Kabir Ahmad Azare
Sheikh Kabir Ahmad Azare (tí wọ́n bí ní 11 February 1960, tí ó sì kú ní 27 April 2023)[1] jẹ́ onímọ̀ Islam, oníwàásù, àti adarí Council of Ulama' ti JIBWIS, ti ẹ̀ka Katagum. Ó jẹ́ ọmọ lẹ́yìn ẹgbẹ́ ìrònú Sunni, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ Jama'atu Izalatil Bid'ah Wa'Ikamatis Sunnah (JIBWIS). Ó gbajúmọ̀ fún ìmọ̀ rẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ Kùránì, Hadith, Fiqh àti èdè Lárúbáwá, bẹ́ẹ̀ sì ni àọn ènìyàn fẹ́ràn àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti bí ó ṣe máa ń sọ̀rọ̀.[2]
Ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Sheikh Kabir Ahmad Azare ní 11 February 1960 ní ìlú Azare town ní agbègbè ìjọ́ba ìbílẹ̀ Katagum, nih Ìpínlẹ̀ Bauchi, ní Nàìjíríà.[3] Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Islam rẹ̀ láti ìgbà èwe rẹ̀, lábẹ́ ìṣàkóso bàbá rẹ̀, àti àwọn onímọ̀ Islam mìíràn. Ó ṣe àkàsórí Kùránì pẹ̀lú Malam Baban Ma'ruf, ẹni tó jé gbajúgbajà òǹka Kùránì àti olùkọ́.[3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Hausa, Katagum Dailypost (2023-04-27). "INNALILLAHI: Sheikh Kabiru Ahmad Azare Ya Rasu" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-08.
- ↑ "Sheikh Kabir Ahmad Azare". www.darulfikr.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-08.
- ↑ 3.0 3.1 Ta'aziyyar Rasuwar Sheikh Kabir Ahmad Azare Tare da Sheikh Shamsu Shitu Azare (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), 3 May 2023, retrieved 2024-02-08