Joseph H. Greenberg
Ohun tí òǹkọ̀wé ṣiṣẹ́ lé lórí nínú ìwé yìí ìpín èdè Aáfíríkà sí ẹbí. Orí méje ni ìwé náà ní. Orí kìíní ni ó sọ̀rọ̀ nípa ìlàlà tí a lè tẹ̀lé láti pín èdè kan sí ẹbí. Lẹ́yìn èyí ni òǹkọ̀wé wá bẹ̀rẹ̀ sí ní í ṣe àlàyé àwọn ẹbí tí ó pín èdè Aáfíríkà sí. Orí keyì sọ̀rọ̀ nípa Niger-Cong; ẹ̀kẹ́ta, Afrocasiatic; ẹ̀kẹ́rin; Khoisan; ẹ̀kárùn-ún, Chari-Nile; ẹ̀kẹ́fà; Nilo-Saharan nígbà tí orí kéje sọ̀rọ̀ nípa Niger-Kordofania. Yàtọ̀ sí orí méje yìí, ìwé náà ní index to language classification, key to language classification àti index of languages. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ máàpù ni òǹkọ̀wé yà sínú ìwé yìí. Ní ìparí, òǹkọ̀wé ṣe àfikún díẹ̀ sí ìwé yìí ó sì ṣe àtúnṣe àwọn àṣìṣe tí ó ṣe àkíyèsí nínú ìwé náà. Bí àwọn ohun tí ó wa nínú ìwé náà ṣe lọ ní olóríjorí nì yí:
Joseph Greenberg | |
---|---|
Ìbí | May 28, 1915 Brooklyn, New York |
Aláìsí | May 7, 2001 Stanford, California |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | American |
Pápá | linguistics, African anthropology |
Ilé-ẹ̀kọ́ | Columbia University Stanford University |
Ó gbajúmọ̀ fún | work in linguistic typology, genetic classification of languages |
Àwọn ẹ̀bùn àyẹ́sí | Haile Selassie I Prize for African Research (1967), Talcott Parsons Prize for Social Science (1997) |
Iwe ti a yewo
àtúnṣe- Joseph H. Greenberg (1966), The Languages of Arica. Bloomingtion; Indian University Press.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |