Johann Rupert
Johann Peter Rupert (tí a bí ní ọjọ́ Kínní oṣù kẹfà ọdún 1950) jẹ́ oníṣòwò ọmọ orílẹ̀ ède South Africa, òun ni ọmọkùnrin Anton Rupert àti Huberte. Òun ni alága ilé isẹ́ Remgro ní South Africa. Láti oṣù kẹrin ọdún 2010 ni ó ti jẹ́ CEO ilé iṣẹ́ Compagnie Financiere Richemont. Rupert àti ìdílé rẹ̀ ni Forbes sọ pé ó lówó julọ ní South Africa ní ọdún 2024, pẹ̀lú owó àti ìkan ìní tí ó tó US$12.0 billion.[2]
Johann Rupert | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1 Oṣù Kẹfà 1950 Stellenbosch, Cape Province, Union of South Africa |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Stellenbosch University |
Iṣẹ́ | Chairman of Compagnie Financiere Richemont SA[1] |
Gbajúmọ̀ fún | Luxury goods |
Olólùfẹ́ | Gaynor Rupert |
Àwọn ọmọ | 3 |
Parent(s) | Anton and Huberte Rupert |
Nípa ayé rẹ̀
àtúnṣeRupert dàgbà ní Stellenbosch, ní ibi tí ó ti lọ ilé ìwé Paul Roos Gymnasium àti Yunifásítì Stellenbosch, láti kó nípa economics àti company law. Ó fi ilé ìwé náà kalẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ isẹ́ òwò, síbẹ̀ síbẹ̀, ní ọdún 2004, Yunifásítì Stellenbosch fún ní honorary doctorate ní Economics.[3]
Ní ọdún 2008, Yunifásítì Nelson Mandela Metropolitan fun ní àmì ẹyẹ doctorate mìíràn.[4]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Johann Rupert & family". Forbes (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-07.
- ↑ "Johann Rupert & family". Forbes (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-09-27.
- ↑ "Chancellor". sun.ac.za. Retrieved 13 October 2015.
- ↑ "Synchronised Speakers | Johann Rupert". synchronisedspeakers.co.za. Archived from the original on 3 September 2018. Retrieved 13 October 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)