KÍ NI ÀWỌN NǸKAN ÌWÚRE?

Ki ni àwọn nǹkan Ìwúre?

Àwọn ohun èlò ti a máa ń lò nígbà ti a bá fe wúre ni ìwọ̀nyí: Ọtí Òyìnbó, epo, iyọ̀, orógbó, ataare, oyin, ṣúgà, irèké, àádún, ẹ̀ja, omi, ilẹ̀, abbl. Ki í se níbi gbogbo iwúre ni gbogbo àwọn ohun èlò tí a dárúkọ sókè wọ̀nyí ní láti péjú. Nígbà ìgbéyàwó tàbí níbi ìsọmọlórúkọ̀, ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ohun èlò wònyí kìí sáábà yẹ̀. Èyí to jẹ́ pé kò-sí-lájo-àjo-ò-kún nínú àwọn ohun èlò wọ̀nyí ni ọtí. Àní wọn a máa dá ọtí nìkan lò, yálà níbi ifi ìpilẹ̀ ilé lélẹ̀, níbi ìṣélé tàbí níbi àjọyọ̀ ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ra okọ̀ tuntun sójú ọ̀nà abbl.

Bí olúware bá ti wúre si ọtí tan, ọtí yií ti di ọtí tí a yà sọ́tọ̀: ó ti di ọtí àdúà. Wọn a bẹ̀rẹ̀ sí í gbé e fun gbogbo èniyàn tó yẹ láti tówò nínú rẹ̀. Ọtí àdúa ni èyi, kì í ṣe ọtí àmuyó. Wọn a máa fi irú ọtí báyií pamọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n bá pẹ́ lẹ́yìn kí wọn tó dé. Wọ́n a máa fi ọtí yií kan náà ránṣẹ́ si àwọn ìbátan tí kò ráye mésèwá síbi àseye. Bi àwọn eniyàn bá ti n tọ́ irú ọtí báyií wò, àdúà yóó máa gorí àdúà ni.

Àròfọ̀ ẹnu àwọn Yorùba tó máa ń jẹyọ nínú Ìwúre

Nínú iwúre, àròfọ̀ ẹnu àwọn Yorùbá tí í sáábà jáde ni ọfọ̀. A ó rí i pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn gbólóhùn tó jẹ́ mó ọfọ̀ sáábà máa ń wáyé, Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ. Ìdí pàtàkì tí a lèrí tọ́ka sí fún èyi ni wí pé àwọn Yorùbá gbàgbọ́ nínú agbára ọ̀rọ̀. Bí wọ́n bá fẹ́ kí ohun kan ṣelè fún idí pàtàkì kan, wọ́n ní láti ṣe é bí wọ́n tí í ṣe é, kí ó baà lè rí bí í ti í rí. Gbogbo àwọn ohun èlò tí wọ́n kó kalẹ̀ láti fi wúre ni wọn yóò sì máa pè lórúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan bí ìgbà tí ẹni tí ń pọfọ̀ ń ka gbogbo àwọn nǹkan tó kó jọ láti fi ṣe ọfọ̀.