Joseph Fọláhàn Ọdúnjọ

Joseph Fọláhàn Ọdúnjọ (1904–1980) jẹ́ ogbóntagì òǹkọwé, olùkọ̣́, àti olóṣèlú tí ó gbajúmọ̀ fún àpilẹ̀kọ lítíréṣọ̀ Yorùbá àwọn ọmọdé.[1][2][3][4][5]

Ìgbésí ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Ọdúnjọ ní ìlú Ìbarà, Abéòkúta ní ọdún 1904.[6] Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti 'St Augustine Primary School', ní Abẹ́òkúta. Lẹ́yìn tí ó sì tún lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ti  'Catholic Higher Elementary Training School' àti ilé ẹ̀kọ́ àgbà ti  'London Institute of Education'.

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àti òǹkọ̀wé

àtúnṣe

Ọdúnjọ tẹ̀ síwájú nínú iṣé ìkọ́ni rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ilé ìwé Catholic Training College, Ìbàdàn láti ọdún 1924 tí tí di ọdún 1927, tí ó sì padà di ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ tó tí jáde tẹ́lẹ̀ rí ìyẹn St Augustine, Abéòkúta. Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, ó dá ẹgbẹ́ ìṣọ̀kan àpapọ̀ àwọn olùkọ́ tí ìjọ Kátólííkì (Catholic) láti lè ma bá àwọn aláṣẹ àti olóòtú àgbà sọ̀rọ̀ fún ìgbáyé gbádùn àwọn olùkọ́ wọn. Bákan náà ni Ọdúnjọ tún ṣe olùkọ́ àti olùkọ́ àgbà fún àwọn ilé-ìwé ìjọ́sìn Kátólííkì oríṣiríṣi káà kiri láti ọdún 1940 tí tí di 1950.[7] Àwọn iṣé àpilẹ̀kọ tó ti tẹ̀ jáde láti ọdún 1958 ní ó jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn iṣẹ́ ìbèrè-pẹ̀pẹ̀ èdè Yorùbá. Ó tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé eré onítàn ọlọ́rọ̀-geere (novels), ìwé eré oníṣe orí-ìtàgé (plays), ìwé ewì (poems) àti àkọsílẹ̀ ní èdè Yorùbá . Àwọn ìwé tí ó kọ tí ó tẹ̀ jáde náà ló jẹ́ àkàsọ̀ fún àwọn òǹkọ̀wé èdè Yorùbá òde òní ní ìwúrí láti gbé àpilẹ̀kọ Yorùbá lárugẹ síwájú si.[8][9] Ní ọdún 1966 sí ọdún 1969, ó jẹ́ òkan pàtàkì nínú ìgbìmọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ akọ́mọ-lédè Yorùbá Orthography.[10] Bákan náà ni ó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ olùkọ́ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (Nigeria Union of Teachers) fún àìmọye ọdún.

Ṣíṣe òṣèlú rẹ̀

àtúnṣe

Ní ọdún 1951, ó di ọmọ ilé aṣòfin ti (Western House of assembly) tí ó sì tún padà di Mínísítà àkọ́kọ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ àti iṣẹ́ ṣíṣe ní ìwọ̀ Òòrùn Nàij̀íríà (region's first minister of Land and Labour).[11] Bákan náà ni ó tún ṣe Ààrẹ fún ọmọ ẹgbé Ẹ̀gbádò (Ẹ̀gbádò Union) tí wọ́n sì tún fi jẹ oyè Aṣíwájú gbogbo Ilẹ̀ Ẹ̀gbá pátá.[12]

Joseph Fọláhàn Ọdúnjọ di olóògbé  ní  1980.

Àwọn iṣé àkànṣe rẹ̀

àtúnṣe

Ìtàn àròkọ ọlọ́rọ̀-geere

àtúnṣe

Ìwé àkàyé

àtúnṣe

Àwọn ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Remembering J. F. Odunjo, the literary icon". Nigerian Guardian. http://article.wn.com/view/2000/04/29/Remembering_J_F_Odunjo_the_literary_icon/. Retrieved June 14, 2016. 
  2. Albert S. Gérard (1972). Black Africa, Volumes 2-3. the University of Virginia: St. John's University Press. p. 195. ISSN 0034-6640. https://books.google.com.ng/books?id=gHgOAAAAYAAJ&q=. Retrieved June 14, 2016. 
  3. Ayọ Bamgbose; Ọlátúndé O. Ọlátúnjí (1986). Yoruba: A Language in Transition. University of Virginia: J.F. Ọdunjọ Memorial Lectures. https://books.google.com.ng/books?id=I-QNAAAAYAAJ&q=. Retrieved June 14, 2016. 
  4. Daily Times of Nigeria Limited (1971). Who's who in Nigeria: a biographical dictionary. Times Press (Magazine Division). https://books.google.com.ng/books?id=m5gUAQAAIAAJ&q=. Retrieved June 14, 2016. 
  5. "Odunjo remembered". Allafrica. Retrieved June 14, 2016. 
  6. Janheinz Jahn; Ulla Schild; Almut Nordmann Seilerr (1972). Who's who in African Literature: Biographies, Works, Commentaries. Horst Erdmann Verlag. p. 286. ISBN 978-3-7711-0153-4. https://books.google.com.ng/books?id=ko0HAQAAIAAJ&q=Joseph+Folahan+Odunjo&dq=Joseph+Folahan+Odunjo&hl=en&sa=X&ved=0ahUKEwi18ZyV9pDNAhWiD8AKHaTuCEUQ6AEIHDAB. Retrieved June 14, 2016. 
  7. Albert S. Gérard (1972). Review of national literatures. St. John's University Press. https://books.google.com.ng/books?id=gHgOAAAAYAAJ&q=Joseph+Folahan+Odunjo&dq=Joseph+Folahan+Odunjo&hl=en&sa=X&ved=0ahUKEwi18ZyV9pDNAhWiD8AKHaTuCEUQ6AEIMTAG. Retrieved June 14, 2016. 
  8. Kayode Sobayo (2007). "Abeokuta: 175 years of unity & excellence : plus who's who". Skys Production. p. 66. ISBN 978-978-2829-07-8. Retrieved June 14, 2016. 
  9. Akínwùmí Íṣọ̀lá (1992). "New Findings in Yoruba Studies (J.F. Ọdunjọ memorial lectures series)". University of Virginia. ISBN 978-978-30181-4-3. Retrieved June 14, 2016. 
  10. Philiip Adédòtun Ògúndèjì. 2016. Odúnjo, Joseph Folàhán. Encyclopedia of the Yoruba, ed. by Tóyìn Fálolá and Akíntúnde Akínyemí, pp. 251,252. Bloomington, IN: Indiana University Press.
  11. Who's who in Nigeria. the University of California: Nigerian Printing and Publishing Company. 1956. p. 212. https://books.google.com.ng/books?id=egUaAAAAIAAJ&q=. Retrieved June 14, 2016. 
  12. Ayọ Bamgbose; Ọlátúndé O. Ọlátúnjí (1986). Yoruba: A Language in Transition. 1. J.F. Ọdunjọ Memorial Lectures (University of Virginia). p. 5. https://books.google.com.ng/books?id=I-QNAAAAYAAJ&q=joseph+folahan+odunjo+asiwaju+of+egbaland&dq=joseph+folahan+odunjo+asiwaju+of+egbaland&hl=en&sa=X&ved=0ahUKEwj0pMPHqaTNAhXII8AKHeqwCncQ6AEIHzAC. Retrieved June 14, 2016. 
  13. "Literatures in African languages : Yoruba". Encyclopædia Britannica for Kids. Archived from the original on September 28, 2016. Retrieved June 14, 2016.