Jacqueline Wolper Massawe (tí wọ́n bí ní 6 Oṣù Kejìlá, Ọdún 1987) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Tànsáníà

Jacqueline Wolper
Ọjọ́ìbí6 Oṣù Kejìlá 1987 (1987-12-06) (ọmọ ọdún 37)
Moshi, Tanzania
Orílẹ̀-èdèTanzanian
Iṣẹ́Actress, fashion stylist
Ìgbà iṣẹ́2007-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Wolper lẹni tí wọ́n bí tó sì dàgbà ní ìlú Moshi, orílẹ̀-èdè Tànsáníà.[1] Ó lọ sì Mawenzi Primary School fún ètò-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ṣáájú kì ó tó lọ sí àwọn ilé-ìwé bíi Magrath, Ekenywa àti Masai fún ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀.[2] Ó wọ agbo iṣẹ́ fíìmù ti Tànsáníà ní ọdún 2007. Wolper ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù tí ó gbajúmọ̀ tó fi mọ́ Tom Boy – Jike Dume, Crazy Desire, Mahaba Niue, I am Not Your Brother, Chaguo Langu, Dereva Taxi, Shoga Yangu, Red Valentine àti Family Tears.[3] Àwọn ará Kẹ́nyà fiyìn fún Wolper fún àwọn ipa rẹ̀ tí ó kó nínu eré Red Valentine àti Family Tears, èyí tí ó mú kí ó di ọ̀kan lára àwọn òṣèrébìnrin tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ní Tànsáníà. Yàtọ̀ sí iṣẹ́ eré ṣíṣe, Wolper jẹ́ olùdásílè ilé-ìtajà Houseofstylish_tz, ilé-ìtajà aṣọ kan tí ó wà ní ìlú Dar es Salaam.[4][5] Ní ọdún 2018, wọ́n yan Wolper sí ara àwọn ìgbìmọ̀-adájọ́ níbi ìdíje Miss Tanzania, ṣùgbọ́n wọ́n padà yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lẹ́hìn tí ó pẹ́ dé ibi àpèjọ kan.[6]

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wolper bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú akọrin kan tí wọ́n pè ní Harmonize ní Oṣù Kaàrún Ọdún 2016, ṣùgbọ́n àwọn méjèjì pínyà ní Oṣù Kejì, Ọdún 2017.[7] Ó tún ní wọléwọ̀de pẹ̀lú Diamond Platnumz.[8] Bótilèjẹ́pé ó ní ìfẹ́ sí àṣà ilẹ̀ Kẹ́nyà, Wolper sọ́ di mímọ̀ wípé òun kò lè ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú okùnrin ará Kẹ́nyà.[9]

Ńi ọdún 2018, ó kéde pé òún ti di àtúnbí.[10]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "If marriage was about looks, I would be married - Wolper". https://www.standardmedia.co.ke/entertainment/african-news/2001341592/if-marriage-was-about-looks-i-would-be-married-wolper. Retrieved 15 October 2020. 
  2. "Jacqueline Wolper biography". The Circle Media Plus TV. Archived from the original on 14 November 2021. Retrieved 15 October 2020. 
  3. "Jacqueline Wolper". Africultures. Retrieved 15 October 2020. 
  4. "Tanzanian Movie Star, Jacqueline Wolper Steps Out Looking Like a Princess in Ankara styles". Archived from the original on 14 November 2021. https://web.archive.org/web/20211114033538/https://ke.opera.news/ke/en/fashion-beauty/aff979d8dbfd8f567c0d884cb9fed58b. Retrieved 15 October 2020. 
  5. "Money from ‘sponsors’ cursed, says Bongo actress Jacqueline Wolper". https://www.standardmedia.co.ke/entertainment/news/2001377436/money-from-sponsors-cursed-says-bongo-actress-jacqueline-wolper. Retrieved 15 October 2020. 
  6. "The price of lateness! Jacqueline Wolper blocked from judging Miss Tanzania pageant". http://www.ghafla.com/ke/the-price-of-lateness-jacqueline-wolper-blocked-from-judging-miss-tanzania-pageant/. Retrieved 15 October 2020. 
  7. Okoth, Brian (23 February 2017). "Jacqueline Wolper: Why I dumped Diamond Platnumz crony". E-Daily. Archived from the original on 19 October 2020. https://web.archive.org/web/20201019133711/https://edaily.co.ke/entertainment/jacqueline-wolper-why-i-dumped-diamond-platnumz-crony-125802/enews/eafrican/. Retrieved 15 October 2020. 
  8. "15 East African celebrities Diamond Platnumz has dated (Photos)". Pulse Live. 4 November 2019. Archived from the original on 20 October 2020. https://web.archive.org/web/20201020163042/https://www.pulselive.co.ke/entertainment/15-east-african-celebrities-diamond-platnumz-has-dated-photos/nljtzdr. Retrieved 15 October 2020. 
  9. Muchene, Esther (2018). "I can’t date a Kenyan man: Harmonize’s ex-girlfriend Wolper". The Standard. https://www.standardmedia.co.ke/entertainment/local-news/2001291422/i-can-t-date-a-kenyan-man-harmonize-s-ex-girlfriend-jacqueline-wolper. Retrieved 15 October 2020. 
  10. Gesare, Tracy (2018). "Harmonize’s ex-girlfriend Jacqueline Wolper now born again". The Standard. https://www.standardmedia.co.ke/entertainment/african-news/2001294064/harmonizes-ex-girlfriend-jacqueline-wolper-now-born-again. Retrieved 15 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe