Kalakuta Republic
Kalakuta Republic ni oruko ti olorin ati ajafun ìṣèlú tiwantiwa, Fẹlá Kútì fun ilé ti ọ̀hún, ibẹ̀ ni àwon ebí àti àwon ọmọ egbé olórin rè wa, ibè náà ni ilé orin rè wà pẹ̀lú. Ilé náà wà ní ojúlé kẹrìnlá, opopona Agege, Idi-Oro, ni Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Muṣin, ní orilẹ̀-èdè Naijiria. kalakuta ní ilé-ìwòsàn ọfẹ Fẹla sọ pe ilé náà ko sí lábé ìjoba Ologun junta leyin ti o pada lati Amẹrika ni ọdun 1970. Ogba naa jona ni 18 February 1977 ìgbà tí awon ọmọ ologun bi egbèrún se ìkolù si.[1]
Fela so ilé náà ni "kalakuta" láti se yeye ogbà ewon "Calcutta tí o ti sùn rí. Kí o dipé wón wo ilé náà, Fela ko orin kan nípa ìjoba ologun, o pe oruko orin náà ní "Zombie". Nínú orin náà, o se yèyé àwon ologun pé won Ma un tèlé ìjoba ologun láì ronú. [2]
Orin náà gbajúmọ̀ gan ní Nàìjíríà, ó sì bí Olórí ologun ní Nàìjíríà, Ọ̀gágun Olusegun Obasanjo nínú.
nígbà náà. Inu awọn ọmọ ogun ko dun si bi Fẹlse un n ṣe ariwissiwon n nigba gbogbo, wọn si sọ pe ko bojumu lati ni ijọbolominira tirare ninú orílè-èdè a olominian. Awọiroyin kan ní d Naijiriba ún bèrè si ún gbé itan jan tí wón òle jeri sí pé wón ma un tan àwon n ọbirin lo ogba Fela ti àwon omo egbé Fela kuti si ún mú won se ìkan tí ko da.
Nígbà tí awọn ọmọ ogun Naijiria se ìkolù sí Kalakuta Republic, wón ju iya Fẹla Frances Abigail Olufunmilayo Thomas jáde láti pètésì kejì lati oju ferese sílè.Ìyá rè ku lẹhin ti o wa ni kíkú-yíyè fun bii ọsẹ mẹjọ.[3]
Àwon ìtókasí
àtúnṣe- ↑ "Home". Kalakuta Museums. 2020-11-09. Retrieved 2022-09-11.
- ↑ Fela: The Life and Times of an African Musical Icon. p. 143.
- ↑ "Fela Kuti: Chronicle of A Life Foretold". The Wire (169). September 2011. http://www.thewire.co.uk/in-writing/essays/fela-kuti_chronicle-ofa-life-foretold. Retrieved 2015-06-13.