Kẹ́hìndé Fádípẹ̀ (tí a bí ní 17 Oṣù kẹfà, Ọdún 1983) jẹ́ òṣèrèbínrin ní Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì tí a bí sí ọwọ́ àwọn òbí tí n ṣe ará orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Kehinde Fadipe
Ọjọ́ìbíLondon, England
Orílẹ̀-èdèBritish
Net worthN/A
Olólùfẹ́Wole Olufunwa

Ìsẹ̀mí rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Kẹ́hìndé Fádípẹ̀ ní Ilé-ìwòsàn St Mary tí ó wà ní ìlú Lọ́ndọ̀nù ní ọdún 1983. Ó kọ́kọ́ gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sí ṣááju kí ó tó gba oyè gíga láti Royal Academy of Dramatic Art ní ọdún 2009.[1]

Àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ tí ó ṣe gbòógì wáyé ní ọdún 2009 nígbà tí ó fi kópa nínu eré kan tí a pe àkọ́lé rẹ̀ ní Ruined, [2] èyítí ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti Pulitzer. Ní ọdún 2011 ó kópa nínu eré. tẹlifíṣọ̀nù kan tí BBC gbé kalẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Body Farm, èyí tí ó dá lóri ìwé kan tí Patricia Cornwell kọ ní ọdún 1994. Ó darapọ̀ mọ́ àwọn olùkópa lóri abala ẹ̀kẹẹ̀ta eré Misfits níbití ó ti kópa gẹ́gẹ́ bi Melissa.

Ní ọdún 2013, ó ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú Wole Olufunwa, èyí tí wọ́n ṣe fídíò rẹ̀ tí ìkànnì Channels TV Metrofile gbé sáfẹ́fẹ́.[3] Ó ti ní àwọn ọmọ méjì

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe