Juuso Ngaikukwete
Juuso Amuaalua (Hamalwa) Ngaikukwete (tí wọ́n bí ní ọdún c. 1873 ní Oukwanyama, Ovamboland, Namibia — tí ó sì fi ayé sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹfà ọdún 1955[1]) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùsọ́ àgùntàn méje tí Matti Tarkkanen yàn ní Oniipa, Ovamboland, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 1925 lábé ìdarí Bíṣọ́bù Tampere, Jaakko Gummerus.[2][3][4]
A bí Ngaikukwete sínú ìdílé Ngaikukwete yaShimupeni àti Mwalungilange yUugwanga. Friedrich Meisenholl ṣe ìrìbọmi fun ní ọjọ́ kablélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1893 ní Oukwanyama. Ngaikukwete lọ sí ilé ìwé Oniipa nígbà 1918 sí 1920, ó sì kọ́ nípa iṣẹ́ àlùfáà ní Oniipa láàrin ọdún 1922 sí 25. Ó ṣiṣẹ́ ní Oshitayi láàrin ọdún 1925 sí 1934 ati ní Oshigambo láàrin ọdún 1931 sí 1955.[1]
Ngaikukwete fẹ́ Mwaalwa Maria gaShelungu (tí a bí ní ọdún 1899) àwọn méjèèjì sì bí ọmọkùnrin kan àti ọmọbìnrin mẹ́ta.[1]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Nambala, Shekutaamba V. V. (1995). Ondjokonona yaasita naateolohi muELCIN 1925–1992. Oniipa, Namibia: ELCIN. p. 162.
- ↑ Peltola 1958, p. 212.
- ↑ Pentti 1958, p. 113.
- ↑ Vilho Shigwedha & Lovisa Nampala (2006). Aawambo Kingdoms, History and Cultural Change. Perspectives from Northern Namibia.. Switzerland: P. Schlettwein Publishing. p. 80.