Justine Burns
Justine Burns jẹ́ onímọ̀ ìṣòwò ti orílẹ̀-èdè South African, tó sì tún jẹ́ olùarí School of Economics, ní University of Cape Town (UCT), níbi tí ó ti ń ṣiṣẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n. Ó jẹ́ olùṣèwádìí ní Southern Africa Labour and Development Research Unit (SALDU) àti Research Unit in Behavioural Economics and Neuroeconomics (RUBEN).[1]
Justine Burns | |
---|---|
Alma mater | University of Massachusetts at Amherst (PhD, 2004) |
Iṣẹ́-ìwádìí Burns dá lórí ìmọ̀ ìṣòwò, tó tún ní ṣe pẹ̀lú ìyàsọ́tọ̀, ìfọkàntán, owó ìṣòwò àti ọjà iṣẹ́. Ó sì tún ti ṣe àtẹ̀jáde àwọn ìwé ìwádìí rẹ̀ lórí àwọn ètò tó ń ran àwùjọ lọ́wọ́. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti UCT fún olùkọ́ tó tayọ jù lọ ní ọdún 2006,[2] tí wọ́n sì gbà á sí Academy of Science of South Africa, ní oṣù kẹwàá, ọdún 2021.[3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Justine Burns". SALDRU (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-05-27.
- ↑ "Distinguished Teacher Award". University of Cape Town. https://uct.ac.za/explore-uct-awards-achievements/distinguished-teacher-award.
- ↑ "Top Scholars in South Africa Honoured". ASSAf (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 21 October 2021. Retrieved 2023-05-27.