Joelle Kayembe
Joelle Kayembe Hagen (tí wọ́n bí ní 31 Oṣù Kaàrún, Ọdún 1983) jẹ́ afẹwàṣiṣẹ́ àti òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Kóngò.
Joelle Kayembe | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 31 Oṣù Kàrún 1983 Lubumbashi |
Orílẹ̀-èdè | Congolese |
Iṣẹ́ | Model, actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2014-present |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Kayembe ní ìlú Lubumbashi, ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Òṣèlú ilẹ̀ Kóngò. Ó jẹ́ ọmọ ọlùṣòwò kan ní ilẹ̀ Kóngò tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Kalonji Kayembe.[1][2] Ní ọdún 1994, ó kó lọ sí Gúúsù Áfríkà.[3]
Kayembe jẹ́ àkọ́kọ́ obìnrin adúláwọ̀ tí yóó hàn nínu ìwé ìròyìn Sports Illustrated . Ó tún hàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé ìròyìn míràn bíi Cosmopolitan àti Elle, àti fún ti ìpolówó ọjà kan tí ó ṣe fún Sprite Zero. Kayembe tún maá ṣiṣẹ́ àwòrán àti ilé kíkùn.[4] Kayembe kópa níbi àṣekágbá ìdíje International Supermodel ti ọdún 2005 tí ó wáyé ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà.[5]
Ní Ọjọ́ 27 Oṣù Kẹẹ̀sán Ọdún 2008, Kayembe ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú Bongani Mbindwane. Ṣùgbọ́n látàrí àwọn èdè-àìyedè kan tí ó ṣí yọ láàrin wọn, ilé-ẹjọ́ kan paá láṣẹ fún wọn láti pínyà ní Oṣù Kínní Ọdún 2011.[6]
Kayembe kó ipa Zina nínu fíìmù Jérôme Salle kan ti ọdún 2013 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Zulu.[7]
Ní ọdún 2015, Kayembe ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Trace Foundation láti pèsè àwọn ohun-ìkẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin méjì kan.[3] Ní Oṣù kọkànlá Ọdún 2016, ó ṣe ìgbéyàwó ní ìlú Cape Town.[8]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣe- 2013: Zulu
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Huisman, Bienne (27 June 2010). "'I want R10m to end divorce fight'". Sunday Times. https://www.timeslive.co.za/sunday-times/lifestyle/2010-06-27-i-want-r10m-to-end-divorce-fight/. Retrieved October 13, 2020.
- ↑ "Love child causes big drama". News 24. 2 June 2013. https://www.news24.com/news24/Archives/City-Press/Love-child-causes-big-drama-20150429. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ 3.0 3.1 "Model Joelle helps provide study material". Daily Sun. 7 August 2015. https://www.dailysun.co.za/News/Entertainment/Model-Joelle-helps-provide-study-material-20150807. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ Hawkey, Kim (8 November 2009). "Joelle Kayembe, one of South Africa's sexiest women, thought she was the luckiest woman on earth when businessman Bongani Mbindwane proposed. Now — just a year after their traditional wedding ceremony — Mbindwane wants her out of his life and denies they were married". Sunday Times. https://www.pressreader.com/south-africa/sunday-times-1107/20091108/281556581903643. Retrieved October 13, 2020.
- ↑ "Joelle Kayembe slams cheating dad with protection order!". All4Women. 6 June 2013. https://www.all4women.co.za/222687/entertainment/joelle-kayembe-slams-cheating-dad-with-protection-order. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ Chelemu, Khethiwe (19 November 2010). "Top model thrown out of R5m house". Sowetan Live. https://www.sowetanlive.co.za/news/2010-11-19-top-model-thrown-out-of-r5m-house/. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ Matuntuta, Simamkele (22 November 2017). "Joëlle Kayembe does everything believed to be impossible". GQ. https://www.gq.co.za/girls/models-celebrities/joelle-kayembe-does-everything-believed-to-be-impossible-16562322. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ Tshiqi, Bongiwe (15 November 2016). "Congrats to Joelle Kayembe who recently tied the knot". Bona. Archived from the original on 15 October 2020. https://web.archive.org/web/20201015093734/https://www.bona.co.za/congrats-joelle-kayembe-recently-tied-knot/. Retrieved 13 October 2020.