Kafui Danku
Kafui Danku jẹ́ òṣèrébìnrin àti aṣàgbéjáde eré, tó gbajúmọ̀ fún ìkópa rẹ̀ nínú àwọn fíìmù bíi Any Other Monday, Alvina: Thunder and Lightning, I Do, and 4Play.[1][2][3][4] Ó sì tún jé òǹkọ̀wé ìwé Silence Is Not Golden.[5]
Kafui Danku | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 16 Oṣù Kẹjọ 1983 |
Orílẹ̀-èdè | Ghanaian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Ghanaian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Cape Coast |
Iṣẹ́ | Ghanaian Actress and movie producer |
Gbajúmọ̀ fún | Alvina: Thunder and Lightning I Do 4Play. |
Àwọn ọmọ | 2 |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Kafui ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹjọ, ọdún 1982.[6] Ó dàgbà sí Ho, ìlú rẹ̀ sì ni Tanyigbe-Etoe, èyí tó jẹ́ ìlú kan ní agbègbè Volta ní Ghana. Ó gba ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀ ní Mawuli Primary àti JSS.[7] Ó tún lọ sí Ola Girls School ní agbègbè Volta ní Ghana, tí ó sì tẹ̀síwájú nínú ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní University of Cape Coast, ní ààrin gbùngùn Ghana[8], níbi tí ó ti gboyè ẹ̀kọ́ nínú ẹ̀kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì.[9]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeKafui bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe ní United Nations ṣáájú ìgbà tó wọ Ghana Movie Industry ní ọdún 2009.[10] Ó jẹ́ òṣèrébìnrin bẹ́è sì ni ó tún jẹ́ òǹkọ̀wé.[11] Yàtọ̀ sí èyí, ó jẹ́ alágbàwí, Vlogger àti akópa nínú ìdíje arẹwàobìnrin. Ó kópa nínú ìdíje arẹwà obìnrin, ó sì gbéga orókè gẹ́gẹ́ bíi Miss Ghana ní ọdún 2004. Òun ni olùdásílè ABC Limited (ABC Pictures GH), èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tó ń ṣe àgbéjáde fíìmù ní Ghana.[12] Fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀ ní Ghana ni Agony of the Christ, èyí tí àwọn òṣèré bí i Majid Michel àti Nadia Buari kópa nínú.[13]
Ìgbésí ayé ara ẹni
àtúnṣeÓ fẹ́ arákùnrin kan tó wá láti canada [14][15] tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kojo Pitcher.[11] Àwọn méjèèjì fẹ́ ara wọn ní ọdún 2011. Wọ́n bí ọmọ méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́; Lorde Ivan Pitcher àti Titan Pitcher.[16] [11] Kafui ní àbúrò méjì. Àwọn òbí rẹ̀ ni Madam Agnes Asigbey (tó jẹ́ nọ́ọ̀sì tó ti fẹ̀yìntì) àti Olóògbé John Danku.[17]
Inú rere rẹ̀
àtúnṣeNí oṣù karùn-ún ọdún 2018, ó ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò kan, èyí tí ó pè ní 'Ghana Power Kids Charity Ball' láti fi máa ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ọmọdé ní ẹ̀ka Kwashiorkor ti Princess Marie Louise Children's Hospital ní Accra.[18]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Actress Kafui Danku has given birth". www.ghanaweb.com. Retrieved 13 June 2018.
- ↑ "Trailer: Kafui Danku to premiere 'Any Other Monday' on March 4". www.ghanaweb.com. Retrieved 13 June 2018.
- ↑ Mawuli, David. "Kafui Danku: Actress And Producer Says, Romantic Roles In Movies Do Not Affect Her Marriage Life". Archived from the original on 10 July 2018. Retrieved 13 June 2018.
- ↑ "Kafui Danku". IMDb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-12-14.
- ↑ "Kafui Danku launches 'Silence Is Not Golden' book; urges women to speak out". www.ghanaweb.com. Retrieved 13 June 2018.
- ↑ Plug, Ak (2020-11-24). "Kafui Danku Biography, Movies and Net Worth in 2023 - Afrokonnect" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-11-13.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Mawuli, David. "Kafui Danku: Actress And Producer Says, Romantic Roles In Movies Do Not Affect Her Marriage Life". Archived from the original on 10 July 2018. Retrieved 13 June 2018.
- ↑ Plug, Ak (2020-11-24). "Kafui Danku Biography, Movies and Net Worth in 2023 - Afrokonnect" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-11-13.
- ↑ bigedemtimes (2022-10-28). "Kafui Danku biography". Times In Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-09-06.
- ↑ 11.0 11.1 11.2 "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2023-08-23. Retrieved 2024-08-22.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Buckman-Owoo, Jayne (9 October 2021). "Social media for good: The Kafui Danku way". Graphic Online. Retrieved 13 November 2023.
- ↑ Arthur, Portia. "Just A Number !!! Marriages with old men are the best - Kafui Danku". Archived from the original on 10 July 2018. Retrieved 13 June 2018.
- ↑ "GOSSIP: Actress Kafui Danku & White Husband Are Splitting? - We've Just Spoken to Her About This... - Ghanacelebrities.com". 26 June 2016. Retrieved 13 June 2018.
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Buckman-Owoo, Jayne (9 October 2021). "Social media for good: The Kafui Danku way". Graphic Online. Retrieved 13 November 2023.
- ↑ "Kafui Danku to support Kwashiokor Unit of Princess Marie Louise Hospital". GhanaWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-05-10. Retrieved 2023-11-14.