Joselyn Dumas

Òṣèrébìrin ti ilẹ̀ Ghana

Joselyn Dumas ( /ˌɔːsəlɪn ˈdʊmɑː/; tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 1980) [1] jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ghana tó sì jẹ́ òṣèrẹ́bìnrin àti olóòtú ètò orí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán.[2] Ní ọdún 2014, ó farahàn nínú fíìmù A Northern Affair, èyí tí ó mú gba àmì-ẹ̀yẹ ní Ghana Movie Award àti ní Africa Movie Academy Award fún òṣèrébìnrin tó dára jù lọ.[3]

Joselyn Dumas
Ọjọ́ìbíGhana
Iṣẹ́
  • Actress
  • television host
Ìgbà iṣẹ́2009–present
Websitejoselyndumas.net

Ìbẹ̀rẹ̀pèpẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Dumas sí ìlú Ghana, ó sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ìgbà èwe rẹ̀ ní Accra, Ghana. Ó gbá ẹ̀kọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ní Morning Star School[4] ó sì tẹ̀síwájú láti gba ẹ̀kọ́ girama ní Archbishop Porter Girls High School[5]níbi tih wọ́n ti fi jẹ akẹ́kọ̀ó tó ń darí ètò ìdárayá. Joselyn tẹ̀síwájú nínú ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀, ní United States níbi tí ó ti gboyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ Administrative Law.

Àwọn iṣẹ́ tó yàn láàyò

àtúnṣe

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóòtú ètò ní orí èrọ-amóhùnmáwòrán

àtúnṣe

Joselyn Dumas jẹ́ agbẹjọ́rò kí ó tó kó lọ sí orílẹ̀-èdè Ghana láti ṣe iṣẹ́ tó wùn ún, ìyẹn iṣẹ́ olóòtú lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán. Ó jẹ́ olóòtú fún ètò Charter House's Rhythmz, èyí tó jẹ́ ètò ìdárayá, níbi tí ó ti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilénuwò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbajúmọ̀ ènìyàn.[6] Ilé-iṣẹ́ TV Network, ViaSat 1 pè é láti darí ètò kan fún wọn, tí wọ́n pè ní The One Show,[7] èyí tó wáyé láàárín ọdún 2010 wọ ọdún 2014. Òun ni olóòtú ètò At Home pẹ̀lú Joselyn Dumas èyí tí wọ́n máa ń gbọ́ ní ilẹ̀ Africa àti àwọn agbègbè kọ̀òkan ní Europe.[8]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré

àtúnṣe

Ẹ̀dá-ìtàn tó ṣe nínú fíìmù Perfect Picture, mú kí olùdarí fíìmù náà nífẹ̀é rẹ̀, èyí sì mu kí wọ́n pè é nínú àwọn fíìmù mìíràn láti kópa. Aṣeyọrí ńlá rẹ̀ wáyé lẹ́yìn ọdún méjì tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí nínú fíìmù Shirley Frimpong-Manso tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Adams Apples. Ẹ̀dá-ìtàn "Jennifer Adams" nínú Adams Apples ló mu kí wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèrẹ́bìnrin tó dára jù lọ ní 2011 Ghana Movie Awards.[9] Láti ìgbà tí Joselyn Dumas bẹ̀rẹ̀ isẹ́ eré ṣíṣe ní Ghana náà ni ó ti ń kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré. Ó ti kópa nínú àwọn fíìmù bí i Love or Something Like That, A Sting in a Tale, Perfect Picture, A Northern Affair àti Lekki Wives. Ó ti kópa pẹ̀lú àwọn òṣèrẹ́ bí i John Dumelo, Majid Michel àti OC Ukeje.

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i Olùdarí

àtúnṣe

Ó ṣe olùdarí Miss Malaika Ghana,[10][11] èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdíje láti yan obìnrin tó rẹwà ní Ghana, láti ọdún 2008 wọ ọdún 2010. Òun ni olùdásílẹ̀ Virgo Sun Company Limited, èyí tó máa ń ṣe àgbéjáde fíìmù, tí ó sì ti ṣe àgbéjáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù bí i Love or Something Like that, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀

àtúnṣe
Ọdún Àkọ́lé Ẹdá-ìtàn Ọ̀rọ̀
2009 Perfect Picture Cameo Role
2009 A Sting in a Tale Esi
2011 Adams Apples Jennifer Adams Drama
2011 Bed of Roses Medical Doctor
2012 Peep Detective
2014 A Northern Affair[15] Esaba Romantic film
2014 Lekki Wives (season 2)[15] Aisha
2014 Love or Something Like That Dr. Kwaaley Mettle Drama
2014 V Republic Mansa TV Series
2015 Silver Rain[16][17][18] Adjoa Drama
2015 Cartel the Genesis Agent Naana Action film
2016 Shampaign Naana Akua Quansah TV Series
2017 Potato Potahto[19][20] Lulu Comedy film
2019 Cold feet Omoye Drama
Perfect Picture - Ten Years Later[21][22] Flora Gaisie
2022 Glamour Girls[23] Jemma Drama
2023 Madam Lankai Morgan TV Series

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

àtúnṣe
Ọdún Àmì-̀ẹyẹ Ìsọ̀rí Èsì
2011 Ghana Movie Awards (GMA) Best Actress in a Leading Role Wọ́n pèé
2012 Radio and Television Personality Awards (RTP) Best Entertainment Host of the Year Gbàá
2013 Radio and Television Personality Awards (RTP)
  • Radio/TV Personality of the Year
  • Female Entertainment Host of the Year
  • Female Presenter of the Year
Wọ́n pèé
2013 4syte TV Hottest Ghanaian Celebrity Gbàá
2013 Ghana Movie Awards (GMA) Best Supporting Actress Gbàá
2013 City People Entertainment Awards
  • Stellar Contribution to the Movie & Media Industry in Africa
  • Tremendous Growth in the Movie Industry
Gbàá
2014 Africa Movie Academy Awards (AMAA) Best Actress in a Leading Role Wọ́n pèé
2014 Africa Magic Viewers' Choice Awards (AMVCA) Best Actress in a Leading Role Wọ́n pèé
2014 All Africa Media Networks Outstanding Personality in Creative Entrepreneurship Gbàá
2014 Ghana Movie Awards Best Actress in a Lead Role Gbàá
2015 Africa Magic Viewers' Choice Awards (AMVCA) Best Actress in a Drama Wọ́n pèé
2015 GN Bank Awards Best Actress Gbàá
2015 Blog Ghana Awards Best Instagram Page Gbàá
2016 Golden Movie Awards Best Actress,TV Series Shampaign Gbàá
2016 Ghana Make-Up Awards Most Glamorous Celebrity Gbàá
2016 Shortlisted Among Africa's Top 3 Women in Entertainment Gbàá
2018 IARA UK Best Actress Gbàá

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Joselyn Dumas Biography, Daughter, Relationships, Failures And Other Facts". BuzzGhana. 2017-11-21. Retrieved 2019-04-13. 
  2. "Glitz top 100 inspirational women – Page 100 – Glitz Africa Magazine" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-28. 
  3. Gracia, Zindzy (2018-09-04). "Joselyn Dumas bio: family, career and story". Yen.com.gh. Retrieved 2019-04-13. 
  4. "Morning Star School". Retrieved 2019-04-13. 
  5. "Joselyn Dumas Full Biography [Celebrity Bio]". GhLinks. 2018-07-23. Retrieved 2019-04-13. 
  6. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named BuzzGhana2
  7. "Dumas chosen to host The One Show on VIASAT1". Ghana Celebrities. 16 July 2010. Retrieved 15 July 2014. 
  8. "At Home with Joselyn Dumas Launched! Check out All the Photos". Ghana Celebrities. 27 July 2013. Retrieved 21 August 2014. 
  9. "Ghana Movie Awards 2011 Nomination List". Ghana Celebrities. 27 November 2011. Retrieved 21 August 2014. 
  10. "Joselyn Dumas". ameyawdebrah.com. Retrieved 21 August 2014. 
  11. "Meet Our Presenters". Viasat1. Archived from the original on 26 August 2014. Retrieved 21 August 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  12. "Shirley Frimpong Manso releases Perfect Picture". jamati.com. Archived from the original on 6 August 2010. Retrieved 15 July 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  13. "Adam's Apple Chapter 10 Movie premiere". 8 April 2012. Retrieved 15 July 2014. 
  14. "CinAfrik premieres Bed of Roses on seventh of April". Modern Ghana. 4 April 2012. Retrieved 15 July 2014. 
  15. 15.0 15.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named myjoyonline.com
  16. "Silver Rain the movie". You Tube. Silver Rain movie. Retrieved 24 September 2014. 
  17. "WATCH: TRAILER for Juliet Asante's 'Silver Rain' movie". GhanaWeb. 16 December 2014. Retrieved 16 December 2014. 
  18. "'Silverain' Movie gets Amsterdam premiere date". Pulse Nigeria. Chidumga Izuzu. 2 June 2015. Archived from the original on 17 November 2016. Retrieved 2 June 2015. 
  19. "Shirley's New Movie 'Potato Potahto' Starring Joselyn Dumas, Chris Attoh, Nikki, Adjetey Annan & Others To Premiere In Ghana". E Ghana. Retrieved 2019-06-14. 
  20. Frimpong-Manso, Shirley (2019-12-15), Potato Potahto (Comedy), O. C. Ukeje, Joselyn Dumas, Joke Silva, Kemi Lala Akindoju, retrieved 2021-02-03 
  21. "Sparrow Production shoots 'Perfect Picture' movie again 10 years later". GhanaWeb. 2019-10-09. Retrieved 2021-02-03. 
  22. Frimpong-Manso, Shirley (2020-07-04), The Perfect Picture - Ten Years Later (Comedy, Romance), Jackie Appiah, Naa Ashorkor Mensa-Doku, Lydia Forson, Adjetey Anang, Sparrow Pictures, retrieved 2021-02-03 
  23. Glamour Girls (2022) - IMDb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), retrieved 2022-07-08