KÍ NI ÌWÚRE?

Àwọn Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, 'Yóò ṣẹ̀; kó ṣẹ; àdúrà tu ni lára ju èpè lọ'. Ìjìnlẹ̀ àdúrà ẹnu àwọn Yorùbá ni ìwúre jẹ́. Nílé ni, lóko ni, àti lájò pẹ̀lú, àdúrà kọjá ohun tí à á fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Ènìyàn le lówó, kó kọ́lé, kó là bíi Eléwì-odò, gbígbà àdúrà ni.

Kò sí ibi tí àwọn Yorùbá kò ti le wúré tàbí ṣe àdúrà. Wọ́n le wúre nígbà tí wọ́n wà nínú ilé, lọ́nà oko, nídìí ọjà tí wọ́n ń tà, nírìn-àjò, abbl. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe èyí kò ṣòro láti mọ̀. Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé kò sí ibi tí ojú Olódùmarè kò tó. Wọ́n tún gbàgbọ́ pé kò sí ibi tí Àláwùràbí kò wà nígbàkúùgbà. Elétí gbáròyé ni Olódùmarè pẹ̀lú kì í gbọ́ ti ẹnìkan kó dá ti ẹnìkejì sí. Àdúrà sì jẹ́ ohun-ó-wù-mí-kò-wù-ọ́ tí kò jẹ́ ká pawọ́pọ̀ fẹ́ obìnrin. Fún ìdí èyí olúkúlùkù ni Olódùmarè fún láàyè láti béèrè ohun tí ó bá ń fẹ́ tàbí kí ó tọrọ àdúrà rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ irúmalẹ̀ sí Olódùmarè.

Yàtọ̀ sí gbogbo àwọn àdúrà tí a le nìkan ṣe, àdúrà mìíràn wà tó jẹ́ pé a máa ń péjọ ṣe é ni. A ó pé àwọn ẹbí, ọrẹ́ àti àwọn ojúlùmọ̀ láti wá bá wa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún oore ńlá tó ṣe tàbí fún àṣeyọrí rere kan, kí á má baà di aláramóorejẹ. Irú àkànṣe àdúrà báyìí ni wọ́n ń pè ní ìwúre. Ó le wáyé níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, ìsọmọlórúkọ, ayẹyẹ ìkọ́ṣẹ́ parí, ilé ṣíṣí, abbl.

Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé bí a bá ṣe ni lóore, ọpẹ́ là á fún. Bí Olódùmarè bá sì ṣe oore ńlá kan fún ẹnìkan, kò yẹ kí ó da ọwọ́ boore náà. Ó yẹ kí ó tọrọ àkànṣe àdúrà lórí rẹ̀, kí ó ba le tùbà-tùṣẹ fún un.