Ìyísódì nínú Ẹ̀ka-èdè Ìkálẹ̀

(Àtúnjúwe láti Iyisodi ninu Eka-ede Ikale)

ÌYÍSÓDÌ NÍNÚ Ẹ̀KA-ÈDÈ ÌKÁLẸ̀

Ìfáàrà

Gẹ́gẹ́ bí ìyísódì ṣe ń jẹ yọ nínu YA, Ìkálẹ̀, tíí ṣe ọ̀kan lára àwọn èka-ède Yorùbá, máa ń ṣe àmúlò oríṣiríṣi wúnrẹ̀n láti fi ìyísódì hàn. Ìyísódì lè jẹ yọ nínú ẹyọ ọ̀rọ̀ kan, ó sì tún lè jẹ yọ nínu ìhun gbólóhùn kan. Ṣíṣe àfihàn àwọn ọ̀nà lóríṣiríṣi tí ìyísódì máa ń gbà wáyé nínu ẹ̀ka-èdè Ìkálẹ̀ gan-an ló jẹ wá lógún nínu iṣẹ́ yìí.

Ìyísódì Ẹyọ Ọ̀rọ̀

Àkíyèsí fí hàn pé irúfẹ́ ọ̀rọ̀ méjì ló wà: ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ (èyí ti a kò ṣẹ̀dá) àti ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá. Àwọn ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ kan wà tó jẹ́ wí pé wọ́n ní ìtumọ̀ ìyísódì nínú. Irúfẹ́ ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni rárá. Rárá jẹ́ òdi bẹ́ẹ̀ ni. Ó máa ń dúró gẹ́gẹ́ bíi ìdáhùn gbólóhùn ìbéère

21 (a) (i) Ṣé Adé wúlí? (ii) Ṣé Adé wálé?

(b) (i) Rárá (ii) Rárá

A ó ṣe àkíyèsí wí pé rárá jẹ́ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan tó ń ṣiṣé gbólóhùn òdì.

Tí a kò bá fé lo rárá fún ìdáhùn (21a), a lè sọ wí pé:


(c) (i) Adé éè wúlí (ii) Adé kò wálé.

Irúfẹ́ ọ̀rọ̀ kejì ni ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá. Àwọn yìí ni ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá tí wọ́n sì ń fún wa ní òye ìyísódì. A pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá, nítorí pé wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ oní-mọ́fíìmù kan. Tí a bá fẹ́ ṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀ yìí, a máa ń lo mọ́fíìmù ìsẹ̀dá mọ́ ọ̀rọ̀ ìpìlè, èyí tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀-ìṣe ló máa ń jẹ; àkànpọ̀ àwọn méjéèjì máa ń yọrí sí ọ̀rọ̀-orúkọ. Fún àpẹẹrẹ:

22 (a) (i) àì- + hùn àìhùn (ii) àì- + sùn àìsùn

  	(b)	(i)	àì- + gbọ́n	 àìgbọ́n	(ii)	àì- + gbọ́n	àìgbọ́n
  	(c)	(i)	àì - + jẹun	 àìjẹun		(ii)	àì - + jẹun	àìjẹun

A ṣe àkíyèsí pé mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá àì- náà ni YA máa ń lọ láti fi yi ọ̀rọ̀-ìṣe sódì.

Ìyísódì Fọ́nrán Ìhun Nínu Gbólóhùn Àkíyèsí Alátẹnumọ́

Bí a bá fẹ́ ṣẹ̀dá gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́, fọ́nrán ìhun tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí sí ni a ó gbé sí iwájú gbólóhùn ìpìlẹ̀. Ọ̀nà tí à ń gbà ṣe èyí ni pé a ó fi ẹ̀rún ní sí èyìn fọ́nrán ìhun náà tí a fẹ́ pe àkíyèsí sí. Àwọn fọ́nrán ìhun tí a lè ṣe bẹ́ẹ̀ gbé sí iwájú ni: òlùwà, àbọ̀, kókó gbólóhùn, ẹ̀yán, àpólà-atọ́kùn. Àwọn fọ́nrán ìhun tí a lè pe àkíyèsí sí yìí ni a lè yí sódì. A ó ṣe àgbéyẹ̀wò wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Ìyísódì Olùwà

Bí ó ṣe jẹ́ wí pé a lè pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí olùwà nínu gbólóhùn, bẹ́ẹ̀ náà ni a lè ṣe ìyísódì fún un. Ée ṣe ni wúnrẹ̀n tí ẸI máa ń lò fún ìyísódì Olùwà nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́. Sùgbọ́n nínu YA, ọ̀nà méjì ni a lè gbà ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun tí a pẹ àkíyèsí sí. A lè lo atóka ìyísódì kọ́ tàbí kì í se. Fún àpẹẹrẹ:

23 (a)(i) Àwa rín (ii) Àwa ni

(b)(i) Ée ṣe àwa (ii) Àwa kọ́

  tàbí 

kì í ṣe àwa.

24 (a)(i) Olú ò ó lọ rín (ii) Olú ni ó lọ

(b)(i) Ée ṣe Olú ò ó lọ (ii) Olú kọ́ ni ó lọ

    tàbí 

Kì í ṣe Olú ni ó lọ

25 (a)(i) Ọmàn pupa ò ó hun rín (ii) Ọmọ pupa ni ó sùn

(b)(ii) Ée ṣe ọmọ pupa ò ó hùn (ii) Ọmọ pupa kọ́ ni ó sùn tàbí Kì í ṣe ọmọ pupa ni ó sùn

A ṣe àkíyèsí pé rín ni atọ́ka àkíyèsí alátẹnumọ́ nínu ẸI. Tí a bá sì ti ṣe ìyisódì fọ́nrán ìhun tí a pe àkíyèsí sí, atọ́ka àkíyèsí alátẹnumọ́ náà kì í jẹ yọ mọ́.

Ìyísódì Àbọ̀

Pípe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí àbọ̀ nínu gbólóhùn fara jọ ìgbésẹ̀ ti Olùwà. Ìyàtọ̀ tó kàn wà níbè ni pé tí a bá ti gbé àbọ̀ síwájú, ààye rẹ̀ yóò sófo.

Tí a bá fẹ ṣe ìyísódì àbọ̀ inú gbólóhùn, ée ṣe náà ni wúnrẹ̀n tí ẸI máa ń lò. Fún àpẹẹrẹ:

26 (a) (i) Olú nà Adé (ii) Olú na Adé

(b) (i) Ée ṣe Adé Olú nà (ii) Adé kọ́ ni Olú nà tàbí kì í ṣe Adé ni Olú nà

27 (a) (i) Kítà á pa ẹran (ii) Ajá pa ẹran

(b) (i) Ée ṣe ẹran kítà á pa (ii) Ẹran kọ̀ ni ajá pa

    tàbí 

Kì í ṣe ẹran ni ajá pa


Ìyísódì Kókó Gbólóhùn

Tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí kókó gbólóhùn, a máa ń ṣe àpètúnpè ẹlẹ́bẹ fún ọ̀rọ̀-ìṣe. Bí a ṣe ń ṣe èyí ni pé a ó ṣe àpètúnpè kọ́nsónáǹtì àkọ́kọ́ ti ọ̀rọ̀-ìṣe náà kí a tó wá fi fáwẹ̀lì /i/ Olóhùn òkè sí ààrin kọ́ńsónáǹtì méjéèjì. Fún àpẹẹrẹ:

28 (a) (i) Délé ra bàtà (ii) Délé ra bàtà

(b) (i) Rírà babá ra bàtà rín (ii) Rírà ni babá ra bàtà

29 (a) (i) Ìyábọ̀ fọ ọfọ̀ núẹ̀n (ii) Ìyábọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mìíràn

(b) (i) Fífọ̀ Ìyábọ̀ fọ ọfọ̀ múẹ̀n rín (ii) Sísọ ni Ìyábò sọ ọ̀rọ̀ mìíràn Ìyísódì (28) (b) ni (30) nígbà tí ìyísódì (29) (b) ni 31)

30 (i) Ée ṣe rírà bàbá ra bàtà (ii) Rírà kọ́ ni bàbá ra bàtà tàbí Kì í ṣe rírà ni bàbá ra bàtà

31 (i) Ée ṣe fífọ̀ Ìyábọ̀ fọ ọfọ̀ múẹ̀n (ii) Sísọ kọ́ ni Ìyábọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mìíràn tàbí Kì í ṣe sísọ ni Ìyábọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mìíràn.

Ìyísódì Ẹ̀yán

Ọ̀nà tí a ń gbà yí èyán sódì nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́ yàtọ̀ díẹ̀ sí tí àwọn fọ́nrán ìhun yòókù. Ìgbésẹ̀ kan wà tí a máa ń ṣe fún èyán tí a pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí nígbà tí a bá fẹ́ ṣe ìyísódì rẹ̀.

A lè yíi sódì nínu àpólà-orúkọ tí ó ń yán, a sì tún lè yíi sódì láìbá àpólà-orúkọ tó ń yán rín. Tí èyí bá máa wáyé, a gbọdọ̀ sọ ẹ̀yán náà di awẹ́-gbólóhùn asàpèjúwe, kí á tó yíi sódì. Yí ni atọ́ka awẹ́-gbólóhùn asàpèjúwẹ nínu ẸI. Àpẹẹrẹ ìyísódì ẹ̀yán tó dá dúró láìba ọ̀rọ̀-orúkọ tó ń yán rìn ni:

32 (i) Ọmàn yí mọ rí, ée ṣe pupa (ii) Ọmọ tí mo rí kì í ṣe pupa tàbí Pupa kó ni ọmọ tí mo rí.

33 (i) Ilẹ̀ yí mọ lọ, ée ṣe Ègùn (ii) Ilẹ̀ tí mo lọ, kì í ṣe Ègùn, tàbí Ègùn kọ́ ni ilè tí lọ

Ìyísódì Àpólà-Àpọ́nlé

Gẹ́gẹ́ bí àwọn fọ́nrán ìhun yòókù ṣe máa di gbígbe síwájú nígbà tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí wọn, àpólà-àpọ́nlé náà máa ń di gbígbé wá síwájú nígbà tí a bá fẹ́ pe àkíyèsí alátẹnumọ́ sí i.

Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni àpọ́là-àpọ́nlé máa ń ṣe nínu gbólóhùn: àwọn kan máa ń sọ ibi tí ìṣe inú gbólóhùn náà ti wáyé; àwọn kan sì máa ń sọ ìdí tí ìṣèlẹ̀ náà fi wáyé.

Tí a bá fé ṣe ìyísódì àpólà-àpọ́nlé tó ń sọ ibi tí ìṣe inú gbólóhùn ti wáyé, a ó kọ́kọ́ gbé àpólà-àpọ́nlé náà síwáju, a lè ṣe ìpajẹ ọ̀rọ̀-atọ́kùn tó síwáju rẹ̀, a sì lè dáa sí. Tí a bá ṣe yí, a ó wá fi èrún ti kún àpólà-ìṣe náà. Àpẹẹrẹ ni:

34 (a) (i) Mọ jẹun n’Ọ́ọ̀rẹ̀ (ii) Mo jẹun ní Ọ̀ọ̀rẹ̀

(b) (i) Ée ṣe Ọ̀rẹ̀ mọ ti jẹun (ii) Ọ̀rẹ̀ kọ́ ni mo ti jeun Àpẹẹrẹ ìyísódì àpólà-àpọ́nlé tó ń sọ ìdí tí ìṣe inú gbólóhùn fi wáyé ni

35 (i) Ée ṣe tìtorí àtijẹun àn án bá susẹ́ (ii) Nítorí àtijẹun kọ́ ni wọ́n ṣe ṣiṣẹ́

Ìyísódì Àsìkò, Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ àti Ojúṣe

Oríṣiríṣi àríyànjiyàn ló wà lóri pé ède Yorùbá ní àsìkò gẹ́gẹ́ bí ìsọ̀rí gírámà tàbí kò ní. Bámgbóṣé (1990:167) ní tirẹ̀ gbà pé àsìkò àti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ wọnú ara wọn Ó ní: Àsìkò àti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ máa ń fara kọ́ra nínu ède Yorùbá.

Èro Bámgbóṣé yìí ni yóò jẹ́ amọ̀nà fún wa nínu ìsọ̀rí yìí


Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àdáwà

Àsìkò afànámónìí jẹ mọ́ ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ń sẹlẹ̀, yálà ó ti ṣẹlẹ̀ tán tàbí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lásìkò tí à ń sọ̀rọ rẹ̀. Tí a bá lò ó pẹ̀lú ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ adáwà, kò sí wúnrẹ̀n tó máa ń tọ́ka rè. Fún àpẹẹrẹ:

36 (i) Olú ó lọ Oló lọ (ii) Olú lọ Ìyísódì (36) ni:

37 (i) Olú éè lọ Oléè lo ̣ (ii) Olú kò lọ

Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Atẹ́rẹrẹ

Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àìṣetán atẹ́rẹrẹ máa ń ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ lọ́wọ́ nígbà tí Olùsọ̀rọ̀ ń sọ̀rọ̀. Àpẹẹrẹ èyí ni:

38 (a) (i) Olú éé rẹ̀n (ii) Olú ń rìn

Éé ni atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àìṣetán atẹ́rẹrẹ nínu ẸI, ṣùgbọ́n atọ́ka ìyísódì éè ni a fi ń yí i sódì. Àpẹẹrẹ ni:

(b) (i) Olú éè rẹ̀n Oléè rẹ̀n (ii) Olú kò rìn

Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Bárakú

Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àìṣetán bárakú máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Máa ń àti a máa ló máa ń tọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu YA. Ọ̀nà tí ẸI ń gbà tọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yàtọ̀ gédéńgbé sí ti YA. Atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu ẸI ni éé àti a ka. Ìlo rẹ̀ nínu gbólóhùn ni:

39 (i) Olú éé jẹun (ii) Olú ń jẹun

40 (i) Olú a ka kọrin (ii) Olú a máa kọrin Ée ni atọ́ka ìyísódì ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àpẹẹrẹ ni:

41 (i) Olú ée jẹun (ii) Olú kì í jẹun

42 (i) Olú ée kọrin (ii) Olú kì í kọrin

Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìbẹ̀rẹ̀

Stockwell (1977:39) ṣàlàyé ibá-ìsẹ̀lẹ̀ àṣetán gẹ́gẹ́ bí ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti parí. Bámgbósé (1990:168) ní tirẹ̀ ṣàlàyé wí pé ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ìbẹ̀rẹ̀ nínu àsìkò afànámónìí máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ti parí, ṣùgbọ́n tí ó ṣe é ṣe kí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà má tíì tán. Ti ni atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu ẸI. A máa ń lò ó papọ̀ pẹ̀lú atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ atẹ́rẹrẹ

43 (i) Olú éé ti lọ Oléé ti lọ (ii) Olú ti ń lọ 44 (i) Àn án ti ka kọrin (ii) Wọn á tí máa kọrin Ée ni atọ́ka ìyísódì ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Fún àpẹẹrẹ:

45 (i) Olú ée ti í lọ Olée ti í lọ (ii) Olú kì í ti í lọ

46 (i) Án àn ti ka korin (ii) Wọn kò tíì máa kọrin

Ìyísódì Àsìkò Afànámónìí àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìparí

Ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ìparí nínu àsìkò afànámónìí máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti parí pátápátá. Ti ni atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àpẹẹrẹ ìlo rẹ̀ nínu gbólóhùn ni:

47 (i) Ọmàn mi ti hùn (ii) Ọmọ mi ti sùn

48 (i) Mọ ti fọfọ̀ múẹ̀n (ii) Mo ti sọ̀rọ̀ mìíràn

Éè ni atọ́ka ìyísódì ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nínu ẸI. Nígbà tí a bá yíi padà, ohun ààrin to wà bẹ lóri atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò yí padà sí ohùn ìsàlẹ̀. Àpẹẹrẹ ni:


49 (i) Ọmàn mi éè tì hùn (ii) Ọmọ mi kò tíì sùn

50 (i) Méè tì fọfọ̀ múẹ̀n (ii) N kò tíì sọ̀rọ̀ mìíràn

Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lè Àdáwà

Nígbà tí atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú bá ti jẹ yọ pẹ̀lú ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ adáwà, (tí kò ní atọ́ka kankan), àbájáde rẹ̀ yóò jẹ́ ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ adáwà nínu àsìkò ọjọ́-iwájú. Àwọn àpẹẹrẹ ni:

51 (i) Olú a lọ (ii) Olú á lọ

52 Ìyábọ̀ á fọfọ̀ nọọ̀la (ii) Ìyábọ̀ á sọ̀rọ̀ lọ́lá Ìyábọ̀ (51) ni (53), nígbà tí ìyísódì (52) ni (54)

53 (i) Olú éè níí lọ Oléè níí lọ (ii) Olú kò níí lọ

54 (i) Ìyábọ̀ éè níí fọfọ̀ nọọ̀la (ii) Ìyábọ̀ kò níí sọ̀rọ̀ lọ́la.

Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Atẹ́rẹrẹ

Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí èyí ti jẹ yọ ni:

55 Ìyábọ̀ a ka hunkún (ii) Ìyábọ̀ á máa sunkún Ìyísódì rẹ̀ ni:

56 (i) Ìyábọ̀ éè níí ka hunkún (ii) Ìyábọ̀ kò níí máa sunkún

Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àìṣetán Bárakú

Ìhun kan náà ni èyí ní pẹ̀lú ìhun àsìkò ọjọ́-iwájú àti ibá-ìṣẹ̀lẹ àìṣetán atẹ́rẹrẹ. Àpẹẹrẹ ni:


57 (a)(i) Àlàdé a ka jẹja ẹri (ii) Àlàdé á máa jẹja odò Ìyísódì gbólóhùn yìí ni:

(b)(i) Àlàdé éè níí ka jẹja ẹri (ii) Àlàdé kò níí máa jẹ ẹja odò

Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìbẹ̀rẹ̀

Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí èyí ti jẹ yọ ni:

58 (i) A tí a jọ lọ hí oko (ii) A ó tí jọ lọ sí oko Ìyísódì rẹ̀ ni

59 (i) Ẹ́ẹ̀ níí ti a jọ lọ hí oko (ii) A ò níí ti máa jọ lọ sí oko

Ìyísódì Àsìkò Ọjọ́-Iwájú àti Ibá-Ìṣẹ̀lẹ̀ Àṣetán Ìparí

Àpẹẹrẹ gbólóhùn tí ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán ìparí ti jẹ yọ nínu àsìkò ọjọ́-iwájú ni:


60 (a) (i) Olú a ti rẹ̀n (ii) Olú á ti rìn Ìyísódì gbólóhùn yìí ni:

(b) (i) Olú éè tì níí rẹ̀n (ii) Olú kò tíì níí rìn

Ìyísódì Atọ́ka Múùdù (Ojúṣe)

Adéwọlé (1990:73-80) gbà pé múùdù jé ọ̀kan lára àwọn ìsọ̀ri gírámà Yorùbá. Ó pín wọn sí oríṣìí mẹ́ta nípa wíwo ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jẹ yọ: Ó pe àkọ́kọ́ ni èyí tó ń fi ṣiṣe é ṣe hàn (possibility); ó pe èkejì ní èyí tó ń fi gbígbààyè hàn (permission); ó pe ẹ̀kẹta ni èyí tó pọn dandan. Àwọn múùdù wọ̀nyí ni à ń dá pè ni ojúṣe wọ̀fún, àníyàn àti kànńpá lédè Yorùbá. Fábùnmi (1998:23-24) pè é ní Ojúṣe.

Ìyísódì Ojúṣe Wọ̀fún

Léè ni atóka ojúse wọ̀fún nínu ẸI. Fún àpẹẹrẹ:

61 (i) Olú léè jọba ùlú rẹ̀ (ii) Olú lè jọba ìlu re. Tí a bá yi atọ́ka ojúṣe yìí sódì, yóò di leè. Ée ni atọ́ka ìyísódì ojúṣe nínu ẸI.

62 (i) Olú éè leè jọba ùlú rẹ̀ (ii) Olú kò lè jọba ìlú rẹ̀

Ìyísódì Ojúṣe Kànńpá

Gbẹẹ̀dọ̀ ni atọ́ka ojúṣe kànńpá nínu ẸI. Àpẹẹrẹ ni:

63 (i) Olú gbẹẹ̀dọ̀ hùn (ii) Olú gbọdọ̀ sùn Ìyísódì rẹ̀ ni:

64 (i) Olú éè gbẹẹ̀dọ̀ hùn (ii) Olú kò gbọdọ̀ sùn

Ìyísódì Ojúse Ànìyàn

Àríyànjiyàn pọ̀ lóri ìsọ̀ri gírámà tí yóò wà nínu YA.Bámgbóṣé (1990) gbà pé atọ́ka àsìkò ọjọ́ iwájú ni yóò àti àwọn ẹ̀da rẹ̀ bíi yó, ó, á. Fábùnmi (2001) ní tirè sàlàyé wí pé ojúse ni yóò àti àwọn ẹ̀da rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ní Yorùbá tún máa ń lò wón láti fi tọ́ka sí àsìkò ọjọ́-iwájú. Oyèláràn (1982) nínu èro rẹ̀ kò fara mọ́ èro pé yóò jẹ́ atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú. Ó ni yóò máa ń ṣiṣẹ́ ibá-ìṣẹ̀lẹ̀, ò sì tún máa ń ṣiṣẹ́ ojúṣe nígbà mìíràn. Sàláwù (2005) ò gba yóò gẹ́gẹ́ bí atọ́ka àsìkò ọjọ́-iwájú tàbí ojúṣe. Ó ní yóò àti àwọn ẹ̀da rẹ̀ á, ó àti óó jẹ́ atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àníyàn nínu YA. Adéwọlé (1988) ní tirè ṣe òrínkíniwín àlàyé láti fi ìdi rè múlẹ̀ pé atọ́ka múùdù ni yóò. Nítorí náà, a ó lo wúnrẹ̀n yóò gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àníyàn. Nínu ẸI, a ni atọ́ka ojúṣe àníyàn. Fún àpẹẹrẹ:


65 (i) Mà a jẹun nóko (ii) N ó jẹun lóko Ìyísódì rẹ̀ ni:

66 (i) Méè níí jẹun nóko (ii) N kò níí jẹun lóko/N kì yóò jẹun lóko

Ìyísódì Odidi Gbòlòhún

Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ní ìbẹ̀rẹ iṣẹ́ yìí, a lè ṣe ìyísódì ẹyọ ọ̀rọ̀, a lè ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun gbólóhùn, a sì tún lè ṣe ìyísódì odidi gbólóhùn pẹ̀lú. Bámgbóṣé (1990:217) sàlàyé pé ìyísódì odidi gbólóhùn ni èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ mọ wí pe ìṣẹ̀lẹ̀ tí a sọ nínu gbólóhùn náà kò ṣẹlẹ̀ rárá. Ó ní: Tí gbólóhùn kò bá ní ju ẹyọ ọ̀rọ̀-ìṣe kan lọ nínu àpólà-ìṣe…, ìyísódì odidi gbólóhùn nìkan ni a lè ṣe fún un. Ṣùgbọ́n, tí ọ̀rọ̀-ìṣe bá ju ọ̀kan, tàbí tí àpólà-ìṣe bá ní fọ́nrán tí ó ju ọ̀kan lọ, a lè ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun tàbí ti odidi gbólóhùn.

Ìyísódì Gbólóhùn Àlàyé

Gbólóhùn àlàyé ni a máa ń lò láti fi sọ bí nǹkan bá ti rí. Bámgbọ́sé (1990:183) sọ wí pé: Tí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ bá fẹ́ẹ ṣe ìròyìn fún olùgbọ́, gbólóhùn yìí ni yóò lo. Gbólóhùn-kí-gbólóhùn tí kò bá jẹ́ ti ìbéèrè tàbí ti àṣẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ gbólóhùn àlàyé.

Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn àlàyé ni:

67 (i) Mo fọfọ̀ múẹ̀n naàná (ii) Mo sọ̀rọ̀ mìíràn lánàá

68 (i) Olú gbé uṣu wá í ọja (ii) Olú gbé iṣu wá sí ọjà Ìyísódì (67) ni (69), nígbà tí ìyísódì (68) ni (70)

69 (i) Méè fọfọ̀ múẹ̀n naàná (ii) N kò sọ̀rọ̀ mìíràn lánàá

70 (i) Olú éè gbé usu wá í ọjà (ii) Olú kò gbé iṣu wá sí ọjà

Ìyísódì Gbólóhùn Àṣẹ

Máà ni wúnrẹ̀n tí ẸI ń lò fún ìyísódì gbólóhùn àṣẹ. Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn àṣe ni

71 (i) Háré wá! (ii) Sáré wá!

72 (i) Ka lọ! (ii) Máa lọ! Ìyísódì (71) yóò fún wa ni (73)

73 (i) Máà háré wá (ii) Má sáré wá

Tí a bá fẹ́ ṣe ìyísódì (72), a ó yọ atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ atẹ́rẹrẹ ka kùrò, a ó sì lo atọ́ka ìyísódì máà dípò rẹ̀. Ìyísódì (72) yóò yọrí sí (74)


74 (i) Máà lọ (ii) Má lọ

Ìyísódì Gbólóhùn Ìbéèrè

Bámgbóṣé (1990:183-186) ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lóri ọ̀nà tí a máa ń gbà ṣe ìbéèrè nínu ède Yorùbá. Ó ní ọ̀nà tí à ń gbà ṣe èyí ni pé kí á lo wúnrẹ̀n ìbéèrè nínu gbólóhùn.

A ó ṣe àgbéyẹ̀wò wọn lọ́kọ̀ọ̀kan àti bí ìyísódì ṣe ń jẹ yọ pẹ̀lú wọn.

Gbólóhùn Ìbéèrè tí ó ń lo Atọ́nà Gbólóhùn

Ṣé ni ẸI máa ń lò gẹ́gẹ́ bí atọ́nà gbólóhùn láti fì ṣe ìbéèrè bẹ́ẹ̀-ni-bẹ́ẹ̀-kọ. Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn ìbéèrè oní-atọ́nà gbólóhùn ni: ẸI YA 75 (i) Ṣé Olú wúlí? (ii) Sé Olú wálé?

76 (i) Ṣé Dàda ti hanghó? (ii) Ṣé Dàda ti sanwó? Éè ni ẸI ń lò láti fi ṣe ìyísódì ìṣẹ̀lẹ̀ inú gbólóhùn ìbéèrè náà. Fún àpẹẹrẹ

77 (i) Ṣé Olú éè wúlé? (ii) Ṣé Olú kò wálé?

78 (i) Ṣé Dàda éè ti hanghó? (ii) Ṣé Dàda kò tíì sanwó? A ó ṣe àkíyèsí wí pé atọ́ka ìyísódí yìí máa ń jẹ yọ nípa pé kí á fi sí inú gbólóhùn lẹ́yìn Olúwà.

Gbólóhùn Ìbéèrè to ní Ọ̀rọ̀-orúkọ Aṣèbéèrè

Bámgbósé (1990:184) ṣe àlàyé pé nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́ ni a ti máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀-orúkọ aṣèbéèrè. Ó ní a lè dá wọn tò gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí kí á fi wọ́n ṣe ẹ̀yán fún ọ̀rọ̀-orúkọ mìíràn. Àwọn àpẹẹrẹ gbólóhùn yìí ni:

79 (a) (i) kí àn án jẹẹ? (ii) Kí ni wọ́n jẹ

(b) (i) Kíì yi we fẹ́ o? (ii) Èwo lẹ fẹ́ o?

(d) (i) Kéèlú àn án gba a? (ii) Èló ni wọ́n gbà? A lè ṣe ìyísódì ìṣẹ̀lẹ̀ inú gbólóhùn ìbéèrè wọ̀nyí. Ìyísódì (79 a-d) ní sísẹ̀-n-tẹ̀lé ni:

80 (a) (i) Kí án àn jẹ ẹ? (ii) Kí ni wọn ò jẹ?

(b) (i) Kíì yi wéè fẹ́ o? (ii) Èwo lẹ ò fẹ́ o?

(d) (i) Kéèlú án àn gba a? (ii) Èló ni wọn ò gbà?


Gbólóhùn Ìbéèrè Ọlọ́rọ̀ọ̀ṣe Aṣèbéèrè

Han àti kẹ ni ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè nínu ẸI. Àpẹẹrẹ ìlo wọn nínu gbólóhùn ni: ẸI YA 81 (i) Ọmàn mi han? (ii) Ọmọ mi dà?

82 (i) Aṣọ̀ mi kẹ? (ii) Aṣọ mi ńkọ́? A kò le ṣe ìyísódì gbólóhùn ọlọ́ròòṣe aṣèbéèrè. Fún àpẹẹrẹ: ẸI YA

83 (i) *Ọmàn mi éè han? (ii) *Ọmọ mi kò dà?

84 (i) *Aṣọ mi éè kẹ? (ii) *Aṣọ mi kò ńkọ́?

Ìyísódì Òǹkà Ẹ̀ka-Èdè Ìkálẹ̀

Ohun tí a fẹ́ ṣe nínu abala yìí ni ṣíṣe àfihàn ipa ti ìyísódì ní lóri òǹkà ẸI. Ohun tó jẹ wá lógún ni ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí à ń gbà yí àwọn òǹkà sódì.

Ọ̀kan lára àwọn àtúnpín-sí-ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-orúkọ Bámgbóṣé (1990:97) ni ọ̀rọ̀-orúkọ aṣeékà. Ó ni ọ̀rọ̀-orúkọ àṣeékà ni èyí tí a lè lò pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òǹkà nítorí pe irú ọ̀rọ̀-orúkọ bẹ́ẹ̀ ṣe é kà.

Ní ìbamu pẹ̀lú èro Bámgbóṣé yìí, tí a bá lo ọ̀rọ̀-orúkọ aṣeékà pẹ̀lú ọ̀rọ̀-òǹkà papọ̀, yóò fún wa ní àpólà-orúkọ. Àtúpalẹ̀ irúfé àpólà-orúkọ yìí ni orí (tíí ṣe ọ̀rọ̀-orúkọ) àti ẹ̀yan rẹ̀ (ọ̀rọ̀ òǹkà náà). Irúfẹ́ ẹ̀yán yìí ni Bámgbóṣé pè ní ẹ̀yán aṣòǹkà. Àpẹẹrẹ irúfẹ́ àpólà-orúkọ yìí ni:

85 (a) (i) Ọman mẹ́ẹ̀fà (ii) Ọmọ mẹ́fà

(b) (i) Ulí mẹ́ẹ̀tàdínógún (ii) Ilé mẹ́tàdínlógún

(d) (i) Bàtà maàdọ́gbọ̀n (ii) Bàtà mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n

Ìjẹyọ àwọn àpólà-orúkọ yìí nínu gbólóhùn ni:

86 (a) (i) Mọ rí ọman mẹ́ẹ̀fà (ii) Mo rí ọmọ mẹ́fà

(b) (i) Mọ kọ́ ulí mẹ́ẹ̀tàdínógún (ii) Mo ko ilé mẹ́tàdínlógún.

(d) (i) Mọ ra bàtà maàdọ́gbọ̀n (ii) Mo ra bàtà mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n

Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣaájú ní 3.3.4, wí pé tí a bá fẹ́ yí ẹ̀yán sódì, nínu gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́, a máa ń sọ ẹ̀yán náà di awẹ́ gbólóhùn asàpèjúwe. Ìgbésè yìí máa ń wáyé nínu ìyísódì òǹkà. Yí ní atọ́ka awẹ́-gbólóhùn-asàpèjúwe nínu ẸI. Ée ṣe ni atọ́ka ìyisódì èyán asòǹka nínu ẸI. Ìyísòdì ẹ̀yán asòǹkà nínu gbólóhùn (86 a-d) yóò fún wa ni (87 a-d)

87 (a) (i) Ọmàn yí mọ rí, ée ṣe mẹ́ẹ̀fà (ii) Mẹ́fà kọ́ ni ọmọ tí mo rí tàbí Ọmọ tì mo rí, kì í ṣe mẹ́fà

(b) (i) Ulí yí mọ kọ́, ée ṣe (ii) Mẹ́tàdínlógún kọ́ ni mẹ́ẹ̀tadínógún ilé tí mo kọ́ tàbí Ilé tí mo kọ́ kì í ṣe mẹ́tàdínlógun

(d) (i) Bàtà yí mọ rà, ée ṣe (ii) Mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n kọ́ ni bàtà tí maàdọ́gbọ̀n mo rà tàbí Bàtà tí mo rà kì í ṣe mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n

A ó ṣe àkíyèsí wí pé ọ̀nà méjì ni YA lè gbà ṣe ìyísódì ẹ̀yán àsòǹkà, ṣùgbọ́n ọ̀nà kan ṣoṣo ni ẸI ń gbà ṣe ìyísódì èyí.

Bámgbóṣé (1990:129) ṣe àkíyèsí irúfé àpólà-orúkọ kan to pè ní àpólà-orúkọ agérí. Irúfẹ àpólà-orúkọ yìí máa ń sáábà wáyé nínu àpólà-orúkọ tí ọ̀rọ̀ òǹkà jẹ́ ẹ̀yan rẹ̀. Àwọn àpẹẹrẹ àpólà-orúkọ yìí ni àbọ̀ àwọn gbólóhùn ìsàlẹ̀ yìí:

88 (i) Mọ jẹ mẹ́ẹ̀ghwá (ii) Mo jẹ mẹ́wàá

89 (i) Bọ́lá mú ọgọ́ọ̀fà (ii) Bólá mú ọgọ́fà

A ó ṣe àkíyèsí pé ẹ̀yán asòǹka nìkan ló dúró gẹ́gẹ́ bí àbọ̀ gbólóhùn òkè wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n sá, kì í ṣe pé àpólà-orúkọ náà kò ní orí; mọ̀ọ́nú ni orí àpólà náà, ó sì yé àwọn méjéèji tó bá ń tàkurọ̀sọ. Ée ṣe ni a fi máa ń yí irúfẹ́ àpólà-orúkọ agérí wọ̀nyí nínu ẸI. Ìyísódì ọ̀rọ̀ òǹkà nínu gbólóhùn (88) àti (89) ni:

90 (i) Ée ṣe mẹ́ẹ̀ghwá mọ jẹ (ii) Kì í ṣe mẹ́wàá ni mo jẹ tàbí Mẹ́wàá kọ́ ni mo jẹ 91 (i) Ée ṣe ọgọ́ọ̀fà Bọ́lá mu (ii) kì í ṣe ọgọ́fà ni Bólá mú tàbí Ọgọ́fà kọ́ ni Bọ́lá mu

Ìgúnlẹ̀

Nínu orí kẹta yìí, a ti gbìyànjú láti ṣe àgbékalẹ̀ bí ìyísódì ṣe ń jẹ yọ nínu ẸI. A ṣe àkíyèsí onírúurú ìhun tí ìyísódì ti ń jẹ yọ nínu ẸI. A jẹ́ kó di mímọ̀ pé a lè ṣe ìyísódì eyọ ọ̀rọ̀; a lè ṣe ìyísódì fọ́nrán ìhun gbólóhùn, a sì lè ṣe ìyísódì odidi gbólóhùn. A tún ṣe àgbéyẹ̀wò ìyísódì àsìkò, ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àti ojúṣe nínu ẸI.

Lẹ́yìn èyí, ọwọ́jà iṣẹ́ yìí dé àgbéyẹ̀wò òǹkà ẸI. A ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ òǹkà náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán aṣòǹkà, a sì ṣe àfihàn bí a ṣe ń ṣe ìyísódì òǹkà ẸI.