Káyọ̀dé Akíntèmi

Káyọ̀dé Akíntèmi tí wọ́n bí ní (June 26, 1965) jẹ́ akọ̀ròyìn , TV presenter, onímọ̀ ní ọ̀rọ̀ tóńlọ (subject matter expert), alámòójútó iṣẹ́ àkànṣe, Olù fúnilámọ̀ràn nípa ICT ( ICT consultant) , ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ Channels TV, gẹ́gẹ́ bí Olóòtú àgbà Àti gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá àgbà fún ẹ̀ka ICT àti alámòójútó iṣẹ́ àkànṣe fún London Borough of Hillingdon.. Ó fi ilé iṣẹ́ amóhùmáwòrán Channels sílẹ̀ ní ọdún 2016 láti lọ dá tirẹ̀ sílẹ̀ tí ó pè ní Plus TV Africa, níbi tí jẹ́ Aláṣẹ àti Olóòtú àgbà fún ìgbé ìròyìn jáde. [1]Káyọ̀dé ló ma ń gbàlejò àwọn ènìyàn lórí ètò tí ó pè ní Sunrise Saturday, tí ó ma ń gbìnàyá ní orí ìkànì Channels TV. Óun tún ninó ma ń ṣètò "Wake Up Africa",èyí tí ó ma ń wáyé ní gbogbo ọjọ́ Ẹtì láàrín agogo mẹ́fà sí ago mẹ́sàán àárọ̀ (6 a.m and 9.am), lórí ìkànì Rédíò 94.3 FM.

Kayode Akintemi
IbùgbéLagos State
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigeria
Iṣẹ́broadcast journalist and television host
Ìgbà iṣẹ́1980 - present
EmployerPlus TV Africa
OrganizationBroadcasting Organization
TelevisionSunrise Saturday

Ètò Ẹ̀kọ́ àti ìgbòkègbodò iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Káyọ̀dé gba ìwé ẹ̀rí Higher National Diploma nínú imọ̀ -ẹ̀ẹ̀kọ́ mass communication àmọ́ tí ó yan broadcast journalism láàyò jùlọ ní ilé-ẹ̀kọ́ Gbogbonìṣe ti Ìpínlẹ̀ Ògùn tínwọ́n ti yí padà sí Moshood Abiola Polytechnic báyí.[2]Lẹ́yìn èyí ni ó gba ìwé-ẹ̀rí postgraduate diploma nínú ìmọ̀ Information technology.Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1980s pẹ̀lú ilé ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ikẹ̀ Nàìjíríà (Radio Nigeria) gẹ́gẹ́ bí Atọ́kùn fún ètòTeen and Twenty Beats. Nígbà tí ó di ọdún 1987, Ó dara pọ̀ mọ́ Ogun State Broadcasting Corporation, níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́ta ṣáájú kí ó tó di òṣìṣẹ́ fún ẹ̀ka-ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Mass Communication ní Fásitì Ahmadu Bello ní ọdún 1991. Ó dara pọ̀ mọ́ Ogun State Television gẹ́gẹ́ bí Olórí fún ẹ̀ka ètò Amóhùmáwòrá ní ọdún 1993, Ó ṣẹ̀dá ẹ̀ka ( Independent production company), tí wọ́n pè ní "The Kay Associate" pẹ̀lú Ọmọba kehinde Adeosun, tí ó jẹ́ Alága tẹ́lẹ̀ fún (Promoserve advertisement). Ní ọdún 1994, Ó gbéra lọ sí ìlú London, níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ BEN Television, tí ó jẹ́ ilé iṣẹ́ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ní oṣù Kẹ́ta ọdún 2011 ó dára pọ̀ mọ́ ikẹ́ iṣẹ́ amóhùnmáwòrán Channels TV gẹ́gẹ́ bí Olótùú Àgbà fún àjọ náà títí di ọdún 2016. Ní ọdún 2013, wọ́n yàn án àmì ẹ̀yẹ Nigerian Broadcasters Merit Awards gẹ́gẹ́ bí "Best Station's Manager of the year", ọ́dún yìí kan náà ni wọ́n fun ilé iṣẹ́ Channels TV ní àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán tí ó dára jùlọ ní ọdun náà.[3] Ní January 2013, Káyọ̀dé bu ẹnu àtẹ́ lu ìròyì ẹlẹ́jẹ̀ kan tí ó ń jà ràìn ràìn wípé àpérò kan tí ilé iṣẹ́ Channels TV gbé kalẹ̀ lórí bí ìgdàgbàsókè ṣe lè débá àwọn Agbófinró Nigerian Police Force ni ìjọba àpapọ̀ Federal Government of Nigeria. Ó sọ àsọ minu ọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ wípé ìfòté lé àpèjọ ìjíròrò náà ni ìjọba ri wípé àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ nípa ètò àbò ti kópa.

Ìjọ́mọ Ẹgbẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Akíntèmi jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tí ọ̀jọ̀gbọ́n, ti Royal Television Society àti ti Ilé- ẹkọ Redio . Ó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti àwùjọ tí ó wà fún ìṣàkóso Àlàyé ọ̀erọ̀ . [4]àti Ilé- iṣẹ́ Àwọn olùdari .

Ẹ tún lè wo

àtúnṣe

Ìtàkùn Ìjásóde

àtúnṣe

MD/CEO Kayode Akintemi | About Plus TV Africa

Àwọn Ìtaọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Kayode Akintemi". UNESCO. 2016-09-01. Retrieved 2019-10-06. 
  2. "Team – Plus TV". Plus TV – Big Stories Live Here!. Retrieved 2019-10-07. 
  3. "Kayode Akintemi biography, net worth, age, family, contact & picture". Nigeria Business Directory - Find Companies, People & Places in Nigeria. 1965-06-26. Retrieved 2019-10-07. 
  4. "Prabook". prabook.com. Retrieved 2019-10-07.