Julius Agwu (bí ni Oṣù kejè, Oṣù Igbe, ọdún 1973)jẹ́ apanilẹ́ẹ̀rín, òṣèré, olórin àti atọ́kùn. Òun ni aláṣẹ àti olùdarí iléeṣẹ́ Reellaif Limited, Music and Movie Production Company. Ó tún jẹ́ olùdámọ̀ràn lórí amúlùúdùn àti sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ajẹmọ́-ìṣípayá. Òun ni olótùú àwọn eré bíi adárìínpani Crack ya Cribs, Laff 4 Christ's Sake àti Festival of Love.[1][2]i.[3]

Julius Agwu at AMVCA 2020

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbé-ayé ati iṣẹ́ àtúnṣe

Ìlú Port-Harcourt ní Ìpínlẹ̀ Rivers ni wọ́n bi sí. Àwọn òbí rẹ̀ ni Olóyè Augustine Amadi Agwu àti Arábìnrin Mary aya Agwu. Òun ni ọmọ karùn-ún nínú àwọn mẹ́fà. Ìlú Port-Harcourt tí ó dàgbà sí ni ó ti bẹ̀rẹ̀ Ó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe lórí ìtàgé. Ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré orí Tẹlifíṣàn àti àwọn eré bíi Torn (2013), A Long Night (2014) àti After Count (2011).[4]

Ẹ̀kọ́ àtúnṣe

Julius Agwu bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ní Iléẹ̀kọ́ Alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ tí Ìpínlẹ̀ (Elementary State School) tí ó di Iléẹ̀kọ́ Alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ UBE ni Choba, Port-Harcourt, Ìpínlẹ̀ Rivers níbi tí ó ti gba Ìwé-ẹri Iléẹ̀kọ́ Alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn ti ó parí ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ ó tẹ̀síwájú sí Iléẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ndírì ti Ìjọba ni Borokiri, Port-Harcourt, Ìpínlẹ̀ Rivers, Nàìjíríà, ó sì padà parí ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndírì rẹ̀ ni Iléẹ̀kọ́ Gírámà Akpor ni Ozoba, Port Harcourt Ìpínlẹ̀ Rivers níbi tí ó ti gba Ìwé-ẹri ìdánwò àsekàgbá tí Ilé ẹ̀kọ́ Gíga (West African Senior School Certificate). Nígbà tí ó wà ní Iléẹ̀kọ́ Gírámà Akpor ní Ozoba, ó jẹ́ oyè amúlùúdùn àti àárẹ ẹgbẹ́ eré - oníṣẹ́, ẹgbẹ́ ìjíròrò àti àṣà. Nígbà tí ó parí ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndírì rẹ̀, ó lọ lọ ẹ̀kọ́ Tíátà ní ipele dípúlómà ní Yunifásítì Port-Harcourt tí ó sì gbajúmọ̀ eré ṣíṣe, ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ eré - dídarí nílé ẹ̀kọ́ kanáà[5]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe