Ìrẹsì Jọ̀lọ́ọ̀fù

Iresi Jollof jẹ ounjẹ ọkan ti orilẹ-ede Naijiria ti o kọja si gbogbo ẹya ati ẹya ni orilẹ-ede naa, ati laarin awọn ọna oriṣiriṣi ti o le jẹ, “party jollof ...
(Àtúnjúwe láti Jollof rice)

Ìrẹsì Aláṣẹ̀pọ̀ Jọ̀lọ́ọ̀fù ( /əˈlɒf/), jẹ́ ìrẹsì àsèpọ̀ láti ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà. Oúnjẹ yìí jẹ́ àdàpọ̀ ìrẹsì, tòmátì, àlùbọ́sà, àwọn èròjà amóúnjẹ-ta-sánsán, ẹ̀fọ́ àti ẹran papọ́ sínú ìkòkò kàn, pẹ̀lú èròjà, àti pé orísirísi ònà ní àwọn èèyàn ń gbà ṣe oúnjẹ yìí níbikíbi.

Ìrẹsì Jọ̀lọ́ọ̀fù
Jollof rice with stew and garnish
Alternative namesBenachin, riz au gras, ceebu jën, zaamè
TypeRice dish
Region or stateWest Africa[1][2]
Main ingredientsRice, tomatoes and tomato paste, onions, cooking oil, fish, lamb, goat meat, chicken, or beef
Àdàkọ:Wikibooks-inline 

Ìtàn àti ìpìlẹ̀ṣẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n tọ orírun ìrẹsì àsèpọ̀ jọ̀lọ́ọ̀fù lọsí agbègbè Sẹ̀nẹ̀gáḿbíà lábẹ ìjọba Jọ̀lọ́ọ̀fù tàbí Wọ́lọ́ọ̀fù ní ọ̀rúndún kẹrìnlá, èyí tí Sẹ̀nẹ̀gà, Gáḿbíà àti Mọriténíà máa ń dáko ìrẹsì. Orísun àti orírun oúnjẹ báyìí ni "thieboudienne", tí ìrẹsì, ẹja àti ẹ̀fọ́ wà nínú rẹ̀.[3]

Òpìtàn àti Ọ̀jọ̀gbọ́n oúnjẹ àti Iṣẹ Ọ̀gbìn James C. ronú pé òun tí ó wà lókè bá tiẹ jẹ́ òotọ́ nítorí bí ìrèsi ṣe gbajúmò tó ní agbègbè Niger, amò o tún lè jẹ pé òun gán ló fàá kìí iresi dì ìlú mọọkà ni Sẹ̀nẹ̀gà Títí dé ibí tí o dé.

Ó wá dáâbàà pé ìrẹsì náà tán ká agbègbè Málì láàrin àwọn Dyula àti Ejika tí ó di òun tí wọn fí ni ṣòwò, èyí tí wọn fí iṣẹ alágbède ṣe ìkejì, àwọn ìpolówó ọjà kékèké àti iṣẹ ìrẹsì.[2]

Marc Dufumier, tí ó jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n tó gbọyèe gẹgẹ bí Emeritus Professor ní ìmọ̀ ọ̀gbìn oko sọ pé ìrẹsì àsèpọ̀ jọ́lọ́fù jẹ́ oúnjẹ ìgbàlódé, tí ó lè jẹ́ pé láti ipasẹ̀ awọn èèbó tí wọn ń dáko ẹpa ní Sẹ̀nẹ̀gà labẹ ìjọba àwọn elédè faransé ti wọn ń ṣe iṣé èpo rọ̀bì, níbi tí ìrẹsì ó ti pọ, tí ó jé pé wọn lọ ń kò ìresì àfọ́kù lati Àsìá ní apá gúúsù ìwọ̀òrùn..[4]

It may then have spread throughout the region through the historical commercial, cultural and religious channels linking Senegal with Ghana, Nigeria and beyond, many of which continue to thrive today, such as the Tijāniyyah Sufi brotherhood bringing thousands of West African pilgrims to Senegal annually.[5]

Geographical range àti variants

àtúnṣe

Ìrẹsì Jọ̀lọ́fù jé oúnjẹ kan tí ó gbajúmò ní apa iwo oòrùn ní áfíríkà. Orísirísi orúkọ àti èròjà ni wọn máa ń pé àti pé ní wọ́n máa fí ń sèé.;[1] fún àpẹẹrẹ, ní Málì wọn a má pé ní Zaame ní Bamanankan. Jọ̀lọ́fù jẹ́ orúkọ kàn tí wọn yọ jáde lọ́dọ̀ àwọn elédè Wolofu ,[6] amò ní Sénégal àti Gámbíà, orúkọ tí àwọn èèyàn Wolofu ń pé túmọ sí Ceebu jën tàbí Benachin. Ní ọ̀dọ̀ awọn elédè faransé, Riz sí Grand ni wọn ń pé. Wàyí ọ, ládúrú gbogbo gbọ́misi-omi òto yìí, Bákan náà ní ọ tí ṣe ń rí ní gbogbo àgbègbè yìí tí bó tí wá dìlú mọ̀ọ̀ká ní Áfíríkà àti ní àgbáyé lápapọ̀.[2][7][8][9][10]

Àwọn èròjà

àtúnṣe
 
Jollof rice with fish, plantains, cucumber, and tomatoes.

Ìrẹsì jọ̀lọ́fu jẹ́ àpapọ̀ ìrẹsì, òróró, ẹfọ bíi tòmáatì, Àlùbósà,ata rodo, Ata ilé, Aáyù, ata ṣœm̀bọ̀. Láti lè jẹ́ kí ô pọ́n-ọ́n, wọn á má fí tòmáatì sí. Bákan náà ní wọn á máa fí awọn èròjà dídùn bíi, iyọ̀, magí, àwọn spices mìíràn bí curry, àti táàmù lati tún bọ̀ jẹ́ kì ó ta sán sán. Láti tún bọ jékí ó dùn rí, ẹran Adìye, tàbí vTọkí, Ẹja tàbí ẹran náà ó gbẹ́yìn tí ó máa ń bá ìrẹsì Aláṣẹpọ jọ́lọ̀fù lọ.[11][12][3]

Regional variations and rivalry

àtúnṣe

Níbi kí ní áfríkà ní wọn tí ní oríṣi ero, àti ìyàtọ̀ àti bí wọn ti ń ṣe pàápá jùlọ láàrin àwọn ará Gánà, Nàìjíría, Sori lónù, kamẹrúùn, lìbèríà, tí ó jẹ́ pé oníkálukú ní ó pé orílé èdè wọn ní o ní jọ́lọ́fu tí ó dùn jù.[3].[13][14]

Ìrèsì Aláṣẹpọ jọ́lọ̀fù ní orílé èdè Nàìjíríà

àtúnṣe

Oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni wọn máa ń gbà ṣe irú ìrẹsì yìí ní Nàìjíríà, amò èyí tí ó jẹ́ ìpìlẹ ní pé, tí a bá fẹ ṣe Ìrèsì yìí, ìrẹsì tí ó gún ni wọn máa sábà lò, tòmáatì, ata rodo, òróró àti magí. Gbogbo èròjà yìí, inú kókó kàn ní gbogbo rẹ yóò wà, èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran, ata díndín ti wa nílé. Nígbà tí gbogbo èròjà yìí bá gbóná tan ní a tó lè da ìrẹsì sínú ìkòkò náà, tí yóò sì fí wà lórí iná títí yóò fí jiná. Lẹyìn gbogbo eyi ní, a lè bo sí abọ́, tí a sì lè fi iru ohun míìràn tí ó bá wún wà bí dodo, mọ́í-mọ́í, ẹfọ, Sàládìí àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.[15] ní àwọn agbègbè mìíràn, ìbí tí ó jẹ́ agbègbè tí omi ọ sì, èyí tí ó jẹ́ pé eja ló ọ sí, ẹja ní wọn fi máa jẹ jólọ́fu dípo Ẹran tàbí ẹran Adiye gẹ́gẹ́ ohun tí ó wùn.Àdàkọ:Cn

Ìrẹsì Aláṣẹpọ jọ́lọ̀fù ní orílé èdè Gánà

àtúnṣe

Bí wọn tí ń ṣe ìrẹsì Aláṣẹpọ jọ́lọ̀fù ní gánà: òróró, Àlùbósà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ááyù àti ata rodo tí wọn lọ̀pọ̀, tòmáatì lílọ̀, ẹran màálù tàbí ẹran Adìye, nígbà mìíràn won máa ní fí ẹfọ oríṣi sí, ìrẹsì tí ilé yìí tàbí tí òkè òkun pàápàá jùlọ Jasmine Rice àti ata dúdú. Bí wọn ti n ṣe ni; ní àkókò wọn máa bọ ẹran pẹlu èròjà bíi, magí, iyọ Àlùbósà, áàyu, lẹyìn náà ni wọn máa rìn ẹran náà, [16] lẹyìn èyí ni gbogbo èròjà yòókù, náà máa wà ní díndín (àwọn ní, Àlùbósà, ata lilọ, tòmáatì lilọ, magí ní tẹ̀lẹ́tẹ̀lẹ́. Nígbà tí àwọn wọnyí bá dín tán, á má da ìrẹsì sí inú ikòkò tí ohun tí a dìn wa, Títí yóò fí jina tí wọn yóò fi bú sí abọ́. Wọn máa ń fí awọn ohun bí ẹran díndín , adìye tàbí tõõkí tàbí ẹja jẹ, awọn mìíràn a má fí ẹfọ diẹ sí orí Ìrẹsì jọ̀lọ́fu ti gánà.[17][18]

Fún ayẹyẹ, wọn máa ń jẹ Gánà Jọlọfu pẹlu Shito, èyí tí jẹ́ kìkì dáa ata rodo tí ó wọ ní orílé èdè Gánà, tàbí Sàládìí ni àwọn ayẹyẹ mìíràn.[19]

Jọlọ́fùú orílé èdè Bissau-Guinea

àtúnṣe

Wọn máa ń fí Arabambi ṣe ìrẹsì àsèpọ̀ yìí ní Bissau Guinea pẹlu awọn ohun bí tòmáatì lilọ, Àlùbósà, tòmáatì lásán, ata rodo lílọ, ata rodo bi tí kò pọn, áàyu, ewe tí wọn pè ní Bay leave. Gbogbo ohun tí a káalè yìí ní wọn máa dín nínú òróró gbóná pẹlu èròjà tí ó má ń jékí oúnjẹ tasánsán. Àwọn ará bissau máa ń ló atalẹ̀ tí a mọ̀ sí garlic láti lè tún bọ jékí òórùn-ùn tún bọ̀ jáde sí. Ní ìgbẹ̀yìn, wọn má ń jẹ́ ìrẹsì àsèpọ̀ yìí lasan tàbí pẹ̀lú Ẹran Adiye, ilá tabi dòdò.Àdàkọ:Cn

Ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ ní àgbáyé

àtúnṣe

Láti ọdún 2010 ní ìfẹ fún oríṣìíríṣìí oúnjẹ ti ilé aláwọ̀ dúdú tí ń gboòrò lọ́kàn àwọn èèbó Alawọ funfun. Àwọn èèbó bẹrẹ sí ní ṣe Àjọ̀dún Fún ìrẹsì jólọ́fu tí wọn ṣe ni awọn agbègbè bíi washington DC ní Orílé èdè USA, Toronto ni Kánádà ní wọn tí ń ṣe ọdún Jólọ́fu, èyí tí wọn ṣe kọjá wáyé ni ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n ọdún 2015 tí wọn pè ní World Jollof Day, tí ó sí wùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lórí ẹ̀rọ ayélujára.[3]

Àwọn ìtọ́kasi

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Ayto, John (2012). "Jollof rice". The Diner's Dictionary: Word Origins of Food and Drink (2nd ed.). Oxford University Press. p. 188. ISBN 978-0199640249. https://archive.org/details/dinersdictionary0000ayto. 
  2. 2.0 2.1 2.2 McCann, James C. (2009). A west African culinary grammar". Stirring the Pot: A History of African Cuisine. Ohio University Press. pp. 133–135. ISBN 978-0896802728. https://books.google.com/books?id=CAhgpbXzq0oC&pg=PA133. 
  3. 3.0 3.1 3.2 3.3 Sloley, Patti (7 June 2021). "Jollof Wars: Who does West Africa's iconic rice dish best?". BBC Travel. Retrieved 16 July 2021. 
  4. Dufumier, Marc (March 30, 2018). "Recette : le thiéboudiène de Marc Dufumier". Le Monde. Retrieved 2018-10-27. 
  5. "Know Your History: Jollof Is An Indigenous African Dish And Was Named After The Wolof Tribe Of West Africa". RiddimsGhana. Archived from the original on 2022-01-22. Retrieved 2022-01-22. 
  6. Osseo-Asare, Fran (1 January 2005). Food Culture in Sub-Saharan Africa. Greenwood Publishing Group. pp. 33, 162. ISBN 978-0-313-32488-8. https://books.google.com/books?id=1s-a7EMM6BgC&pg=FA162. 
  7. Davidson, Alan (11 August 2014). "Jollof rice". The Oxford Companion to Food. Oxford University Press. p. 434. ISBN 978-0-19-967733-7. https://books.google.com/books?id=RL6LAwAAQBAJ&pg=FA434. 
  8. Brasseaux, Ryan A.; Brasseaux, Carl A. (1 February 2014). "Jambalaya". In Edge, John T.. The New Encyclopedia of Southern Culture: Volume 7: Foodways. University of North Carolina Press. p. 188. ISBN 978-1-4696-1652-0. https://books.google.com/books?id=s-qnAgAAQBAJ. 
  9. Anderson, E. N. (7 February 2014). Everyone Eats: Understanding Food and Culture, Second Edition. NYU Press. p. 106. ISBN 978-0-8147-8916-2. https://books.google.com/books?id=hBFoAgAAQBAJ&pg=FA106. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  10. "Ghana Jollof Recipe: Steps To Preparing Jollof Rice The Ghanaian Way". BuzzGhana. 2017-09-05. Retrieved 2020-01-16. 
  11. "Classic Nigerian Jollof Rice Recipe on Food52". Food52. Retrieved 2021-02-27. 
  12. "Ghana Jollof Recipe: Steps To Preparing Jollof Rice The Ghanaian Way". BuzzGhana. 2017-09-05. Retrieved 2020-01-16. 
  13. "Know the Differences Between Nigerian and Ghanaian Jollof Rice". Demand Africa. 2018-07-04. Retrieved 2021-07-11. 
  14. Adam, Hakeem (20 January 2017). "A Brief History of Jollof Rice, a West African Favourite". Culture Trip. Retrieved 2020-01-16. 
  15. "How to cook Nigerian Jollof Rice". All Nigerian Recipes. Retrieved 2020-01-16. 
  16. "Ghana: Jollof Rice". The African Food Map. Retrieved 15 November 2016. 
  17. Sekibo, Kojo (2020-01-14). "Traditional Ghanaian Jollof Rice Recipe". Yen.com.gh. Retrieved 2020-01-16. 
  18. "Ghana Jollof Recipe: Steps To Preparing Jollof Rice The Ghanaian Way". BuzzGhana. 2017-09-05. Retrieved 2021-05-18. 
  19. Sekibo, Kojo (2020-01-14). "Traditional Ghanaian Jollof Rice Recipe". Yen.com.gh. Retrieved 2020-01-16. 


Fún Àkàsíwájú si

àtúnṣe

Àdàkọ:African cuisine Àdàkọ:Rice dishes