Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C
Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C jẹ́ àrùn tí ó jẹ́ pé ẹ̀dọ̀ ni ó kọ́kọ́ máa n ṣe àkóbá fún. Kòkòrò-àrùn Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C ni ó máa n fa àrùn náà.[1] Hepatitis C kì í sáábà ní ìmọ̀lára-àìlera, sùgbọ́n èyí tí ó bá ti wọ ara gan an lè dá ọgbẹ́ sí ara ẹ̀dọ̀, tí ó sì lè yí sí àìsàn ẹ̀dọ̀ míràn tí a mọ̀ sí cirrhosis lẹ́yìn ọdún díẹ̀. Ní àwọn ìgbà míràn, àwọn ènìyàn tí ó bá ní àìsàn ẹ̀dọ̀ tí n jẹ́ cirrhosis àìlera ẹ̀dọ̀ parí-iṣẹ́, jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀, tàbí kí ó mú kí gògò-ń-gò àti ikùn wú bọ-bọ-ọ-bọ, èyí tí ó sì le yọrí sí sìsun ẹ̀jẹ̀ tí ó mú ikú lọ́wọ́.[1]
Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C | |
---|---|
Electron micrograph of hepatitis C virus purified from cell culture (scale = 50 nanometers) | |
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta | |
ICD/CIM-10 | B17.1, B18.2 B17.1, B18.2 |
ICD/CIM-9 | 070.70,070.4, 070.5 070.70,070.4, 070.5 |
OMIM | 609532 |
DiseasesDB | 5783 |
MedlinePlus | 000284 |
Ọ̀nà àkọ́kọ́ tí àwọn ènìyàn ti máa n ṣe àgbákò àrùn hepatitis C jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀-kan-ẹjẹ̀ ní ìgbà tí ènìyàn bá n gba ìtọ́jú fífa òògùn sínú isan ara, àwọn ohun èlò iṣẹ́ ìlera tí a kò bọ̀ lórí iná kí a tó lò wọn, àti nípa gbígba ẹ̀jẹ̀ sí ara. Ó tó miliọnu 130–170 káàkiri àgbáye tí wọn ní àrùn hepatitis C. Àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìwádìí lóri kòkòrò-àrùn HVC ni ààrin ọdún 1970, tí wọn sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọdún 1989 pé àrùn tí n jẹ́ bẹ́ẹ̀ wà.[2] Kò tí ì hàn bóyá kòkòrò náà lè fa àìsàn si ara ẹranko.
Peginterferon àti ribavirin ni àwọn òògùn tí ó yẹ fún kòkòrò-àrùn HCV. Ìdá ààdọ́ta sí ọgọ́rin ninu ọgọ́rùn ún ènìyàn tí a fún ní òògù yìí ni wọn gba ìmúláradá. Àwọn tí wọn ní àìsàn ẹ̀dọ̀ cirrhosis tàbí jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀ lè nílò ìpààrọ̀ ẹ̀dọ̀, sùgbọ́n kòkòrò-àisàn yìí a tún lè jẹ jáde lẹyìn ìpààrọ̀ ẹ̀dọ̀ náà.[3] Kò sí abẹ́rẹ́-àjẹsára fún hepatitis C.
Àwọn àmì àti Ìmọ̀lára-àìsàn
àtúnṣeÌwọ̀nba ìdá mẹ́ẹ̀dógún ninu ọgọrun un àìsàn Jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C ni ó máa n mú ìmọ̀lára-àìsàn lọ́wọ́.[4] Àwọn ìmọ̀lára-àìsàn kì í sáàbà le ni ara, wọn kì í sì fi ojú hàn dáradára, lára wọn ni kí oúnjẹ má wù ènìyàn jẹ, kí ó máa rẹ̀ ènìyàn, kí èébì máa gbé ni, ìrora inu-ẹran ara tàbí ìrora oríkèé-ríkèé ara, kí ènìyàn máa rù.[5] Díẹ̀ péré lára àwọn àìsàn tí ó wọ aláìsàn náà lára ni ó máa n mú ibà-ọmọdé lọ́wọ́.[6] Àìsàn náà a máa lọ fúnrarẹ̀ ní ara ìdá mẹ́wàá sí àádọ́ta ninu ọgọ́rùn ún àwọn ènìyàn tí ó bá mú, tí ó sì máa n tètè kúrò lára àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ju àwọn yooku lọ.[6]
Àìsàn tí ó ti wọ ara gan an
àtúnṣeÌdá ọgọ́rin ninu ọgọ́rùn ún àwọn ènìyàn tí kòkòrò-àrùn yìí bá jà ní ó máa n wọ̀ lára gan an.[7] Ọ̀pọ̀ ni ó máa n ní ìmọ̀lára-àìsàn ní ìwọ̀nba, tàbí kí wọn má tilẹ̀ ní ìmọ̀lára yìí rárá ní ààrin ọdún mẹ́wàá àkọ́kọ́ tí wọn ti ní àìsàn nàá lára, [8] bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn hepatitis C máa n mú ara rírẹ̀ lọ́wọ́.[9] Hepatitis C ní okùnfà àkọ́kọ́ fún àìsàn-ẹdọ̀ cirrhosis àti jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀ láàrin àwọn tí àrùn yìí n bá já fún ọdún díẹ̀.[3] Láàrin ìdá mẹ́wàá sí ọgbọ̀n ninu ọgọrun un tí wọn ni àìsàn náà fún bí i ọgbọ̀n ọdún ni wọn ni àìsàn-ẹ̀dọ̀ cirrhosis.[3][5] Àìsàn-ẹ̀dọ̀ cirrhosis wọ́pọ̀ júlọ láàrin àwọn tí wọn ní àìsàn hepatitis B tàbí àìsàn-kò-gbóògùn HIV, àwọn ọ̀mùtípara, àti ni àárin áwọn ọkùnrin.[5] Àwọn tí wọn ní àìsàn-ẹ̀dọ̀ cirrhosis n bẹ ninu ewu nla pé wọn yóò ní jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀, èyí tí í ṣe ìdá kan sí mẹ́ta ninu ọgọ́rùn ún láàrin ọdún kan.[3][5] Fún àwọn ọ̀mùtípara, ewu àìsán náà tó ìlọ́po ọgọ́rùn ún lọ́dọ̀ wọn.[10] Hepatitis C ni ó máa n fa àísàn-ẹ̀dọ̀ cirrhosis tí ó tó ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ninu ọgọrùn ún àti àìsàn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀ tí ó tó ìdá márùndínlọ́gbọ̀n ninu ọgọrùn ún.[11]
Àísàn-ẹ̀dọ̀ cirrhosis tún lè yọrí sí ìfúnpá gíga ninu àwọn iṣan ara ti wọn so pọ̀mọ́ ẹ̀dọ̀, kí omi ara rọgún sínú ikùn, awọ-ara tí kò gbó tàbí ìsun ẹ̀jẹ̀, iṣan tí ó fẹ̀ sí i, pàápàá ninu ikùn àti ní gògò-n-gò, ibà-àyìnrín (kí awọ-ara pọ́n bí), àti àkóbá ọpọlọ.[12]
Àwọn àkóbà míràn yàtọ̀ fún ti ẹdọ̀
àtúnṣeÀìsàn Hepatitis C tún jẹ́ ọ̀rẹ́ àìsàn àìsàn Sjögren's syndrome (irú àìlera kan tí n mú àgọ̀-ara dá àbò àìnídìí bo ararẹ̀), tí àwọn awo ẹ̀jẹ̀ kò tó bí ó ti yẹ, àìsàn awọ-ara, àìsàn ìtọ̀-súgà, àti àìsàn jẹjẹrẹ tí kì í ṣe Hodgkin.[13][14]
Okùnfà
àtúnṣeKòkòrò-àrùn hepatitis C náà jẹ́ àìlèfojúrí, tí ó ní èèpo, onífọ́nrán kan, fáírọ́ọ̀sì RNA.[3] O jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹbí kòkòrò-àìrùn hepacivirus Flaviviridae.[9] Àwọn oríṣi jẹnotaipu HCV méje pàtàkì ní n bẹ.[15] Ní ilẹ̀ Amẹrika, jẹnotaipu 1 n fa ìdá àádọ́rin ninu ọgọ́rùn ún àwọn àìsàn, jẹnotaipu 2 n fa ìdá ogún ninu ọgọ́rùn ún àwọn àìsàn, tí ìyòókù ìdá kan ninu ọgọ́rùn ún n fa àwọn àìsàn míràn. [5] Jẹnotaipu 1 ni ó tún wọ́pọ̀ jùlọ́ ni Gúùsù Amẹrika àti ni ilẹ Europe.[3]
Bí aìsàn Ṣe n tàn kálẹ̀
àtúnṣeỌ̀nà àkọ́kọ́ tí àìsàn n gbà tàn kálẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè ti wọn ti gòké-àgbà ni gbígba abẹ́rẹ́ sínu iṣan-ara (IDU). Ní àwọn orílẹ̀-èdè ti n gòké-àgbà ọ̀nà tí ó wọ́pọ̀ níbẹ̀ ni nípa gbígba ẹ̀jẹ̀ sí ara àti àwọn ọ̀nà ìtọ́jú aláìsàn tóléwu[16] Ìdá ogún ninu ọgọ́rùn ún ọ̀nà yóòkù tí àìsàn gbà tàn kálẹ ni ó sì farasin síbẹ̀;[17] sùgbọ́n ọ̀pò ninu àwọn ọ̀nà lè máa ṣe ẹ̀yìn gbígba abẹrẹ sinu iṣan ara, IDU.[6]
gbígba abẹ́rẹ́ sínú iṣan-ara
àtúnṣeGbígba abẹrẹ sínú iṣan ara, IDU jẹ́ ọ̀nà kan tí ó léwu jùlọ́ láti kan àìsàn hepatitis C ní ọ̀pọ̀ ibi ní àgbáyé.[18] Àgbéyẹ̀wò ní orílẹ̀-èdè mẹ́tadínlọ́gọ́rin fihàn pé marundinlọgbọn ninu wọn ni ìdá ọgọ́ta sí ọgọ́rin ninu ọgọrùn ún àwọn ara orílẹ̀-èdè náà ni wọn ti ipasẹ̀ gbígba òògùn sínú isan-ara di aláìsàn hepatitis C, ninu èyí tí ilẹ́ Amẹrika[7] àti ilẹ̀ China n bẹ lara wọn. [18] Àwọn orílẹ̀-èdè mejila ní ìdá tí o ga ju ọgọ́rin ninu ọgọrùn ún.[7] Ó tó miliọnu mẹ́wàá tí wọn ní àìsàn hepatitis C nítorí wọn ngba abẹ́rẹ́ sinu isan ara wọn; ní China (wọn jẹ́ 1.6 million), ní ilẹ́ Amẹrika (1.5 million), ati ní ilẹ́ Russia (1.3 million) gẹgẹ bí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ní àìsàn yìí jùlọ.[7] Bí àìsàn hepatitis C ti n gbilẹ̀ láàrin àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ Amẹrika tó ẹni mẹ́wàá ninu ogún láàrin wọn, ní èyí tí ìwádìí sọ pé àwọn ìwà tó léwu bí i a n gba abẹ́rẹ́ sinu isan ara àti sínsín gbẹ́rẹ́ pẹ̀lú àwọn nnkan ṣó-n-ṣó tí wọn kò ṣè lórí iná.[19][20]
Fífi ojú ẹni mọ ìtọ́jú-ìlera
àtúnṣeGbígba ẹ̀jẹ sí ara, èròjà ẹ̀jẹ̀, àti gbígba ẹ̀yà ara tuntun láì ya fọto HCV a màa mú ewu nlá àìsàn yìí lọ́wọ́.[5] Ilẹ̀ Amẹrika ni o fìdí yíya fọto náà lélẹ̀ ní ọdún 1992. Láti ìgbà náà sí ni ina àìsàn náà ti n jó lọ sílẹ̀ sí ẹni kan pere nínú igba ènìyàn fún ẹ̀jẹ̀ gbìgbá[21] to one in 10,000 to 10,000,000 per units of blood.[6][17] Ewu kékeré yìí sí wà nítorí pé àlààfo bí i ọdún mọkanla sí àádọ́rin ọdún nín bẹ láàrin olùfẹ̀jẹ̀sílẹ̀ tí o lè ní àìsàn hepatitis C àti bí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣe lè fihàn pé wọn ní i.[17] Àwọn orílẹ̀-èdè kan sì wà tí wọn kò tí ì máa ya fọto ẹ̀jẹ̀ fún àyẹ̀wo àìsàn hepatitis C nítorí iye owó tí ó máa ná wọn.[11]
Ẹni kan tí ó ní ìpalára gígún abẹ́rẹ́ láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní HCV ṣeéṣe kí ó ní àìsàn náà ní bí i ó dín díẹ̀ ní ìdámeji ninu ọgọrun un ìgbà.[5] Ewu náà tún ga sí i tí ó bá jẹ́ pé abẹ́rẹ́ náà bá ní ihò tí ọgbẹ́ náà sí jìn wọnú.[11] Ewu lè wà láti inú kẹ̀lẹ̀bẹ̀ tàbí láti inú ẹ̀jẹ̀; sùgbọ́n ewu yìí kò ga rárá, kò sì sí ewu kan kan rárá bí ó bá jẹ́ pé ara náà kó bó lójú tàbí ní ọgbẹ́.[11]
Àwọn irinṣẹ́ tí a n lò ní ilé-ìwòsàn pẹ̀lú lè fa àìsàn hepatitis C, àwọn bí i: abẹ́rẹ́ àti ọ̀pá-abẹ́rẹ́ tí-a-tún-lò, ìgò òògùn alájùmọ̀lò, àwọn garawa fún pípo òògùn, àti àwọn irin iṣẹ́ fún iṣẹ́–abẹ tí a kò bọ̀ ní omi gbígbóná.[11] Àwọn ohun-èlò iṣẹ́ ìlera àti ìtọ́jú-eyín ni n fa ọ̀pọ̀ títàn ka àìsàn HCV ní orílẹ̀-èdè Egypt, orílẹ̀-èdè náà tí àìsàn náà ti wọ́ pọ̀ jùlọ ní àgbáyé.[22]
Ìbára-ẹni lò pọ̀
àtúnṣeA kò tí ì mọ̀ bóyá ènìyàn lè ti ipasẹ̀ ìbáraẹnilòpọ̀ kó àìsàn hepatitis C.[23] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbáṣepọ̀ n bẹ láàrin bíbáraẹnilòpọ̀ ní àìbìkítà àti àìsàn hepatitis C, kò han kedere bóyá títàn kálẹ̀ àìsàn náà n wá láti ipasẹ̀ lílo òògùn ni, èyí tí a kò mẹ́nu bà tàbí ní ipasẹ̀ bíbáraẹnilòpò tilẹ̀ ni.[5] Ẹri ti n gbe eyi lẹ̀sẹ̀ ni pe ko si ewu fun àwọn onibaalopọ lakọ-labọ ti wọn ko ni ibasepọ pelu àwọn miran.[23] ọna iba-ara-eni lo pọ ti o ba fa ọgbẹ́ ti o jin sinu eran inu iho-idi, bi i dídó-iho-idi, tàbí ẹyọ ti o sele ni igba ti eni kan ba ni àisàn gbajumọ, ninu eyi ti àisàn HIV tàbí kikọ-ila-abẹ, eyi ti o le mu ewu lowo.[23] Ijoba orile-ede Amerika gba ni niyanju pe ki a lo kọndọọmu fun àwọn eniyan ti wọn ni onibaalopọ ti o pọ̀ sita lati lè dena àìsàn hepatitis C.[24]
Lílu ihò-oge sí ara
àtúnṣeFínfín-ara a maa se atọna ewu àìsàn Hepatitis C ni ilọpo meji sí mẹta ju àwọn ọna miran lọ.[25] Eyi le waye nipasẹ àwọn irin-iṣẹ́ tí a kò bọ̀ ní omi gbígbóná tàbí kí aró ti wọn lò ní idọti ninu.[25] Ara-fínfín tàbí lilu iho-oge si ara ti wọn n se ni bi aarin ọdun 1980 tàbí eyi ti àwọn ti kò kọ ise naa n se ni o jẹ eyi ti o n ko ni lominu jọjọ, ni iwọn bi o ti je pe ọna ti wọn n gba bọ àwọn irin-iṣẹ́ naa ní omi gbígbóná le ma ba oju mu tó ni iru ibi bẹẹ. O dabi pe ewu naa si kuku ga nigba ti a ba n so nipa ara-fínfín.[25] o fẹrẹ to ilaji àwọn elewon ti wọn maa n se àpínlò àwọn irin-iṣẹ́ fínfín-ara naa ti wọn kò bọ ní omi gbígbóná.[25] O ṣòro ki ara-fínfín ti a ṣe ni ile-oge ti o ni iwe-aṣẹ fa àisàn HCV si ago-ara.[26]
Fífi ra kan ẹjẹ̀
àtúnṣeÀwọn ohun itọju ara bi i abẹfẹlẹ, burọọsi-eyin, ati àwọn irin-iṣẹ́ ṣíṣe ọwọ tàbí fun ṣíṣe ẹ́sẹ́ lóge lè kan ẹ̀jẹ. Pínpín wọn lò lè ṣe okunfa ewu àisàn HCV.[27][28] Àwọn eniyan ni lati ṣọra pelu ọgbẹ́ ati egbo tàbí àwọn ohun miran ti o le mu ara ṣe ẹ̀jẹ.[28] Eniyan ki i ko àìsàn HCV nipa ara-kan-ara lasan, bi i didi mọ ni, fifi-ẹnu-ko-ẹnu, tàbí nipa ajọlo ohun-elo ijẹun tàbí ohun-elo sise-ounje.[28]
Kiko arun ọmọ láti ara Ìyá
àtúnṣeKiko àìsàn hepatitis C lati ara iya si ara omo ko to ida mewaa ninu ogorun un lara àwọn ti wọn loyun.[29] Kò si odiwọn kankan ti o yi ewu yii pada.[29] Kiko àìsàn le sele ni akoko oyun tàbí ni akoko ibimo.[17] Irobi ti o gun maa n saaba fa ewu kiko àìsàn naa.[11] Ko si eri kankan pe fifun-omo-ni-ọyàn maa n tan àìsàn HCV kale; sibe, ki iya naa ti o ni àìsàn yii ma se fun ọmọ ni ọyàn mu ti ori ọyàn re ba la tàbí ti o ba n se ẹ̀jẹ,[30] tàbí ti kokoro-àìsàn ba pọ lara re.[17]
Ìmọ̀lára-àìsàn
àtúnṣeLara àwọn ayẹwo ara fun àisàn hepatitis C ni: ayẹwo ota-ara fun HCV , ayẹwo ELISA, ayẹwo Western blot, ati ayẹwo RNA HCV .[5] Polymerase chain reaction (PCR) le kẹfin HCV RNA ni bi i ọṣẹ kan si meji leyin àisàn, nigba ti àwọn ota-ara yii le gba akoko ti o gun si i ki wọn to le ko ara jọ lati fi ara han.[12]
Àisàn hepatitis C je àisàn ti o ti wọ ara gan an eyi ti kòkòrò-àrùn hepatitis C n ba ara wọ ija ju osu mefa lọ, ti o da lori pe RNA re n be ninu agọ-ara.[8] Nitori pe àrùn ti o ba ti wọ ara ki i ni ìmọ̀lára-àìsàn fun aimọye odun,[8] àwọn onise-iwadii-ilera a maa kẹfin re nipasẹ ayẹwo iṣẹ ẹdọ tàbí ni akoko ti wọn ba n se ayẹwo àwọn ti o seese ki àrùn wọle si lara. Sise ayẹwo ko le sọ iyatọ laarin boya àisàn ga ni ara tàbí pe o ti wọ ẹni naa lara gan.[11]
Àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀
àtúnṣeÀyẹ̀wò àrùn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ C bẹrẹ pelu àwọn àyęwÒ ęję lati ṣawari awọn ohun ajoji ara si HCV nipa lilo ęnsáímùimmunoassay. [5] bi ayẹwo yii ba jẹ bẹẹ, a o tun ṣe ayẹwo lẹẹkeji lati jẹri immunoassay ati lati mọ bi o se nípọn-sí. [5] Amúpọ immunoblot assay ṣèjẹri immunoassay naa, ati pe iṣokunfa isopọ HCV RNA polymerase fa ilewu. [5] Bi kobasi RNA ti immunoblot is jẹ bẹẹ, iru eniyan naa ni àkóràn tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n ó ṣàmúkúrò rẹ̀ yala nipa itọju ni tabi lọgan; bi immunoblot naa kobasi, aṣiṣe ni immunoassay naa. [5] Yoo to ọsẹ mẹfa si mẹjọ lẹhin akoran ki ayẹwo immunoassay to jẹ bẹẹ. [9]
Ẹnsáímù ẹdọ jẹ oriṣirisi ni ibẹrẹ àkÓràn;[8] ní gbígbé gègélé wọn maa n dagba ni ọsẹ meje lehin akoran.[9] Ẹnsaimu ẹdọ ko farajọ àrùn tÓ nípọn. .[9]
Iṣayẹwò tiṣu
àtúnṣeIṣayẹwo tiṣu Ẹdọ le ṣafihan ipele, tí ẹdọ ti bàjẹ dé ṣugbọn ewu wa ninu ilana yii. [3] Irufẹ awỌn iyàtỌ ti iṣayẹwo tiṣu se àwárí rę ni limfosaites laarin tiṣu ẹdọ, awọn limfọidi foliku ninu pọta tíráyádì, ati awon iyipada si apo ÒrÓ-ǹ-ro. [3] Oriṣirisi ayẹwo ẹjẹ lowa ti o gbiyanju lati safihan ipele idibàję ati ìdínkù ìdí fun iṣayẹwo tiṣu. [3]
Iṣewadi
àtúnṣeBii márùn ún si àádỌta ninu ỌgỌrun awọn eniyan ti o ni àrùn ni United States ati Canada ni o mọ ipo àrùn wọn. [25] Iṣayẹwo jẹ ohun ti awọn eniyan ti o wa nipele ewu gbọdọ ṣe, eyi ti o si kan awọn ti o n fíra pẹlu. [25] Iṣewadi ṣe pataki fun awọn ti o ni arun ensaimu ẹdọ niwọn igba ti o jẹ wipe eyi nikan ni ami ìdánimỌ fun Ògbó-ló-gbὸó àrùn jẹdọjẹdọ ti o le. .[31] Iṣayẹwo lóórè-kóὸrè ko se ìtęwọgbà gba ni United States.[5]
Dídádúró
àtúnṣeTi ti di 2011, ko si abęrę fun àrùn jẹdọjẹdọ C. Awon abęrę ṣi wa ni ipele imudagba, ati wipe awọn kan si ti fi esi iwunilori han.[32] Àgbájọpọ awọn ìlànà ìdádúró, gẹgẹbi awọn ètὸ fun ipàsípààrọ abęrę ati itọju fun oὸgùn ìlòkulò, jęki ewu àrùn jẹdọjẹdọ C laarin awọn to ngbabęrę oògùn inu iṣan dinku si ìdá marun-din-lọgọrin ninu ọgọrun.[33] Iṣewadii awọn olufęjẹsilẹ ṣe pataki ni orilẹ- ede, gẹgẹbi o ṣe wa ni ibamu pęlu titęle àkíyèsára gbogbogbòò ni ti ilera.[9] Ni awọn orilẹ ede ti awon abęrę ti a ti fọ kὸ pọ tó, awọn olutọju gbọdọ funni l’ogun lilo dipo gígún ni abẹrẹ.[11]
Itọju
àtúnṣeHCV nfa akoran lile laarin àádọta si ọgọrin ninu ọgọrun awon ẹni ti o ni akoran. Lapapọ ida ogoji si ọgọrin ninu ọgọrun awon to ni àrùn na ni o ri ìwὸsan nipa ìtọjú. [34][35] Ni ọna ti ko wọpọ, akoran le lọ laiṣe itọju.[6] Awọn ti o ni ògbólógbòó àrùn jẹdọjẹdọ C gbọdọ yẹra fun ọtí-líle ati oògùn to lewu fun ẹdọ,[5] ki wọn si gba abęrę àjęsára fun hepatitis A ati hepatitis B.[5] Awọn ti o ni sí-ró-sì-sì gbọdọ ṣe ayẹwo Ọtira-sá-ùnd fun arun ẹjẹ jẹdọjẹdọ.[5]
Oògùn Lílò
àtúnṣeAwọn ti o ni akoran segesege ẹdọ HCV to daju gbọdọ lọ fun itọju. [5] Itọju tó wà bayi jẹ apapọ pegylated interferon ati ogun asodisi kokoro ribavirin fun ọsẹ 24 tabi 48, ti o da lori irufẹ HCV.[5] Abajade to yanranti nṣẹlẹ fun àádọta si ọgọta ninu ìdá ọgọrun awọn eniyan ti a ṣetọju.[5] Àpapọ yala boceprevir tabi telaprevir pẹlu ribavirin ati peginterferon alfa nse iranlowo fun aṣodisi kὸkὸrὸ fun irúfẹ ẹjẹ 1 ti abajade arun jẹdọjẹdọ C.[36][37][38] Awon abayọri fun itọju wọpọ; idaji awọn ti a tọju ni, ami ìdánimọ àrùn ayỌkęlę; ati irírí kẹta ní ìṣÒro imọlára.[5] Itọju ni oṣu mẹfa akọkọ dara ju itọju lẹhin ti àrùn jẹdọjẹdọ C ba ti lewu.[12] Bi eniyan kan bani akoran titun ti ko si tii kuro lẹhin oṣu mẹjọ si mejila, a gba iru ęni bęę niyanju lati lo pegylated interferon fun Ọsę mẹrinlelogun.[12] Fun awọn ti o ni talasémíà (a blood disorder), ribavirin dara, ṣugbọn yoo fa gbigba ẹjẹ.[39]
Awọn alatilẹhin sọ pe itọju nipa lilo oògun ibilę yoo wulo fun àrùn jẹdọjẹdọ C pẹlu wàràa thistle, ginseng, ati kọlọida silfa.[40] Sibẹsibe, ko si oògùn ìbílẹ ti o wo àrùn jẹdọjẹdọ C, ko si si àrídájú ẹrí pe oògùn ibilẹ ni agbára lóri kòkòrò na rárá.[40][41][42]
Imọtẹlẹ
àtúnṣeDidaraya nipa itọju yatọ gęgębi irúfẹ ẹyà ẹjẹ ti ję. Dida ara fun igba pipę ję 40-50% ninu awọn eniyan ti o ni irufẹ ẹjẹ 1 HCV pẹlu itọju ọsẹ mejidinlaadọta .[3] Dida ara wa ni ida 70-80% ninu awọn eniyan ti o ni irufẹ ẹjẹ 2 ati 3 HCV pẹlu itọju ọsẹ mẹrinlelogun .[3] Dida ara wa ni ida 65% ninu awọn eniyan ti o ni irufẹ ẹjẹ 4 pẹlu itọju laarin Ọsę mejidinlaadọta. Ẹri itọju arun irufẹ ẹjẹ 6 ko wọpọ, ẹri itọju ti o wa si jẹ bi ọsẹ mejidinlaadọta ni irufẹ iye oògun kanna pẹlu àrùn irufẹ ẹjẹ 1.[43]
Ẹ̀kọ́ ìtànkálę àrùn
àtúnṣe no data <10 10-15 15-20 20-25 25-30 30-35 | 35-40 40-45 45-50 50-75 75–100 >100 |
Laarin 130 ati 170 milionu eniyan, tabi ~3% ida męta ninu Ọgọrun awọn eniyan agbaye, ni o ni arun jẹdọjẹdọ to lewu.[44] Laarin 3-4 miliọnu eniyan ni o ni arun yii lọdọọdun, ati ju 350,000 eniyan ni o n ku lọdọọdun lati ọwọ arun ti o jẹmọ arun jẹdọjẹdọ C.[44] Iye-nísirò ti pọ gidigidi ni 20th century lori adapọ IDU ati ipoogun intravenous tabi lilo ohun oogun laifọ.[11]
Ni United States, ida meji ninu ọgọrun awọn eniyan ni o ni arun jẹdọjẹdọ C,[5] Pẹlu 35,000 si 185,000 oriṣirisi awọn isęlę titun lọdọọdun. Iye-nísirò ti dinku ni iwọ oòrùn lati 1990 eyi to da lori iṣayẹwo ẹjẹ fínnífínní ki a to fa sara ẹlòmíran.[12] Ikú ọdọọdún nipase HCV ni United States to lati ęgbęrùn męjọ si ęgbęrùn męwàá. Ireti nipe iye eniyan to nku yoo pọsi nigba ti awọn ti ó kó àrun nipa gbigba ęję sara ba ṣàìsàn tabi ku ṣaaju ayẹwo HCV.[45]
Iye-nísirò akoran kokoro ga ni awọn orilẹ ede kan ni Afrika ati Asia.[46] Awon orilẹ ede ti o ni iye akoran kokoro ti o ga ni Egypt (22%), Pakistan (4.8%) ati China (3.2%).[44] Giga rẹ ni Egypt so mọ ìdádúró ìpolongo ìtọjú gbogbogbòò fun schistosomiasis, lilo abẹrẹ onídígí ti a ko fọ mọ daradara.[11]
Akọọlẹ itàn
àtúnṣeNi akoko kan laarin awọn ọdun 1970, Harvey J. Alter, Olori Ẹka ti Akoran Arun ni Ẹka Ogun Ifẹjẹ funni ni National Institutes of Health, ati awọn ẹlẹgbẹ iwadii rẹ ṣafihan pe ọpọ- blood transfusion arun jẹdọjẹdọ kii ṣe lati kokoro hepatitis A tabi B. Pẹlu awari yii, akitiyan iwadi agbaye lati ṣawari kokoro yii kuna fun ọdun mẹwa ti o tẹle. Ni 1987, Michael Houghton, Qui-Lim Choo, ati George Kuo ni Chiron Corporation, pẹlu ajọṣepọ Dr. D.W. Bradley lati Centers for Disease Control and Prevention, lo ọna molecular cloning titun lati ṣawari ohun abẹmi aimọ ati imudagba awari ayẹwo.[47] Ni 1988, Alter ṣejẹri kokoro naa nipa jijẹri wíwà rẹ ninu pánẹ̀ẹlì non A non B apẹẹrẹ arun jẹdọjẹdọ. Ni oṣu Igbe (kęrin) 1989, awarii HCV ni a tẹ jade ninu akọsilẹ meji ninu jọ́nà Science.[48][49] Awari yii jasi aṣeyọri toṣee tọkasi ninu awari ati imúgbòòrò itọju aṣodisi kòkòrò.[47] Ni ọdun 2000, Drs. Alter ati Houghton ni a bu ọla fun lati Lasker Award for Clinical Medical Research fun "aṣaju iṣẹ to jasi awari kokoro ti o n fa arun jẹdọjẹdọ C ati imudagba ọna ti o n din ewu ti o rọmọ ifẹjẹ funni ti o fa arun jẹdọjẹdọ ni U.S lati ida 30% ni 1970 di ofo ni 2000."[50]
Chiron ṣelana fun oriṣirisi iwe aṣẹ lori kokoro ati iwadi rẹ.[51] Gbigba aṣẹ to yanranti lati ọwọ CDC ni a kọ ni 1990 lẹhin ti Chiron san $1.9 million fun CDC ati $337,500 fun Bradley. Ni 1994, Bradley pe Chiron lẹjọ, o n wa ọna lati fagile aṣẹ naa, o fẹ lati jẹ pe oun wa lara awọn to jumọ ṣawari rẹ, ki o si gba owo itọna. O kọ ipẹjọ naa ni 1998 nigba ti o padanu ẹjọ ni ile ẹjọ kotẹmi lọrun .[52]
Àwùjọ àti àṣà
àtúnṣeThe World Hepatitis Alliance coordinates World Hepatitis Day, waye lọdọọdun ni July 28.[53] Inawo ori arun jẹdọjẹdọ C nipa lori olukuluku ati si awujọ. Ni United States iwọn owo igbe aye arun naa ni a ṣiro si 33,407 USD ni 2003,[54] pẹlu apapọ iye igbin ẹdọ si ara jẹ 200,000 USD ni 2011.Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid parameter in <ref>
tag Ni Canada iye owo ẹkọ itọju aṣodikokoro gaa bii 30,000 CAD ni 2003,[55] nigba ti iye owo ti United States wa laarin 9,200 ati 17,600 ni 1998 USD.Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid parameter in <ref>
tag Ni ọpọ ibi lagbaye ni awọn eniyan kole san owo itọju aṣodikokoro yi nitori wọn koni idábòbò adíyelófò tabi idíyelófò ti wọn ni kole sanwo aṣodikokoro naa. [56]
Ìwádìí
àtúnṣeNi 2011, bii ọgọọrun awon oògùn itọju ni won nse iwadi re lowo fun àrùn jẹdọjẹdọ C.Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid parameter in <ref>
tag Lara awọn oogun naa ni ogun itọju lati wo àrùn jẹdọjẹdọ, immunomodulators, ati cyclophilin oludilọwọ.[57] Awọn ọna tituun itọju yii waye nipa imọsi lori kokoro àrùn jẹdojẹdọ C.[58]
Itọkasi
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Ryan KJ, Ray CG (editors), ed (2004). Sherris Medical Microbiology (4th ed.). McGraw Hill. pp. 551–2. ISBN 0838585299.
- ↑ Houghton M (November 2009). "The long and winding road leading to the identification of the hepatitis C virus". Journal of Hepatology 51 (5): 939–48. doi:10.1016/j.jhep.2009.08.004. PMID 19781804.
- ↑ 3.00 3.01 3.02 3.03 3.04 3.05 3.06 3.07 3.08 3.09 3.10 Rosen, HR (2011-06-23). "Clinical practice. Chronic hepatitis C infection.". The New England journal of medicine 364 (25): 2429–38. PMID 21696309. http://www.casemedicine.com/ambulatory/Continuity%20Clinic/Clinic%20Articles/1)%20July/2)Week%20of%20July%2025th/chronic%20hep%20c.NEJM.pdf.
- ↑ Maheshwari, A; Ray, S, Thuluvath, PJ (2008-07-26). "Acute hepatitis C.". Lancet 372 (9635): 321–32. doi:10.1016/S0140-6736(08)61116-2. PMID 18657711.
- ↑ 5.00 5.01 5.02 5.03 5.04 5.05 5.06 5.07 5.08 5.09 5.10 5.11 5.12 5.13 5.14 5.15 5.16 5.17 5.18 5.19 5.20 5.21 Wilkins, T; Malcolm, JK, Raina, D, Schade, RR (2010-06-01). "Hepatitis C: diagnosis and treatment.". American family physician 81 (11): 1351–7. PMID 20521755. http://www.aafp.org/afp/2010/0601/p1351.html.
- ↑ 6.0 6.1 6.2 6.3 6.4 Chronic Hepatitis C Virus Advances in Treatment, Promise for the Future.. Springer Verlag. 2011. p. 4. ISBN 9781461411918. http://books.google.ca/books?id=6G7mff5DnBQC&pg=PA4.
- ↑ 7.0 7.1 7.2 7.3 Nelson, PK; Mathers, BM, Cowie, B, Hagan, H, Des Jarlais, D, Horyniak, D, Degenhardt, L (2011-08-13). "Global epidemiology of hepatitis B and hepatitis C in people who inject drugs: results of systematic reviews.". Lancet 378 (9791): 571–83. doi:10.1016/S0140-6736(11)61097-0. PMID 21802134.
- ↑ 8.0 8.1 8.2 8.3 Chronic Hepatitis C Virus Advances in Treatment, Promise for the Future.. Springer Verlag. 2011. pp. 103–104. ISBN 9781461411918. http://books.google.ca/books?id=6G7mff5DnBQC&pg=PA104.
- ↑ 9.0 9.1 9.2 9.3 9.4 9.5 Dolin, [edited by] Gerald L. Mandell, John E. Bennett, Raphael (2010). Mandell, Douglas, and Bennett's principles and practice of infectious diseases (7th ed. ed.). Philadelphia, PA: Churchill Livingstone/Elsevier. pp. Chapter 154. ISBN 978-0443068393.
- ↑ Mueller, S; Millonig, G, Seitz, HK (2009-07-28). "Alcoholic liver disease and hepatitis C: a frequently underestimated combination.". World journal of gastroenterology : WJG 15 (28): 3462–71. PMID 19630099.
- ↑ 11.00 11.01 11.02 11.03 11.04 11.05 11.06 11.07 11.08 11.09 Alter, MJ (2007-05-07). "Epidemiology of hepatitis C virus infection.". World journal of gastroenterology : WJG 13 (17): 2436–41. PMID 17552026.
- ↑ 12.0 12.1 12.2 12.3 12.4 Ozaras, R; Tahan, V (2009 Apr). "Acute hepatitis C: prevention and treatment.". Expert review of anti-infective therapy 7 (3): 351–61. PMID 19344247.
- ↑ Zignego AL, Ferri C, Pileri SA, Caini P, Bianchi FB (January 2007). "Extrahepatic manifestations of Hepatitis C Virus infection: a general overview and guidelines for a clinical approach". Digestive and Liver Disease 39 (1): 2–17. doi:10.1016/j.dld.2006.06.008. PMID 16884964.
- ↑ Louie, KS; Micallef, JM, Pimenta, JM, Forssen, UM (2011 Jan). "Prevalence of thrombocytopenia among patients with chronic hepatitis C: a systematic review.". Journal of viral hepatitis 18 (1): 1–7. PMID 20796208.
- ↑ Nakano T, Lau GM, Lau GM, Sugiyama M, Mizokami M (December 2011). "An updated analysis of hepatitis C virus genotypes and subtypes based on the complete coding region". Liver Int.. doi:10.1111/j.1478-3231.2011.02684.x. PMID 22142261.
- ↑ Maheshwari, A; Thuluvath, PJ (2010 Feb). "Management of acute hepatitis C.". Clinics in liver disease 14 (1): 169–76; x. PMID 20123448.
- ↑ 17.0 17.1 17.2 17.3 17.4 Pondé, RA; Mikhaĭlova, A (2011 Feb). "Hidden hazards of HCV transmission.". Medical microbiology and immunology 200 (1): 7–11. PMID 20461405.
- ↑ 18.0 18.1 Xia, X; Luo, J, Bai, J, Yu, R (2008 Oct). "Epidemiology of HCV infection among injection drug users in China: systematic review and meta-analysis.". Public health 122 (10): 990–1003. doi:10.1016/j.puhe.2008.01.014. PMID 18486955.
- ↑ Imperial, JC (2010 Jun). "Chronic hepatitis C in the state prison system: insights into the problems and possible solutions.". Expert review of gastroenterology & hepatology 4 (3): 355–64. PMID 20528122.
- ↑ Vescio, MF; Longo, B, Babudieri, S, Starnini, G, Carbonara, S, Rezza, G, Monarca, R (2008 Apr). "Correlates of hepatitis C virus seropositivity in prison inmates: a meta-analysis.". Journal of epidemiology and community health 62 (4): 305–13. PMID 18339822.
- ↑ Marx, John (2010). Rosen's emergency medicine: concepts and clinical practice 7th edition. Philadelphia, PA: Mosby/Elsevier. p. 1154. ISBN 9780323054720.
- ↑ "Highest Rates of Hepatitis C Virus Transmission Found in Egypt". Al Bawaba. 2010-08-09. Archived from the original on 2012-05-15. Retrieved 2010-08-27.
- ↑ 23.0 23.1 23.2 Tohme RA, Holmberg SD (June 2010). "Is sexual contact a major mode of hepatitis C virus transmission?". Hepatology 52 (4): 1497–505. doi:10.1002/hep.23808. PMID 20635398.
- ↑ "Hepatitis C Group Education Class". United States Department of Veteran Affairs. Archived from the original on 2011-11-09. Retrieved 2014-01-03.
- ↑ 25.0 25.1 25.2 25.3 25.4 25.5 Jafari, S; Copes, R, Baharlou, S, Etminan, M, Buxton, J (2010 Nov). "Tattooing and the risk of transmission of hepatitis C: a systematic review and meta-analysis.". International journal of infectious diseases : IJID : official publication of the International Society for Infectious Diseases 14 (11): e928-40. PMID 20678951. http://natap.org/2010/HCV/tatoohcv.pdf.
- ↑ "Hepatitis C" (PDF). Center for Disease Control and Prevention. Retrieved 2 January 2012.
- ↑ Lock G, Dirscherl M, Obermeier F, et al. (September 2006). "Hepatitis C —contamination of toothbrushes: myth or reality?". J. Viral Hepat. 13 (9): 571–3. doi:10.1111/j.1365-2893.2006.00735.x. PMID 16907842.
- ↑ 28.0 28.1 28.2 "Hepatitis C". FAQ – CDC Viral Hepatitis. Retrieved 2 Jan 2012.
- ↑ 29.0 29.1 Lam, NC; Gotsch, PB, Langan, RC (2010-11-15). "Caring for pregnant women and newborns with hepatitis B or C.". American family physician 82 (10): 1225–9. PMID 21121533.
- ↑ Mast EE (2004). "Mother-to-infant hepatitis C virus transmission and breastfeeding". Advances in Experimental Medicine and Biology 554: 211–6. PMID 15384578.
- ↑ Senadhi, V (2011 Jul). "A paradigm shift in the outpatient approach to liver function tests.". Southern medical journal 104 (7): 521–5. PMID 21886053.
- ↑ Halliday, J; Klenerman, P, Barnes, E (2011 May). "Vaccination for hepatitis C virus: closing in on an evasive target.". Expert review of vaccines 10 (5): 659–72. doi:10.1586/erv.11.55. PMID 21604986.
- ↑ Hagan, H; Pouget, ER, Des Jarlais, DC (2011-07-01). "A systematic review and meta-analysis of interventions to prevent hepatitis C virus infection in people who inject drugs.". The Journal of infectious diseases 204 (1): 74–83. PMID 21628661.
- ↑ Torresi, J; Johnson, D, Wedemeyer, H (2011 Jun). "Progress in the development of preventive and therapeutic vaccines for hepatitis C virus.". Journal of hepatology 54 (6): 1273–85. doi:10.1016/j.jhep.2010.09.040. PMID 21236312.
- ↑ Ilyas, JA; Vierling, JM (2011 Aug). "An overview of emerging therapies for the treatment of chronic hepatitis C.". Clinics in liver disease 15 (3): 515–36. PMID 21867934.
- ↑ Foote BS, Spooner LM, Belliveau PP (September 2011). "Boceprevir: a protease inhibitor for the treatment of chronic hepatitis C". Ann Pharmacother 45 (9): 1085–93. doi:10.1345/aph.1P744. PMID 21828346.
- ↑ Smith LS, Nelson M, Naik S, Woten J (May 2011). "Telaprevir: an NS3/4A protease inhibitor for the treatment of chronic hepatitis C". Ann Pharmacother 45 (5): 639–48. doi:10.1345/aph.1P430. PMID 21558488.
- ↑ Ghany MG, Nelson DR, Strader DB, Thomas DL, Seeff LB (October 2011). "An update on treatment of genotype 1 chronic hepatitis C virus infection: 2011 practice guideline by the American Association for the Study of Liver Diseases". Hepatology 54 (4): 1433–44. doi:10.1002/hep.24641. PMC 3229841. PMID 21898493. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3229841.
- ↑ Alavian SM, Tabatabaei SV (April 2010). "Treatment of chronic hepatitis C in polytransfused thalassaemic patients: a meta-analysis". J. Viral Hepat. 17 (4): 236–44. doi:10.1111/j.1365-2893.2009.01170.x. PMID 19638104.
- ↑ 40.0 40.1 Hepatitis C and CAM: What the Science Says. NCCAM March 2011. (Retrieved 07 March 2011)
- ↑ Liu, J; Manheimer, E, Tsutani, K, Gluud, C (2003 Mar). "Medicinal herbs for hepatitis C virus infection: a Cochrane hepatobiliary systematic review of randomized trials.". The American journal of gastroenterology 98 (3): 538–44. PMID 12650784.
- ↑ Rambaldi, A; Jacobs, BP, Gluud, C (2007-10-17). "Milk thistle for alcoholic and/or hepatitis B or C virus liver diseases.". Cochrane database of systematic reviews (Online) (4): CD003620. PMID 17943794.
- ↑ Fung J, Lai CL, Hung I, et al. (September 2008). "Chronic hepatitis C virus genotype 6 infection: response to pegylated interferon and ribavirin". The Journal of Infectious Diseases 198 (6): 808–12. doi:10.1086/591252. PMID 18657036.
- ↑ 44.0 44.1 44.2 "WHO Hepatitis C factsheet". 2011. Retrieved 2011-07-13.
- ↑ Colacino, ed. by J. M.; Heinz, B. A. (2004). Hepatitis prevention and treatment. Basel: Birkhäuser. pp. 32. ISBN 9783764359560. http://books.google.ca/books?id=KwSWN_QtVLUC&pg=PA32.
- ↑ al.], edited by Gary W. Brunette ... [et. CDC health information for international travel : the Yellow Book 2012. New York: Oxford University. pp. 231. ISBN 9780199769018. http://books.google.ca/books?id=597F4ZVu7eQC&pg=PT231.
- ↑ 47.0 47.1 Boyer, JL (2001). Liver cirrhosis and its development: proceedings of the Falk Symposium 115. Springer. pp. 344. ISBN 9780792387602.
- ↑ Choo QL, Kuo G, Weiner AJ, Overby LR, Bradley DW, Houghton M (April 1989). "Isolation of a cDNA clone derived from a blood-borne non-A, non-B viral hepatitis genome". Science 244 (4902): 359–62. doi:10.1126/science.2523562. PMID 2523562.
- ↑ Kuo G, Choo QL, Alter HJ, et al. (April 1989). "An assay for circulating antibodies to a major etiologic virus of human non-A, non-B hepatitis". Science 244 (4902): 362–4. doi:10.1126/science.2496467. PMID 2496467.
- ↑ Winners Albert Lasker Award for Clinical Medical Research, The Lasker Foundation. Retrieved 20 February 2008.
- ↑ Houghton, M., Q.-L. Choo, and G. Kuo. NANBV Diagnostics and Vaccines. European Patent No. EP-0-3 18-216-A1. European Patent Office (filed 18 November 1988, published 31 May 1989).
- ↑ Wilken, Judge. "United States Court of Appeals for the Federal Circuit". United States Court of Appeals for the Federal Circuit. Retrieved 11 January 2012.
- ↑ Eurosurveillance editorial, team (2011-07-28). "World Hepatitis Day 2011.". Euro surveillance : bulletin europeen sur les maladies transmissibles = European communicable disease bulletin 16 (30). PMID 21813077.
- ↑ Wong, JB (2006). "Hepatitis C: cost of illness and considerations for the economic evaluation of antiviral therapies.". PharmacoEconomics 24 (7): 661–72. PMID 16802842.
- ↑ "Hepatitis C Prevention, Support and Research ProgramHealth Canada". Public Health Agency of Canada. 2003. Retrieved 10 January 2012. Unknown parameter
|month=
ignored (help) - ↑ Zuckerman, edited by Howard Thomas, Stanley Lemon, Arie (2008). Viral Hepatitis. (3rd ed. ed.). Oxford: John Wiley & Sons. pp. 532. ISBN 9781405143882. http://books.google.ca/books?id=nT2dauLXoYAC&pg=PA532.
- ↑ Ahn, J; Flamm, SL (2011 Aug). "Hepatitis C therapy: other players in the game". Clinics in liver disease 15 (3): 641–56. doi:10.1016/j.cld.2011.05.008. PMID 21867942.
- ↑ Vermehren, J; Sarrazin, C (2011 Feb). "New HCV therapies on the horizon.". Clinical microbiology and infection : the official publication of the European Society of Clinical Microbiology and Infectious Diseases 17 (2): 122–34. PMID 21087349.