Joshua Olufemi (tí wọ́n bí ní ọjọ́ 22 oṣù keje, ọdún 1983) jẹ́ oṣìṣẹ́ orí ẹ̀rọ-ayélujára ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti olùdásílẹ̀ ìmọ̀-ẹ̀rọ fún àwọn ará ìlú. Òun ni olùdásílẹ̀ Dataphyte, òun sì ni olùdarí ètò Premiun Times Cntre for Investigative Journalism (èyí tí wọ́n ń pè báyìí ní The Centre for Journalism Innovation and Development - CJID).[1][2] Olufemi ni akọròyìn tó tún jẹ́ aṣojú Premium Times ní International Consortium of Investigative Journalists (ICIJ) fún ilé-iṣẹ́ atẹ̀wéjáde Panama Papers àti Paradise Papers.[3][4][5]

Ètò ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́

àtúnṣe

Olufemi kẹ́kọ̀ọ́ gboyè bachelor's degree nínú ẹ̀kọ́ Economics láti ilé ìwé gíga Olabisi Onabanjo ní ọdún 2005 àti oyè master's degree nínú ẹ̀kọ́ Measurement and Evaluation láti ilé-ìwé gíga University of Lagos ní ọdún 2013, kó tó lọ sí Said Business School ti University of Oxford, níbi tí ó ti gba oyè nínú ẹ̀kọ́ Global Financial Technology. O jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Institute of Chartered Economists of Nigeria.[6]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Spotlight: Joshua Olufemi, Media Management Executive, Nigeria". NATIONAL ENDOWMENT FOR DEMOCRACY (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-12-13. Retrieved 2022-04-14. 
  2. "Premium Times Director selected for prestigious Reagan Fascell fellowship | Premium Times Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-03-06. Retrieved 2022-04-14. 
  3. "The Panama Papers: About this project | ANCIR". panamapapers.investigativecenters.org. Retrieved 2022-04-14. 
  4. Shinovene, Shinovene (2016-04-26). "Dangotes offshore games in Panama Papers". Investigation Unit (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-04-14. 
  5. "#ParadisePapers: Saraki Violates Nigerian Law Again, Linked To Another Firm In Offshore Tax Haven". Sahara Reporters. 2017-11-06. Retrieved 2022-04-14. 
  6. "Joshua Olufemi's schedule for IPI World Congress 2018". ipiwoco2018.sched.com. Retrieved 2022-04-14.