Joigny coach crash jẹ́ ìjàmbá ọkọ̀ kan tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀nà ọkọ̀ A6 ní Joigny, Yonne, orílẹ̀ èdè Fránsì ní ọjọ́ kẹta Oṣù kẹfà odún 1990, nígbà tí ọkọ̀ Gẹ̀ẹ́sì double-decker tó lámì kọlù nkan. Ní ìgbìyànju lati ṣe ìfipáju àkókò tó ti ṣòfò, ó wa ọkọ́ tí ó ń sáré rin máìlì méjìdínlọ́gọrin ní wákàtí kan (126km/h) nígbà tí táyà rẹ́ sì fòyọ tí ó kọlu nkan, ó sì pa ènìyàn mọ́kànlá. Wọn kò dá ẹjọ́ yìí fún odún mẹ́tàlá, tí ó fi jẹ́ ẹjọ́ tí ó gùn jù ní ilẹ̀ Fránsì .

Ìjàmbá àtúnṣe

Montego European Travel, tí ó wà ní Wetley Rocks, Staffordshire, bẹ̀rẹ̀ òwò pẹ̀lú ọkọ̀ akérò méjì ní Oṣù kẹrin odún 1990. Wọ́n yà  Pineda Holidays tó wà ní Telford.[1] Ìkan nínú ọkọ̀ yíi gba ènìyàn mẹ́rìndínlọ́gọrin,[2] gbé èrò òkànlélọ́gọ́ta lati Midlands tàbí Liverpool, tí ọjó orí wọn wà láàrín mẹsan sí mẹ́rìndínlọ́gọrin, ẹ̀ṣó mẹ́fà àti awakọ̀, ń padà bọ̀ sí Birmingham lati Nîmes, àwọn kan sọpé ó ń padà bọ̀ lati Costa Brava, Spain.[1][3][4][2] Wọ́n yẹ ọkọ̀ yìí wò ní Oṣù keje ọdún 1989, wọ́n sì tún máa yẹ̀ẹ́wò ní Oṣù keje.[5]

Nígbà tó ń rin ìrìn àjò lọ́nà  àríwá-gúúsù A6, máìlí ọgọrin (130km) gúúsù Paris ní agogo mẹjọ àárọ̀,[5] táyà rẹ̀ sì fòyọ nígbà tí ó ń sáré rin máìlì méjìdínlọ́gọrin ní wákàtí kan (126km/h),[2][1] ogún máìlì fún wákàtí kan (32km/h) bju eré ọkọ́ sísá tí òfin fàyé gbà ní ìgbìyànju lati ṣe ìfipáju àkókò tó ti ṣòfò.[4] Ọkọ̀ náà kọ lu kòtò, ó sì tàkìtì sí òdìkejí, ni ẹsẹ bàtà ọdúrún (91m) kí ó tó dé àlìkámà ààyè tó ti dúró.[1][2] Ó tó wákàtí meṛrin kí wọ́n to rí àwọn èrò fàyọ níbi tí wọn há sí.[1] Kí ìjàmbá yìí tó ṣẹlẹ̀, àwọn èrò sọ̀rọ̀ lórí eré tó ń sá ṣùgbọn obìrin náà kjò dá wọn lóhùn.[2]

Àwọn tó farapa àtúnṣe

Ènìyàn mọkanlá lókú tí tí ọ̀kànlélọ́gọta farapa, mẹ́tàlélọ́gbọ̀n sí dèrò ilé ìwòsàn láìrò tẹ́lẹ̀. Nínú àwọn tí ó kú, mẹ́fà ńbọ̀ lati Telford, Shropshire, marún ńbọ̀ lati West Midlands – ìkan lati  Oldbury, àwọn tókù lati Wolverhampton.[4][2] Ọ̀pò.lọpọ̀ wọn ló joko sí iwájú ọkọ̀.[1] Ọjọ́ orí àwọn tí ìsẹ̀lè yí ṣẹlẹ̀ sí wà láàrin mẹwa sí méjìléláàdọrin.[2] Awakọ̀, John Johnston lati Stoke-on-Trent farapa púpọ̀ sùgbọ́n kò kú.[1] Àyọka Ìwé ìròyìn Evening Standard sọọ́ di mímọ̀ wípé ó ti ń wakọ̀ fún ilé iṣẹ́ fún ọdún mẹwa, ó sì ti ju ọdún méjì tí ó ti ní ìwé àṣẹ làti wa irú ọkọ bẹ́ẹ̀[5] Ìkan lára àwọn tó ku, jẹ́ ọmọ ọdún méjìdińlógún, tí ó sì lóyún.[6] Wọ́n ri wípé táyà ọkọ̀ náà kó fi taratara dára ṣùgbọ́n ó ń ṣiṣẹ́[5]

Ní ìgbà yẹn, ó ṣe pàtàkì kí gbogbo ọkọ̀ tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1988 kí ó ní ohun tí ó lè dínwọ́ eré sísá kù. Àwọn tí wọ́n kọ́ láàrín ọdún 1984 sí 1988 gbọ́dọ̀ ní ohun èlò yìí ní Ọjọ́ kínín Oṣù kérin Ọdun 1990; àwọn tí wọ́n kọ́  láàrín ọdún 1974 sí 1983 gbọ́dọ̀ ní ohun èlò yìí ní Ọjọ́ kínín Oṣù kérin Ọdun 1991. Kò pọn dandan kí ọkọ̀ ní àwọn ìgbánú ijoko. Ní ìgbà yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìdàpọ̀ Yúróòpù kò gbàá.[5]

Ìjàmbá yìí jẹ́ èyí tó burú jùlọ ní orílẹ̀ èdè faransé lati ọdún 1982 tí irú Ìjàmbá bẹ́ẹ̀ pa ènìyàn mẹ́tàléláadọta pẹ̀lú ọmọdé mẹ́rìndínlógójì nígbà tí ọkọ́ náà gbaná nígbà tí ọkọ̀ gbára wọn lẹgbẹ Beaune.[7][1]

Ìlànà òfin àtúnṣe

Wọ́n kọ́kọ́ fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan John Johnston, awakọ̀ náà; Melvin Eardley, tí ó ni Montego European Travel; àti Anthony Mitchard, alákóso Avon Rubber, tí ó ṣe táyà. Wọ́n yọwọ́ nínú èsùn tí wọ́n fi kan Mitchard ní ọdún 2001, ti Eardley ní ọdún 2002.[8][4]

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ atótónu lórí ẹ̀bi àti àṣìṣe òfin, wọ́n ṣe ẹjó Johnston ní Sens ní ọdún 2003, ọdún mẹ́tàlá sí ìgbà tí ìsẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀.[4] Bíótilẹ̀jẹ́pé agbẹjọ́rò fún ijọba gbà pé, ìdádúró ẹjọ́ náà jẹ́ "ibàlórúkọjẹ́" àti pé àwọ́n mọ̀lẹ́bí àwọn tí ìṣẹ̀lwẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ sí lè gba owó lọ́wọ́ ìjọba Faransé, Adájọ́ kọ̀ lati gbá atótónu pé kí wọ́n da ẹjọ́ náà nù.[9][4] Jonston jẹ̀bi àìmọ́mọ̀ pànìyàn, ó sì gba ẹ̀wọ̀n ọgbọ́̀ Oṣù pẹ̀lú ìdánidúro ọkọ̀ wíwà fún ọdún marún.[10] Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ Faransé kọ ìpẹ̀jọ́ ẹ̀bẹ̀, Gẹ̀ẹ́sì kàá sí ìjàmbá ikú ojijì ní Oṣu kẹsan ọdún 2006. Johnston fúnra rẹ̀ kú ní Oṣù kẹjọ ọdún náà lẹ́yìn tí ó pé ọdún méjìdínlaadọrin.[11]

Àwọn àkíyèsí àtúnṣe

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 1.7 "British Tourist Bus Flips in France, Killing 11, Injuring 61". Associated Press. 3 June 1990. Archived from the original on 6 May 2016. http://web.archive.org/web/20160506164452/http://www.apnewsarchive.com/1990/British-Tourist-Bus-Flips-in-France-Killing-11-Injuring-61/id-303a901f931dcd33a26727d2bcceda05. Retrieved 17 January 2016. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 birminghammail Administrator (1 November 2006). "Britons coach crash deaths 'accidental'". Birmingham Mail. http://www.birminghammail.co.uk/news/local-news/britons-coach-crash-deaths-accidental-27534. Retrieved 17 January 2016. 
  3. Michel, Marjorie (23 October 2015). "L'accident de la route le plus meutrier en France depuis 1982" (in French). Sud-Ouest. Archived from the original on 14 March 2016. http://web.archive.org/web/20160314142032/http://www.sudouest.fr/2015/10/23/chronologie-les-accidents-de-la-route-les-plus-meurtriers-en-france-2163435-4626.php. Retrieved 17 January 2016. 
  4. 4.0 4.1 4.2 4.3 4.4 4.5 "Bus driver guilty of 1990 deaths". BBC News. 3 July 2003. Archived from the original on 22 March 2016. http://web.archive.org/web/20160322132820/http://news.bbc.co.uk/2/hi/uk_news/england/staffordshire/3043132.stm. Retrieved 17 January 2016. 
  5. 5.0 5.1 5.2 5.3 5.4 "House of Commons Hansard Debates for 5 Jun 1990". Archived from the original on 8 May 2015. Retrieved 17 January 2016. 
  6. "Justice for father after 18 years". Shropshire Star. Archived from the original on 27 June 2008. Retrieved 17 January 2016. 
  7. "42 die in France’s worst road accident since 1982". The NEWS. Retrieved 17 January 2016. 
  8. "Charges against Avon boss dropped". This Is Wiltshire. Archived from the original on 8 May 2016. Retrieved 18 April 2016. 
  9. "French 'sorry' over inquiry delay". BBC News. 5 June 2003. Archived from the original on 8 May 2016. http://web.archive.org/web/20160508150315/http://news.bbc.co.uk/2/hi/uk_news/england/west_midlands/2967362.stm. Retrieved 17 January 2016. 
  10. "Appeal over 11 coach crash deaths". BBC News. 11 April 2005. Archived from the original on 28 March 2016. http://web.archive.org/web/20160328081432/http://news.bbc.co.uk/2/hi/uk_news/england/4431801.stm. Retrieved 17 January 2016. 
  11. "Accident verdict over coach crash". BBC News. 31 October 2006. Archived from the original on 28 March 2016. http://web.archive.org/web/20160328142914/http://news.bbc.co.uk/2/hi/uk_news/england/shropshire/6101348.stm. Retrieved 17 January 2016.