Jackie Acevedo
Jackie Lynn Acevedo Rangel (tí wọ́n bí ní 18 January 1987) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó wá láti ìlú Mexico, àmọ́ tí wọ́n bí sí ìlú America. Gẹ́gẹ́ bí i agbábọ́ọ̀lù, ipò agbábọ́òlù ata-má-tàsé ló ń gbá.
Personal information | |||
---|---|---|---|
Orúkọ | Jackie Lynn Acevedo Rangel[1] | ||
Ọjọ́ ìbí | 18 Oṣù Kínní 1987 | ||
Ibi ọjọ́ibí | Austin, Texas, United States | ||
Ìga | 5 ft 2 in (1.57 m) | ||
Playing position | Striker | ||
Senior career* | |||
Years | Team | Apps† | (Gls)† |
2012 | Oklahoma City FC (WPSL) | 10 | (12) |
2013 | Houston Aces (WPSL) | 9 | (5) |
2014 | Portland Thorns FC | 2 | (0) |
2015 | Houston Aces | ||
National team | |||
2003 | United States U16 | ||
United States U17 | |||
2006 | Mexico U20 | 2 | |
2013 | Mexico | 1 | (0) |
* Senior club appearances and goals counted for the domestic league only. † Appearances (Goals). |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Acevedo sí ìlú Austin, Texas, ní United States sínú ìdílé àwọn ará Mexico, ó ní àbúrò àti ẹ̀gbọ́n márùn-ún, tí ń ṣe (Jamie Acevedo, Jenny Acevedo, Alexandria King, Victoria King, àti Chancellor King). Ilé-ìwé McNeil High School ní Austin ló lọ, ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ ti Texas State Championship ní ọdún 2004 pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù McNeil. Lẹ́yìn náà ni ó lọ sí University of Tennessee.[2] Acevedo gbá bọ́ọ̀lù fún University of Tennessee fún ọdún kan, ní ọdún 2008 kí ó tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga mìíràn. Acevedo gbá bọ́ọ̀lù fún ọdún mẹ́tá, fún Southern Nazarene University ní Oklahoma. Wọ́n fún ní àmì-ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí i agbábọ́ọ̀lù tó dára jù, láti ọwọ́ Sooner Athletic Conference ní ọdún 2010 àti 2011. Ó ju bọ́ọ̀lù ọgọ́rin (80) sínú àwọ̀n, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n láàárín ọdún méta rẹ̀ ní SNU.[3]
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i agbábọ́ọ̀lù
àtúnṣeẸgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù
àtúnṣeOklahoma City FC
àtúnṣeNí àsìkò 2012 WPSL, Acevedo gbá bọ́ọ̀lù fún Oklahoma City FC ní Women's Premier Soccer League (WPSL). Ó farahàn nígbà mẹ́wàá, ó sì ju bọ́ọ̀lù méjìlá sínú àwọ̀n, èyí tó wà ní ipò kẹta fún ìdíje náà.[4]
Houston Aces
àtúnṣeNí àsìkò 2013 WPSL, Acevedo gba káàpù mẹ́sàn-án fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Houston Aces, níbi tí ó ti ju bọ́ọ̀lù márùn-ún sáwọ̀n, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ mẹ́rin. Wọ́n dárúkọ rẹ̀ mọ́ ẹgbẹ́ All-WPSL. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Houston Aces gbé ipò kejì nínú ìdíje WPSL lọ́dún náà.[4]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Convocatoria de la Selección Femenil para enfrentar a Canadá" (in Spanish). MiSeleccion.mx. Retrieved 19 October 2017.
- ↑ "Tennessee Soccer: Jackie Acevedo". Tennessee Soccer. Archived from the original on 10 August 2014. Retrieved 20 July 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Jackie Acevedo". Portland Thorns. Archived from the original on 10 April 2019. Retrieved 20 July 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 4.0 4.1 "Jackie Acevedo". Portland Thorns. Archived from the original on 10 April 2019. Retrieved 20 July 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)