Kòsọ́kọ́
Kòsọ́kọ́ (ó wàjà ní 1872) ó jẹ́ ọmọ ilé oyè Ológun Kétere, ó sì jẹ gẹ́gẹ́ bí i Ọba ìlú Èkó láti 1845 títí di 1851. Ọba Oṣìnlokùn ni bàbá rẹ̀, nígbà tí àwọn bàbá rẹ̀ ń ṣe Ìdéwu Ojúlarí (tí ó jẹ́ bí Ọba Èkó láti 1829 títí di 1834/35), Olúfúnmi, Ọdúnsì, Ládéga, Ògúnbámbí, Akínsànyà, Ogunjobi, Akimosa, Ìbíyẹmí, Adébánjọ, Matimoju, Adéníyì, Ìsíyẹmí, Ìgbàlú, Ọrẹ́sànyà, àti Ìdéwu-Ojúlarí.
Kòsọ́kọ́ | |
---|---|
Ọba ìlú Èkó | |
1845–1851 | |
Akítóyè | |
Akítóyè | |
Father | Osinlokun |
Born | Èkó |
Died | 1872 Èkó |
Burial | Igà Eréko,Èkó |
Ìgòkè
àtúnṣeJíjẹ Kòsọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ìlú Èkó ni 1845 níṣe pẹ̀lú onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ ajẹmọ́ran.[1]
Aáwọ̀ láàrin ìdílé oyè Oṣìnlokùn àti Àdèlé
àtúnṣeNígbà tí Ọba Ológun Kútere wàjà ní (1800 àti 1805), ìṣòro arọ́pò wáyé láàárín ọmọ rẹ̀ àgbà (Oṣìnlokùn) àti àbíkẹ́yìn rẹ̀ (Àdèlé). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọba jíjẹ kò rọ̀gbọ̀ lé ètò ìbí ṣùgbọ́n nípasẹ̀ àwọn afọbajẹ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti bẹ Ifá wò. Oṣìnlokùn àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ dúró gẹ́gẹ́ bí i lòdì sí ìjọba Àdèlé.[2] Èyí fà á kí òpin wá sí ìjọba Àdèlé ní 1819 nípasẹ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Oṣìnlokùn. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí náà ni ó fà á kí Àdèlé sí kúrò ní Èkó lọ sí Badagry tí ó sì jẹ gẹ́gẹ́ bí olórí níbẹ̀.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ aáwọ̀ Kòsọ́kọ́ pẹ̀lú Elétùú Òdìbò
àtúnṣeKòsọ́kọ́ ṣẹ alàgbà tí ń ṣe èkejì Ọba (Elétùú Òdìbò) àti Afọbajẹ nípa pé ó lọ gbé obìnrin tí Olóyè Elétùú Òdìbò fẹ́ níyàwó.[3] Elétùú Òdìbò gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn olóyè Àkárígbèré ni àṣẹ láti máa ṣàkóso àti fi Ọba jẹ ní ìlú Èkó. Ṣùgbọ́n nítorí ìwà ìgbéraga Kòsọ́kọ́ àti ìpinnu rẹ̀ láti gba obìnrin Elétùú Òdìbò mú kí Olóyè afọbajẹ jẹ́ yìí ni sínú. Èyí ni ó bí aáwọ̀ láàárin wọn, tí kò sì fà á kí Kòsọ́kọ́ le jẹ nígbàkigbà tí ó bá jáde fún ipò Ọba tí àyè bá ṣí sílẹ̀. Nítorí náà, ìṣẹ̀lẹ̀ fi àyè sílẹ̀ fún ìdásí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ní 1851.[3]
Oṣìnlokùn papòdà, ìgbà díẹ̀ tí Ìdéwu Ojúlarí jẹ gẹ́gẹ́ bí Ọba, àti aáwọ̀ láàárin Elétùú àti Kòsọ́kọ́
àtúnṣeLẹ́yìn tí Oṣìnlokùn wàjà ní 1819, ọmọ bàbá Kòsọ́kọ́ Ìdéwu Ojúlarí jẹ gẹ́gẹ́ bí Ọba Kòsọ́kọ́ láti 1819 títí di 1834/5. Síbẹ̀, ìjọba rẹ̀ kò gbajúmọ̀ àti pé Ọba Bìní ni ó ń ṣe àkóso tàbí ni ó ń gba àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà náà. Ní ìgbẹ̀yìn Ìdéwu Ojúlarí ṣígbá wò. Yàtọ̀ sí èyí, ìlú Èkó wà lábẹ́ àṣẹ àwọn ará Bìní títí di ìjọba Ọba Kòsọ́kọ́ tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì yọ nípò ní 1851. Lẹ́yìn náà, Ọba Akítóyè tó jẹ́ arọ́pò rẹ̀, Ọba Dòsùnmú, kọ́ ọ̀ láti máa san ìṣákọ́lẹ̀ ọdọọdún fún Ọba Bìní.[4][5]
Nítorí Elétùú Òdìbò kò tẹ́wọ́ gba Kòsọ́kọ́, àwọn afọbajẹ tún pe Àdèlé láti Badagry wá sí Èkó láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí i Ọba fún ìgbà kejì. Ìgbà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i Ọba wá sí òpin lẹ́yìn ikú rẹ̀ ní 1837 àti pé ní ẹ̀ẹ̀kan si Elétùú Òdìbò kò fàyè gba Kòsọ́kọ́ láti jọba nítorí ó fi Olúwọlé tí ń ṣe ọmọ Àdèlé jẹ gẹ́gẹ́ bí Ọba Èkó.
Ìrúsókè ìjà láàárin Kòsọ́kọ́, Elétùú Òdìbò àti àwọn alábáṣe rẹ̀
àtúnṣeKíkankíkan aáwọ̀ láàárin Elétùú Òdìbò àti Kòsọ́kọ́ túbọ̀ ru sókè nípasẹ̀ pé Elétùú Òdìbò nawọ́ ìbínú rẹ̀ sí Opo Olú tí ń ṣe arábìnrin Kòsọ́kọ́ tí ó fi ẹ̀sùn àjẹ́ kàn án.[6] Àwọn aláawo ṣe ìwádìí tí ó fi hàn pé Opo Olu kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n, Ọba Olúwọlé ṣí ìdí obìnrin náà kúrò ní Èkó. Èyí fà á kí Kòsọ́kọ́ àti àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ Ogun Ewé Kókò tí ó kùnà, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí náà ni ó sọ Kòsọ́kọ́ àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di èrò Ẹ̀pẹ́[7]
Elétùú Òdìbò tún ru àwọn ìkórìíra àárín wọn sókè nípa wíwú òkú ìyá Kòsọ́kọ́ tó kù sókè tí ó sì sọ sínú òkun ní Èkó.[6]
Ìpapòdà Ọba Olúwọlé àti Ìgòkè Akítóyè
àtúnṣeỌba Olúwọlé papòdà nígbà tí àra kan sán tí ó fa kí ààfin Ọba gbaná. Èyí fà á kí gbogbo ẹ̀ya ara Olúwọlé fọ́ káàkiri tí ó jẹ́ pé àwọn ilẹ̀kẹ̀ oyè rẹ̀ ni wọ́n fi dá a mọ̀. Àwọn afọbajẹ kò bá ti pé Kòsọ́kọ́ láti wá jọba ṣùgbọ́n ibi tí ó wà wọ́n kò mọ.[8][9] Fún ìdí èyí, Akítóyè, àbúrò bàbá Kòsọ́kọ́, àbúrò sí Oṣìnlokùn àti Àdèlé, ọmọ Ológun Kútere ni ó jẹ gẹ́gẹ́ bí i Ọba Èkó.
Àìmọ̀ Akítóyè àti ẹ̀san Kòsọ́kọ́
àtúnṣeLáti le da ohun gbogbo sípò (bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé àwọn olóyè lòdì sí èyí, pàápàá Elétùú Òdìbò) pẹ̀lú ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Ọba Akítóyè láìmọ̀ pe Kòsọ́kọ́ padà sí Èkó. Kòsọ́kọ́ padà sí Èkó, ó gba ọkọ̀ ojú-omi olówò ẹrú tó gbajú-gbajà Jose Domingo Martinez lọ. Akítóyè gbìyànjú láti rẹ Kòsọ́kọ́ lọ́kàn pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn kí ó sì tún bùn ún ní oyè Ọlọ́jà Eréko. Kòsọ́kọ́ yára gba ipò yìí ó sì rí àtìlẹ́yìn láàárin ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olóyè olóogun àti láàárin àwùjọ àwọn Mùsùlùmí. Ìrònú dé bá Elétùú Òdìbò nípa agbára tó ti rí gbà yìí ó sì mú orí lé Badagry. Èyí mú kí Akítóyè ránṣẹ́ sí Elétùú Òdìbò láti padà wálé láti Badagry. Ṣùgbọ́n, èyí mú kí Kòsọ́kọ́ fi ohùn lélẹ̀ pé bí Elétùú Òdìbò bá fi le padà sí Èkó, òun yóò sọ ara rẹ̀ di Ọba.
Ogun bẹ́ sílẹ̀ láàárin Ọba Akítóyè àti Kòsọ́kọ́ tí ó rán Akéde rẹ̀ káàkiri ìlú Èkó láti máa kọrin pé "Ẹ sọ fún ọmọ kékeré náà kí ó ṣọ́ra; nítorí tí kò bá ṣọ́ra ìyà rẹ̀ yóò jẹ̀ ẹ́". Akítóyè náà rán Akéde rẹ̀ láti kọrin pé "Abẹ́rẹ́ tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ni mí, tí ó ṣòro láti fà yọ", Kòsọ́kọ́ náà dáhùn pé "Agbẹ́lẹ̀ ni mí tí ó ń fà abẹ́rẹ́ jáde".[10]
Ìkẹ́ẹ̀mísókè yìí ni ó bí Ogun Olómiyọ̀ láti apá ìpín Kòsọ́kọ́ ní oṣù kèje 1845. Kòsọ́kọ́ àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ gbógun ti ààfin Ọba fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Akítóyè gba ìṣẹ́gun Kòsọ́kọ́, ó sì gba òkun sá lọ sí àríwá, ó rí orí omi Agboyi gbà nípasẹ̀ olórí ogun Kòsọ́kọ́ Oṣòdì Tápà, tí ó ṣàlàyé fún Kòsọ́kọ́ pé Èdì ni Akítóyè di àwọn ọ̀tá rẹ tí ó fi rí ọ̀nà lọ. Lẹ́yìn èyí Akítóyè forí lé Abẹ́òkúta níbi tí ó ti rí ààbò. [11] Kòsọ́kọ́ rí ṣíṣá pamọ́ Akítóyè yìí gẹ́gẹ́ bí i ewu. Èyí mú u bí àwọn Ẹ̀gbá fún orí rẹ̀ tí wọ́n sì kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe bí ó ti bèrè. Ní oṣù kẹrin 1841, àwọn ará Ègbá fi àwọn ẹ̀sọ́ sin Akítóyè lọ sí Badagry, ìlú tí àwọn ará Èkó tó ń wá ààbò máa ń sábà lọ. Ibẹ̀ ni ó ti rí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní bá àwọn ajíyìnrere Europe àti àwọn Gẹ̀ẹ́sì ṣe nípasẹ̀ Consul John Beecroft.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Kòsọ́kọ́ rí Elétùú Òdìbò gbá mú, ó sì gbẹ̀san egungun ìyá rẹ̀ tó túká sínú òkun nípa pé ó fi Elétùú Òdìbò sínú garawa epo, ó tì í pa, ó sì sọ́ sínú òkun ní ìlú Èkó.[12][10][13]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Jimoh, Oluwasegun Mufutau (2019-07-12), Goerg, Odile; Martineau, Jean-Luc; Nativel, Didier, eds., "Independence in Epe (Nigeria): political divisions leading to a dual celebration", Les indépendances en Afrique : L'évènement et ses mémoires, 1957/1960-2010, Histoire, Rennes: Presses universitaires de Rennes, pp. 273–292, ISBN 978-2-7535-6947-8, retrieved 2022-01-28
- ↑ Smith, Robert. The Lagos Consulate, 1851–1861. University of California Press, 1979. pp. 14–17. ISBN 9780520037465.
- ↑ 3.0 3.1 Mann, Kristin. Slavery and the Birth of an African City: Lagos, 1760—1900. Indiana University Press, 2007. pp. 47–49. ISBN 9780253117083.
- ↑ Smith, Robert. The Lagos Consulate, 1851–1861. Macmillan. pp. 90. ISBN 0333240545.
- ↑ Ryder, Alan Frederick Charles. Benin and the Europeans: 1485–1897. Humanities Press, 1969 – Benin. pp. 241–242.
- ↑ 6.0 6.1 Mann, Kristin. Slavery and the Birth of an African City: Lagos, 1760—1900. Indiana University Press, 2007. pp. 47–49. ISBN 9780253117083.
- ↑ Smith, Robert. The Lagos Consulate, 1851–1861. University of California Press, 1979. pp. 14–17. ISBN 9780520037465.
- ↑ Smith, Robert. The Lagos Consulate, 1851–1861. University of California Press, 1979. pp. 14–17. ISBN 9780520037465.
- ↑ Mann, Kristin. Slavery and the Birth of an African City: Lagos, 1760—1900. Indiana University Press, 2007. pp. 47–49. ISBN 9780253117083.
- ↑ 10.0 10.1 Mann, Kristin. Slavery and the Birth of an African City: Lagos, 1760—1900. Indiana University Press, 2007. pp. 47–49. ISBN 9780253117083.
- ↑ Smith, Robert. The Lagos Consulate, 1851–1861. University of California Press, 1979. pp. 14–17. ISBN 9780520037465.
- ↑ Cole, Patrick. Modern and Traditional Elites in the Politics of Lagos. Cambridge University Press, 1975. p. 195 n39. ISBN 9780521204392. https://archive.org/details/moderntraditiona0000cole/page/195.
- ↑ Herskovits Kopytoff, Jean. A Preface to Modern Nigeria: The "Sierra Leoneans" in Yoruba, 1830 – 1890. University of Wisconsin Press. pp. 64–66.