Johnson Mlambo
Johnson Phillip Mlambo (22 February 1940 – 9 January 2021) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè South Africa[1] láti Johannesburg.
Johnson Phillip Mlambo | |
---|---|
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 22 Oṣù Kejì 1940 |
Aláìsí | 9 January 2021 | (ọmọ ọdún 80)
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Pan Africanist Congress (1959–2021) |
Occupation |
|
Òṣèlú
àtúnṣeÓ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú Pan Africanist Congress (PAC) ní ọdún ní ọdún 1959, kí ó tó di adarí èka rẹ̀ ní Daveyton.
Wọ́n fi pánpẹ́ òfin gbe ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n osù kẹta ọdún 1963, òun àti àwọn méje mìíràn, wọ́n sì rán wọn lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún ogún ní Robben Island. Ní Robben island, àwọn ọlọ́pàà ẹ̀wọ̀n náà fìyà jẹ́ púpọ̀.[2]
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tu sílẹ̀ ní ọjọ́ ogún oṣù kẹfà ọdún 1983, ó tún dara pọ̀ PAC. Wọ́n yàn án sípò akọ̀wé fún Foreign Affairs tí PAC, lẹ́yìn ikú John Nyathi Pokela, wọ́n yàn án sípò alága Azanian People's Liberation Army (APLA), eka ológun PAC, láti ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹjọ ọdún 1985 títí di 1990.[3] Òun ni igbákejì Ààrẹ PAC láti 1990 di 1994.[1]
Ikú rẹ̀
àtúnṣeJohnson kú sí ilé ìwòsàn látàrí COVID-19 ní àárọ̀ ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Kínní ọdún of 2021.[4][5]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "Mlambo, Johnson P.". Contemporary Africa Database ::: People. The Africa Centre. 17 December 2003. Archived from the original on 2004-08-25. Retrieved 2007-05-13.
- ↑ "Johnson Phillip Mlambo - South African History Online". www.sahistory.org.za. Retrieved 2021-01-10.
- ↑ Kondlo, Kwandiwe Merriman (1 January 2004). "The generation of strained intra-PAC relations in exile 1962-1990" (PDF). In the twilight of the Azanian Revolution: the exile history of the Pan Africanist Congress of Azania (South Africa): (1960-1990). University of Johannesburg. pp. Chapter 4, pp 146–246. Retrieved 2006-12-29.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Àdàkọ:Cite tweet
- ↑ Àdàkọ:Cite tweet