rẹ̀ àkókò lédè Yorùbá lọ́dún 2002. Lẹ́yìn èyí, ó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò tó pọ̀ súa. Ìyábọ́ Òjó tí lọ́kọ, ó sìn tí sabiyamọ. [3] [4] [5]
Àtòjọ àwọn eré tó ti ṣe
àtúnṣe- Satanic (1998)
- Agogo Ide (1998)
- Baba Darinjinwon (2002)
- Okanla (2013)
- Silence (2015)
- Beyond Disability (2015)
- Black Val[6]
- Arinzo
- Apo Owo
- Awusa (2016)
- Tore Ife (Love)[7]
- Trust (2016)[7]
- Ore (2016)
- Ipadabo (2016)[7]
- Twisted Twin (2016)
- Kostrobu (2017)
- Gone to America (2017)
- Divorce Not Allowed (2018)
- The Real Housewives of Lagos (2022)
Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
àtúnṣeYear | Award ceremony | Category | Film | Result | Ref |
---|---|---|---|---|---|
2017 | Best of Nollywood Awards | Best Supporting Actress –Yoruba | style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé | [8] |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Iyabo Ojo Biography and Net Worth - Austine Media". Austine Media. 2018-04-13. Retrieved 2019-11-26.
- ↑ "Òótọ́ ni Iyabo Ojo ń sọ́! Ìdójútì gbàá ni kí Òṣèré máa tọrọ owó tórí àìsàn - Femi Adebayo". BBC News Yorùbá (in Èdè Latini). 2019-10-08. Retrieved 2019-11-26.
- ↑ "Photos from actress' daughter's sweet 16 party". Pulse Nigeria. 2017-03-13. Retrieved 2019-11-26.
- ↑ Okogba, Emmanuel; Okogba, Emmanuel (2019-06-09). "Iyabo Ojo debunks rumours she never married, releases marriage photos..". Vanguard News. Retrieved 2019-11-26.
- ↑ "Iyabo Ojo’s daughter becomes brand ambassador - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2019-06-22. Retrieved 2019-11-26.
- ↑ Chidumga Izuzu (15 February 2016). "'Black Val' – Toyin Aimakhu, Iyabo Ojo, Dayo Amusa, Desmond Elliott attend premiere". Pulse.ng. Chidumga Izuzu. Retrieved 16 February 2016.
- ↑ 7.0 7.1 7.2 "Best Iyabo Ojo Movies 2017 | Latest Movies & Filmography" (in en-US). Yoruba Movies. Archived from the original on 25 July 2018. https://web.archive.org/web/20180725063502/http://yorubamovies.com.ng/iyabo-ojo-movies.
- ↑ "BON Awards 2017: Kannywood’s Ali Nuhu receives Special Recognition Award". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-11-23. Retrieved 2021-10-07.