Jacob Ṣógbóyèga Odùlatẹ̀
olóyè Jacob Ṣógbóyèga Odùlatẹ̀ (1884–1962), tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Blessed Jacob jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pharmacist, olùdásílẹ̀, alápilẹ̀kọ, oníṣòwòàti olùdásílẹ̀ egbògi Alábùkún. [1]
Jacob Ṣógbóyèga Odùlatẹ̀ | |
---|---|
Odulate in his chieftaincy regalia and wearing a saki (specially for chief) over his shoulder | |
Ọjọ́ìbí | Jacob Ṣógbóyèga Odùlatẹ̀ 1884 Ìkòròdú, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà |
Aláìsí | 1962 Creek Hospital, Oníkán, Ìpínlẹ̀ Èkó |
Ibùgbé | Abẹ́òkúta; Ìpínlẹ̀ Ògùn |
Orílẹ̀-èdè | ọmọ Nàìjíríà |
Ẹ̀kọ́ | Elementary School until age of 12; self-taught since then |
Iṣẹ́ | Olùdásílẹ̀ |
Successor | Ṣẹ́gun Odùlatẹ̀ |
Àwọn ọmọ | Dr Jacobson Oladele ODULATE (Eye Surgeon) Segun ODULATE (Physicist & Business Entrepreneur - Successfully ran Alabukun in 70's & 80's Folake Solanke Albert Olukoya Grand Children:Eldest - Julian Olayinka Olatokunbo ODULATE (m) Bola Odulate (f) Akin ODULATE (m) Koye ODULATE (f) I ODULATE (f) Toyin Odulate (f) Dayo Odulate (f) Gboly Odulate (m) |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí Jacob nínú ìdílé olórogún ní ìlú Ìkòròdú, sínú ẹbí alàgbà Odùlatẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1884. Bàba bàá rẹ̀ ni olóyè Odùkànmádé tí ó wá láti inú ẹbí Sẹnlú tí ó jẹ́ ẹ̀ka mọ̀lẹ́bí Ranodu tí ó jẹ́ ìdílé ọba nílú Ìmọ̀ta, ìlú tí ó súnmọ́ Ìkòròdú pẹ́kí pẹ́kí [2] Nígbà tí ó wà ní dédé ọmọ ọdún Mẹ́rìnlá, ó fẹsẹ̀ rìn lọ sílú Abẹ́òkúta ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, tí ìrìn náà sì gbàá ní odidi oṣù mẹ́ta gbáko kí tó dé Abẹ́òkúta. Lásìkò tí ó wà ní Abẹ́òkúta, ó ṣalábàá-pàdé onímọ̀ ìpo oògùn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dókítà Ṣapará, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìmọ̀ ìpo oògùn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.[3][4] Láìpẹ́, Jacob dá ilé iṣẹ́ ìpo oògùn tirẹ̀ tí ó pè ní egbògi Alábùkún, níbi tí ó ti ń po oríṣiríṣi oògùn àtinúdá tirẹ̀.[5].
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Did You Know That Oloye Jacob Sogboyega Odulate Trekked for 3months to Invent the Alabukun Powder?". news-af.feednews.com. Retrieved 2020-05-30.
- ↑ Solanke, 'Folake (2007). Reaching for the stars: The autobiography of 'Folake Solanke. ISBN 9789788088431. https://books.google.com/?id=JsElAQAAIAAJ.
- ↑ Admin. "Jacob Odulate". Littcaf. Retrieved 7 February 2017.
- ↑ "Did You Know That Oloye Jacob Sogboyega Odulate Trekked for 3months to Invent the Alabukun Powder?". news-af.feednews.com. Retrieved 2020-05-30.
- ↑ "Did You Know That Oloye Jacob Sogboyega Odulate Trekked for 3months to Invent the Alabukun Powder?". news-af.feednews.com. Retrieved 2020-05-30.