John Ezzidio
John Ezzidio (c. 1810 – October 1872) jẹ́ ẹrú Nupe tí ó gba òmìnira tí ó sì padà di oníṣòwò àti olóṣèlú ńlá ní orílẹ̀ èdè Sierra Leone. Wọ́n tu sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ẹrú tí ó ń lọ sí orílẹ̀ èdè Brazil, ó kọ́ iṣẹ́ lábé ọmọ orílẹ̀ èdè Faransé kan, ẹni tí ó kọ bí a ṣe ń kọ àti kàwé. Ezzidio padà dé ipò mayor ìlú Freetown ó sì padà di ara àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ Gómìnà ìgbà náà.
Ìjígbé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n jí Ezzidio, ọmọ ẹ̀yà Nupe gbé fún ẹrú ní agbègbè tí a wá mọ̀ sí Ìpínlẹ̀ Niger lóni,[1] wọ́n sì gbe wá sí ibi tí ẹ̀yà Yoruba wọ́pọ̀ sí. Ní ọdún 1827, wọ́n tá fún àwọn fún àwọn òyìnbó, àwọn òyìnbó sì fi sínú ọkọ̀ omi tí ó ń lọ sí orílẹ̀ èdè Brazil. Royal Navy dá ọkọ̀ náà dúró [2] wọ́n sì tú Ezzidio àti àwọn ẹrú tí ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta míràn kalẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrú tí ó yẹ̀ sálọ Freetown, Sierra Leone ní oṣù kẹwàá ọdún 1827.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Omoigui, Nowa. "A Perspective on Nigeria's Involvement in the Sierra Leone Imbroglio". Urhobo Historical Society. Retrieved 2007-12-31.
- ↑ "John Ezzidio: From Recaptive Slave to Mayor". Sierra Leone Web. Archived from the original on 2007-12-10. Retrieved 2007-12-31.
- ↑ Sanneh, Lamin O (1999). "Abolition and the Cause of Recaptive Africans". Abolitionists Abroad: American Blacks and the Making of Modern West Africa. Harvard University Press. pp. 129. ISBN 0-674-00718-2. https://books.google.com/books?id=6qJ71dqsmboC&pg=PA129.