James Peace
A bí Kẹ́néẹ̀ti Jèmíìsì Píìsì ní Páísílì (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Paisley) ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹ́sàn-án, ọdún 1963. Ọmọ ilẹ̀ Skọ́tlándì tí ó máa ń kọ orin sílẹ̀, tí ó máa ń tẹ pianó níbi tí wọ́n bá ti ń kọrin ní ìta gban̄gba tí ó sì máa ń ya àwòrán ni.
Ìgbé ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí Jèmíìsì Píìsì ní Páísílí, ní ilẹ̀ Skọ́tlándì ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹ́sàn-án, ọdún 1963. Hẹ́líńsíbọ̀ (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Helensburgh) ni ó ti lo púpọ̀ nínú ìgbà èwe rẹ̀.[1][2] Hẹ́líńsíbọ̀ yìí jẹ́ ibi tí àwọn ọ̀pòlọ̀pọ̀ ènìyàn ti máa n lo oludé. Etíkun kan ní apá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Skọ́tlándì ni ìlù yìí wà. Lára àwọn ẹbí rẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ọnà (bí àpẹẹrẹ Jọ̀ọ́nú Makihíì, èdè Gẹ̀ẹ́sì: John McGhie) ó sì tún bá Fẹlíìsì Bọ́ǹsì (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Felix Burns) tan, ẹni tí ó jẹ́ olùṣẹ̀dá orin tí ó ṣeé jó sí ní àádọta ọdún àkọ́kọ́ ní sẹ́ńtúrì ogún.[1][3] Láti-ọmọ ọdún mẹ́jọ ni ó ti bẹ̀rẹ̀ síí kọ́ iṣẹ́ pianó. Nígbà tí ó di ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni ó ṣe eré ìta gban̄gba rẹ̀ àkọ́kọ́ níbi tí ó ti ń fi orin Síkọọti Jópìlìn (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Scott Joplin) dá àwọn ènìyàn lára yá. Ní ọdún méjì lẹ́yìn èyí, wọ́n gbà á sí Ilé-ẹ́kọ̀ gíga Ajẹmọ́ba Ilẹ̀ Sìkọ́tíláǹdì fún ìkọ́ni ní Díràmà àti Músíìkì (báyìí, wọ́n ń pe ilé-ẹ̀kọ́ yìí ní Royal Conservatoire of Scotland).[1][2][3][4] Ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí, òun ni akẹ́kọ̀ọ́ (tí kìí ṣe pé ó ń fi iṣẹ́ síṣe mọ́ ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ) tí ó kéré jù láti-ìgbà yẹn títí di ìsisìyí. Ní ọdún 1983, ó jade ní Yunifásítì Glasgow pẹ̀lú oyè B.A., ìyẹn oyè àkọ́kọ́ nínú ìpìlẹ̀-ẹ̀dá.[4][5] Inú iṣẹ́ ìkọ́ni ní pianó ni ó ti gba oyẹ̀ yìí. Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ó gba dípúlọ́mà nínú músíìkì ṣíṣe lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe eré Pianó Mẹ̀ǹdélisọ̀ùn àkọ́kọ́.[1] Àwọn òṣèré RSAMD ni wọ́n jọ ṣe eré yìí.[6] Léyìn ìgbà tí ó ti fi ẹ̀kọ́ kíkọ́ àìgbagbẹ̀fẹ̀ sílẹ̀ (ìyẹn nígbà tí ó ti pa ti a ń kàwé nílé-ẹ̀kọ́ tì), ọ̀pọ̀ ibi ní wọ́n ti máa ń fẹ̀ kí ó wá ṣeré pianó fún àwọn. Ó gbé Ẹ́dińbọ̀rọ̀ (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Edinburgh) ní ọdún 1988 títí di ọdún 1991.[1][2]
Jèmíìsì Píìsì ń gbé ní Báàdì Náòhàíìmù (Èdè Jẹ́mánì: Bad Nauheim), ní ilẹ̀ Jẹ́mánì (Èdè Jẹ́mánì: Bundesrepublik Deutschland) láti-ọdún 1991 títí di ọdún 2009.[6][7][8] Ní ọdún 1998, ọ́ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa táńgò ó sì ṣe Tango escocés (Táńgò àwọn ará ilẹ̀ Skọ́tlandì).[8][9] Ìmísí ìfi pianó ṣeré táńgò ni ó darí rẹ̀ láti-ṣeré yìí. Ní ọdún 2002, ó di ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́lẹ́ẹ̀jì Múísìkì ti ìlú Fikitóríà.[3][8] Ní ọdún kan náà, ó gbé eré àdánìkan ṣe lọ sí àríwá ilẹ̀ Jẹ́mánì[10] ní oṣù kẹ́sàn-án/oṣù kẹ́wàá ọdún náà ó sì lọ sí òpin gbùngbùn ìlà oòrùn ní oṣù kọkànlá ọdún kan náà níbi tí ó ti ṣeré ‘Táńgò ketàdínlógún’’ ní Họ́ng Kọngì.[8][9][10][11][12]
Ní àwọn ọdún tó tẹ̀lé èyí, ilẹ̀ Úróòpù ni ó wá dojú eré rẹ̀ kọ láìronú nípa ibòmíràn mọ́ ní sáà yìí. Ó ti ṣeré ní àwọn olú-ìlú wọ̀nyí: Amsterdam, Áténì,[13] Berlin,[14] Brussels, Hẹlisíńkì,[15] Lisbon,[16] Lọ́ńdọ̀nù, Madrid,[17] Oslo,[18] Reykjavík[19] àti Fìẹ́nnà.[20]
Ní ọdún 2008, ó di ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́lẹ́ẹ̀jì Músíìkì ti ìlú Lọndọnu fún ìmọ̀rírì àwọn ohun tó ti gbé ṣe fún táńgò.[1]
Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti lo àkókò díẹ̀ ní Ẹ́díńbọ̀rọ̀[3] ó padà sí ilẹ̀ Jámìnì ní oṣù kejì ọdún 2010 ó sì ń gbé ní Wiesbaden.[1][3] Eléyìí tún jẹ́ kí èrò láti-ṣe nǹkan tuntun sọ sí i lọ́kàn ó sì ṣe fíìmù àwọn kan lára orin rẹ̀. Fíìmù tí ó ń fi ìdì òdodo mulẹ, ìyẹn “K. Jèmíìsì Píìsì ní Wiẹsìbadín”, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn eré wọ̀nyí.[21][22]
Àwọn Oyè tí a Gbà fún Ẹ̀kọ́ tí a Kọ́
àtúnṣe● Ipò Kìíní, Ìdíje Aginẹẹsi Mílà (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Agnes Millar Prize for sight-reading). Glasgow, ọdún 1983[4]
● Ipò Kìíní, Ìdíje Dúníbàrìtọ́nìshíìrì EIS (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Educational Institute of Scotland Prize for piano accompaniment). Glasgow, ọdún 1984[4]
● Ẹ̀bùn níbi àròkọ Sìbẹ́líọ̀sì, Glasgow, ọdún 1985[4]
● Dípúlọ́mà tí a fi dá ni lọ́lá, Ìdíje Gbogbogbòò Àròkọ TIM (Èdè Ítálì: Torneo Internazionale di Musica). Rómù, ọdún 2000[1][2][5]
● Dípúlọ́mà tí a fi dá ni lọ́lá ti IBLA Foundation. New York, ọdún 2000[1][2][5]
● Mẹ́dà ìràntí ti Ẹgbẹ́ Abèjì ti Pianó Àgbáyé. Tokyo, ọdún 2002[1][2][5][23]
● Mẹ́dà Góòlù ti International Academy ti “Lutèce”. Parisi, ọdún 2005[1][2]
Àwọn Músíìkì tí ó Ṣe Kókó tí ó Jẹ́ Àkọsílẹ̀
àtúnṣe•Omi tí ó ń ti ibi gígà sàn wálẹ̀ (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: The Waterfall)[24]
•Àwọn Ìdìílì (Èdè Gẹ̀ẹ́sì Idylls)
•Orin òwúrọ̀ àrọrakọ (Èdè Faransé: Aubade)
•Omi ojú tí kò máriwo dání (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Silent Tears)
•Ewé tí a ti gbàgbé (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Forgotten Leaves)
•Bàlàádì (Èdè Faransé: Ballade)
•Àṣeyẹ fún ìránti nọńba 1 (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Ceremonial March No.1)
•Àṣeyẹ fún ìránti nọńba 2 (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Ceremonial March No.2)
•Góòlù ti Ọtọ́ọ̀mù (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Autumn Gold)[25]
•Orin ayérayé (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Eternal Song)[1]
•“Fún Jọ́jíà” (Èdè Jọ́jíà: საქართველოსთვის) (Ohun tí a kọ sílẹ̀ fún kíkọ: Tamari Chikvaidze, Zurabi Chikvaidze àti James Peace)
Ìbáṣepọ̀ tí ó bá àwọn ará ìta ní
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 1.10 1.11 1.12 Birgitta Lampert. “Láìsí àwọn ohùn tó máa ń bíni nínú”. Wiesbadener Tagblatt (Magasín-ìn-ní Jámìnì), ọjọ́ kẹ̀wá, oṣù kejì, ọdún 2011
- ↑ 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 Julia Anderton. “Táńgò tó dàbí ìtàn adùn-tó-korò”. Wiesbadener Kurier (Magasín-ìn-nì Jámìnì), ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kẹta, ọdún 2012
- ↑ 3.0 3.1 3.2 3.3 3.4 Sabine Klein. “Orin mi dàbá èmi fúnraàmi” - ó níí ṣe pẹ̀lú ìfẹ́”. Frankfurter Rundschau (Magasín-ìn-ní Jámìnì), ọdún 1992 (ìtẹ̀jáde 254), ojú-ìwé 2
- ↑ 4.0 4.1 4.2 4.3 4.4 G. Müller. “Ẹ̀mí pianó ń jó táńgò”. Kulturspiegel Wetterau (Magasín-ìn-ní Jámìnì), ọjọ́ kẹtàndínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2001, ojú-ìwé 5
- ↑ 5.0 5.1 5.2 5.3 Deutsche Nationalbibliothek. “James Peace”
- ↑ 6.0 6.1 “James Peace”. FRIZZ (Magasín-ìn-ní Jámìnì), oṣù kìíní, ọdún 2012, ojú-ìwé 5
- ↑ Manfred Merz. “Ilé aláwọ́ tí ó rọ̀ mọ́ ìfẹ́ tí ó mú mímọ̀-ọ́nṣe dání tí ó sì wọni lára”. Wetterauer Zeitung (Magasín-ìn-ní Jámìnì), ọjọ́ kejìlá, oṣù kọkànlá, ọdún 1992, ojú-ìwé 19
- ↑ 8.0 8.1 8.2 8.3 "James Peace”. The Tango Times (Magasín-ìn-ní Níú Yọòkì). Ní ìgbà òtútù, (ọdún) 2002-2003. ìtẹ̀jáde 39. Ojú-ìwé 1 sí 5
- ↑ 9.0 9.1 9.2 National Library of Scotland. “Tango escocés”
- ↑ La Cadena (Magasín-ìn-ín Dọ́ọ̀jì). Oṣù kẹ́sàn-àn, ọdún 2002, ojú-ìwé 26
- ↑ Tangotang (Ìwé-àtẹ̀jáde Họ́ńgì Kọǹgì). Ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹ̀wàá, ọdún 2002
- ↑ “James Peace”. South China Post (Ìwé-ìròyìn Họ́ńgì Kọńgì), ọjọ́ kẹ́sàn, oṣù kẹ̀wàá, ọdún 2002
- ↑ Magasín-ìn-ní kékeré tí ètò orin kíkọ ìta gban̄gba wà nínú rẹ̀ (Àtẹ́ẹ̀nì). {Για σένα, Αγγελικη}. Ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹ̀wàá, ọdún 2016
- ↑ Tangodanza (Magasín-ìn-ní Jámìnì). Oṣù kìíní, ọdún 2002 (9)
- ↑ Ìwé-ìkéde ètò orin kíkọ ìta gban̄gba (ìrìnàjò afẹ́ orin kíkọ ìta gban̄gba Fínlándì, ọdún 2014)
- ↑ Ìwé-ìkéde ètò orin kíkọ ìta gban̄gba (ìrìnàjò afẹ́ orin kíkọ ìta gban̄gba Pọ́rtúgàl, ọdún 2016)
- ↑ Ìwé-ìkéde ètò orin kíkọ ìta gban̄gba (ìrìnàjò afẹ́ orin kíkọ ìta gban̄gba Sípéènì). «¡Feliz cincuenta cumpleaños, 2013!».
- ↑ Listen.no. Konsert, James Peace (Flygel). Munch Museum (ilẹ́ ọnà). Ọjọ́ kẹrindilógún, ọsù kẹ̀wàá, ọdún 2004
- ↑ Ríkarður Ö. Pálsson. “Skozir Slaghörputangoár”. Morgunblaðið (Ìwé-ìròyìn Íslándí), ọjọ́ kẹrìnlá, ọsù kẹ̀wàá, ọdún 2004
- ↑ Magasín-ìn-ní kékeré tí ètò orin kíkọ ìta gban̄gba wà nínú rẹ̀ (Fienna). Ọjọ́ kẹtàlelógún, oṣù kìíní, ọdún 2005
- ↑ 21.0 21.1 National Library of Scotland. “K. James Peace in Wiesbaden”
- ↑ 22.0 22.1 Deutsche Nationalbibliothek. “K. James Peace in Wiesbaden”
- ↑ Ẹgbẹ́ Abèjì tí Pianó Àgbáyé. Ó ṣe Àkọsílẹ̀ Àwọn tí ó gba Ẹ̀bùn (Tokyo)
- ↑ Wiesbadener Staatstheater (magasín-ìn-ní kékeré tí ètò orin kíkọ ìta gban̄gba wà nínú rẹ̀), oṣù kẹ́sàn-àn, ọdún 2021
- ↑ Schwäbische Post. “Ohùn faolín-ìn-nì ga sókè réré ju ti àwọn òṣèré”. Ọjọ́ kẹrìn, oṣù kẹfà, ọdún 1994