Kelechi Amadi Obi
Kelechi Amadi-Obi (tí a bí ní Oṣù kejìlá ọjọ́ kọkọ̀ndínlọ́gbọ̀n, ọdún 1969) jẹ́ olùyàwòrán, olórin àti olùtẹ̀wé Ìwé ìròyìn Mania, ọmọ orílẹ̀-èdè Naìjíríà. [1] [2] [3] Iṣẹ́ rẹ̀ nínu fọ́tòyíyà àti iṣẹ́-ọnà àwòrán ti jẹ́ kí ó di olókìkí lágbàáyé [4] tí ó ṣe ìfihàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfihàn àgbáyé [5] pẹ̀lú Snap Judgement: Ipò Tuntun ní fọ́tòyíyà Áfíríkà òde òní, Ilé-iṣẹ́ àgbáyé ti fọ́tòyíyà New York (2006) A ti ṣe àpèjúwè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn olùyàwòrán olókìkí ní Naìjíríà [6] "tí ó ti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti fi fọ́tòyíyà Naìjíríà sórí máàpù àgbáyé". Vogue pè é ní "agbára pàtàkì kan ni gbàgéde àtinúdá ni Naìjíríà."
Ìgbésíayé ìbẹ̀rẹ̀ àti Ẹ̀kọ́
àtúnṣeA bí I ní Owerri, ní ìpínlẹ̀ Imo sínú ẹbí Adájọ́ Sylvester Amadi-Obi, adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga, àti Ìyáàfin Theresa Amadi-Obi, onímọ̀ ẹ̀kọ́, Amadi-Obi jẹ́ ọmọ karùn-ún nínú àwọn ọmọ méje. Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Library Avenue, Umuahia, Ipinle Abia, ó sì lọ sí Government College Umuahia fún ètò ẹ̀kọ́ girama. Ẹ̀kọ́ yunifásitì rẹ̀ ló ṣe ní́ University Nigeria Nsukka, níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa òfin.
Ó gba ìwé ẹ̀rí ìmọ̀ òfin ní ọdún 1992 àti ìpè sí ilé-ìgbìmọ̀ Naìjíríà ní ọdún 1994. Lákòókò tí ó wà ní ilé-ìwé, ó dá ilé-iṣẹ́ kékeré kan tí ó pè ní De-Zulu. Lẹ́hìn náà, ó pọ̀ díẹ̀ si ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ ọnà ayàwòrán àti níkẹhìn, lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́, di àjùmọ̀dá ẹgbẹ́ fọ́tòyíyà collective Depth of Field, èyí tí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ TY Bello tí yóò tún tẹ̀síwájú láti jẹ́ aláseyorí nínú iṣẹ́ fọ́tò àti orin.
Amadi-Obi, nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Onebello, ìwé ìròyìn nípa ẹwà, nígbà tí wọ́n bèrè ìdí tí ó fi kọ òfin sílẹ̀ fún fọ́tòyíyà, sọ wí pé yíyàn kìí ṣe láàárin fọ́tòyíyà àti òfin, ṣùgbọ́n láàárin fọ́tòyíyà àti àwòrán. Ó sọ pé ó ti jẹ́ òṣèré láti ìgbà èwe rẹ̀ wá. A ti ṣe àfihàn iṣẹ́ ẹ rẹ̀ ní Lagos Photo Festival, [7] Didi Museum, Rele Art Gallery, àti àwọn ibòmíràn.
Depth of Field
àtúnṣeNí ọdún 2001, Amadi-Obi ṣe alájọdásílẹ̀ Depth of Field (DOF), àkójọpọ̀ àwọn olùyaworan, olorin ati awọn oluyaworan Naijiria. O jẹ ipilẹṣẹ ti gbajumo oluyaworan Naijiria Uche James Iroha, ace photographer TY Bello, Amaize Ojeikere, Emeka Okereke, Kelechi Amad-Obi ati Zainab Balogun, eyi ti o waye lẹhin ti awọn olorin mẹfa naa pade ni Bamako, Mali, lakoko ifihan aworan ti a npè ni Memories. Intimes D'un Nouveau Milleanaire Ives Recontres de la Photo (Bamako, 2001). A ṣe agbekalẹ ẹgbẹ naa pẹlu ibi-afẹde lati ni ilọsiwaju didara fọto nipasẹ apejọ nigbagbogbo lati gba ara wọn niyanju ati ṣe alariwisi iṣẹ ara wọn. [8]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Kelechi Amadi-Obi's stunning portraits capture Lagos fashion and design week" (in en-US). Archived from the original on 2018-02-18. https://web.archive.org/web/20180218024057/http://www.konbini.com/ng/lifestyle/kelechi-amadi-obis-stunning-portraits-capture-lagos-fashion-and-design-week/.
- ↑ "Kelechi Amadi Obi: Veteran photographer shares how to attract well-paying clients [WATCH"] (in en-US). Archived from the original on 2018-02-17. https://web.archive.org/web/20180217143455/http://www.pulse.ng/lifestyle/food-travel-arts-culture/kelechi-amadi-obi-veteran-photographer-shares-how-to-attract-well-paying-clients-watch-id5365085.html.
- ↑ "Inside the changing world of Nigeria's photographers (2) – The Nation Nigeria" (in en-US). http://thenationonlineng.net/inside-the-changing-world-of-nigerias-photographers-2/.
- ↑ "Kelechi Amadi-Obi: Speaking Artistically" (in en-US). Archived from the original on 2018-05-13. https://web.archive.org/web/20180513131757/https://guardian.ng/life/on-the-cover/kelechi-amadi-obi-speaking-artistically/.
- ↑ "LFDW Moments: Kelechi Amadi-Obi makes magic with these celebrities at the Heineken Marquee" (in en-GB). Archived from the original on 2018-03-04. https://web.archive.org/web/20180304000942/http://lifestyle.ynaija.com/lfdw-moments-kelechi-amadi-obi-makes-magic-celebrities-heineken-marquee/.
- ↑ "5 Groundbreaking Nigerian Celebrity Photographers" (in en-US). http://stargist.com/entertainment/lists/5-groundbreaking-nigerian-celebrity-photographers/.
- ↑ Adiele, Chinedu. "Lagos Photo Festival: 1st Mobile phone photography exhibition with Huawei P8 Smartphone" (in en-US). Archived from the original on 2018-02-17. https://web.archive.org/web/20180217214202/http://www.pulse.ng/lifestyle/events/lagos-photo-festival-1st-mobile-phone-photography-exhibition-with-huawei-p8-smartphone-id4293715.html.
- ↑ "Photographer Zaynab Odunsi on Deconstructing Stereotypes of African Masculinity" (in en-US). WanaWana. May 25, 2016. http://wanawana.net/2016/05/25/photographer-zaynab-odunsi-on-deconstructing-stereotypes-of-african-masculinity/.