Jenna Marie Ortega (tí a bí ní ọjọ́ ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gún oṣù kẹsàn-án ọdún 2002) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣeré nínú àwọn fíìmù láti ìgbà èwe rẹ̀, ó sì gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ nínú eré Jane the Virgin (2014–2019). Ó gbajúmọ̀ si lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí ó ṣe Harley Diaz nínú eré Disney kan, Stuck in the Middle (2016–2018), ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ Imagen Award fún ipa rẹ̀ nínú fíìmù yìí. Ó tún kópa Ellie Alves nínú fíìmù You ní ọdún 2019 àti nínú fíìmù Yes Day (2021) tí Netflix ṣe.

Jenna Ortega
Ortega ní ọdún 2022
Ọjọ́ìbíJenna Marie Ortega
27 Oṣù Kẹ̀sán 2002 (2002-09-27) (ọmọ ọdún 22)
Coachella Valley, California, U.S.
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́2012–ìsinsìnyí
Jenna Ortega

Ortega kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù bi The Fallout (2021), Scream àti X (méjèèjì ní ọdún 2022), àti Scream VI ( ní ọdún 2023). Ní ọdún 2022, ó kópa Wednesday Addams nínú fíìmù Netflix tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Wednesday, èyí sì mú kí wọ́n yàn fún àwọn tí ó le gba àmì-ẹ̀yẹ Golden Globe àti Screen Actors Guild Awards.

Ìpìlẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Jenna Marie Ortega[1] ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gún oṣù kẹsàn-án oṣù 2002,Coachella Valley ní California ni wọ́n bí sí, òun ni ọmọ kẹrin nínú mẹ́fà.[2] Bàbá rẹ̀ wá láti Mexico, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Mexico àti Puerto Rica.[3][4]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Àdàkọ:Cite instagramÀdàkọ:Cbignore
  2. "Disney Channel – Stuck in the Middle – Bios". DisneyABCPress. Archived from the original on May 1, 2016. Retrieved April 21, 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Ortega, Jenna (October 1, 2016). "Jenna Ortega: "I Am Extremely Proud of Where I Come From"". Pop Sugar. https://www.popsugar.com/latina/Jenna-Ortega-Her-Mexican-Puerto-Rican-Background-42227222. 
  4. Leonowicz, Rex (August 15, 2016). "Jane the Virgin's Jenna Ortega Fights Anti-Immigration Rhetoric". Teen Vogue. http://www.teenvogue.com/story/jane-the-virgin-jenna-ortega-fights-anti-immigration-rhetoric.