Jill Levenberg
Jill Levenberg (tí a bí ní 20 Oṣù Kẹẹ̀sán, Ọdún 1977) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Gúùsù Áfríkà.
Jill Levenberg | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 20 Oṣù Kẹ̀sán 1977 |
Orílẹ̀-èdè | South African |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Cape Town |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeLevenberg gbé ní agbègbè Kensington, il̀ú Cape Town.[1] Láti ìgbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà ló ti ṣe àkọ́kọ́ eré rẹ̀ lóri ìpele nígbà kan tí ó fí kọrin ní ilé-ìṣeré Kensington Civic Centre. Ó kópa nínu ọ̀pọ̀lopọ̀ àwọn eré, bẹ́ẹ̀ ló sì tún jẹ́ alápọn nínu ẹgbẹ́ akorin ní àkókò ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rè. Levenberg lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga University of Cape Town níbi tí ó ti gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ eré ìtàgé àti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Levenberg kópa nínu ọ̀pọ̀lopọ̀ àwọn eré bii Medea, Blood Brothers àti Orpheus in Africa ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Ó gba àmì-ẹ̀ye amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó tayọ jùlọ fún ipa rẹ̀ nínu Orpheus in Africa[2]
Levenberg kópa gẹ́gẹ́ bi Beulah nínu fíìmù ti ọdún 2015 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Abraham. Ní ìbẹ̀rè ọdún 2015, ó ti kópa gẹ́gẹ́ bi Mymoena Samsodien nínu eré tẹlifíṣọ̀nù alátìgbà-dègbà kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Suidooster.[2] Ní ọdún 2020, Levenberg dá àbá pé kí eré náà tún sọ̀rọ̀ lóri ìlóbìnrin púpọ̀, èyítí ó mú kí AB tí ó jẹ́ ọkọ rẹ̀ nínu eré náà fẹ́ Farah gẹ́gẹ́ bi ìyàwó ẹlẹ́kejì.[3]
Ní ọdún 2018, Levenberg kó ipa Ellen Pakkies nínu eré Ellen: The Ellen Pakkies Story, èyí tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu sinimá àgbéléwò.
Levenberg jẹ́ olùjàfẹ́tọ̀ọ́ àwọn òṣèré tí ó sì maá n tako ṣíṣe ayédèru fíìmù.[2] Levenberg tún maá n ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ nípa eré yógà àti eré orí-ìtàgé fún àwọn ọ̀dọ́ ní ìlú Cape Town.[4] Ó jẹ́ elédè Gẹ̀ẹ́sì, Afrikaans, àti Jẹmánì[5]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣe- 2015: A Whistle Blows/Fluit-Fluit (as Gwen Isaacs)
- 2015: While You Weren't Looking (as Yasmin)
- 2015: Uitvlucht (as San)
- 2015: Abraham (as Beulah)
- 2015-present: Suidooster (TV series, as Mymoena Samsodien)
- 2018: Ellen: The Ellen Pakkies Story (as Ellen)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Jill Levenberg on playing Ellen Pakkies: ‘I had to go into a state of disassociation in order to commit the act of murder’". News 24. 4 September 2018. https://www.news24.com/channel/movies/news/jill-levenberg-on-playing-ellen-pakkies-i-had-to-go-into-a-state-of-disassociation-in-order-to-commit-the-act-of-murder-20180904. Retrieved 12 October 2020.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 "A Conversation with Jill Levenberg". Sarafina Magazine. 5 December 2018. https://sarafinamagazine.com/2018/12/05/a-conversation-with-jill-levenberg/. Retrieved 12 October 2020.
- ↑ "Suidooster stars about the polygamy storyline: "There's going to be a lot of fireworks"". News24. 8 October 2020. https://www.news24.com/channel/tv/news/suidooster-stars-about-the-polygamy-storyline-theres-going-to-be-a-lot-of-fireworks-20201008. Retrieved 12 October 2020.
- ↑ "Trying to change youth lives". https://www.netwerk24.com/ZA/Tygerburger/Nuus/trying-to-change-youth-lives-20200303-2. Retrieved 12 October 2020.
- ↑ "Jill Levenberg". APM. Retrieved 12 October 2020.