Kenkey
Kenkey (tí a tún mọ̀ sí kɔmi, otim, kooboo tàbí dorkunu) jẹ́ oúnjẹ òkèlè tí ó fara jọ búrẹ́dì láti agbègbè Ga and Faninhab ti Ìwọ-Oòrùn Áfíríkà , tí wọ́n sábàá máa ń jẹ pẹ̀lú ọbẹ̀ crudaiola àti ẹja gbígbẹ, ọbẹ̀ tàbí ata.
Kenkey and ground pepper with sardine | |
Alternative names | kɔmi pronounced (kormi), |
---|---|
Type | Swallow, dumpling |
Place of origin | Ghana |
Main ingredients | Ground corn |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
Ìsápèjúwe
àtúnṣeKenkey máa ń di ṣíṣe pẹ̀lú àgbàdo nípa rírẹ àgbàdo sínú omi fún bíi ọ̀sẹ̀ kan, kí ó tó di pé wọ́n di lílọ̀ tí wọ́n sì di rírẹ pẹ̀lú omi sí dóòfù.[1] Wọ́n máa ń fi dóòfù yìí lára balẹ̀ láti fa omi mu fún ọjọ́ mẹ́rin sí ọ̀sẹ̀ kan síwájú kí dóòfù náà tó di ṣíṣè.
Ìyàtọ̀
àtúnṣeÀwọn agbègbè níbi tí wọ́n ti ń jẹ Kenkey ni Ghana, eastern Côte d'Ivoire, Togo, western Benin, Guyana, àti Jamaica. Ó sábàá máa ń di ṣíṣe láti ara àgbàdo, gẹ́gẹ́ bí sadza àti ugali. Ó jẹ́ mímọ̀ káàkiri gẹ́gẹ́ bí kɔmi (pípè ní kormi) láti ọwọ́ àwọn Gas tàbí dokono láti ọwọ́ àwọn Akans ní Ghana. Ó tún jẹ́ mímọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí dokunoo, dokono, dokunu, blue drawers, àti tie-a-leaf. Ní Guyana, wọ́n ń pè é ní konkee.[2] Ní Trinidad wọ́n ń pè é ní "paime" (pípè ní pay-me) tí ó sì yàtọ̀ ní pé kò ní ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà ṣùgbọ́n tí ó lè ní àgbọn, pumpkin àti/tàbí raisin. Àsìkò ọdún Kérésìmesì ni wọ́n sábàá máa ń jẹ oúnjẹ náà.[3] Nínú oúnjẹ Caribbean, ó máa ń di ṣíṣe pẹ̀lú ọkà bàbà, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà, ọ̀gẹ̀dẹ̀ aláwọ̀ ewé, ànàmọ́ (ẹ̀yà ti Asante àti Jamaican ,èyí tí ó wá láti ẹ̀yà ti Asante) tàbí ẹ̀gẹ́ , tí a fi ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ wé. Oúnjẹ náà di rírí láti ara ìṣe ìdáná ilẹ̀ Áfíríkà.
Yíyátọ̀ sí ugali, ṣíṣe kenkey níse pẹ̀lú jíjẹ kí àgbàdo náà fún omi gbẹ síwájú ṣíṣè. Fún ìdí èyí, ìgbáradì máa ń gba ọjọ́ díẹ̀ láti lè jẹ́ kí dóòfù náà wú. Àgbàdo máa ń di pípò pọ̀ pẹ̀lú sítáàsì, omi sì máa ń di fífi sí i títí ó máa fi dán tí dóòfù ó sì fi di ṣíṣe. Ó máa ń di bí ò, yóò sì di fífi sílẹ̀ ní ààyè tí ó lọ́wọ́rọ́ fún wíwú náà láti wáyé. Lẹ́yìn wíwú, Kenkey náà máa ń di ṣíṣè díẹ̀, wọn á sì fi ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ bò ó, aṣọ àgbàdo tàbí irin tẹ́ẹ́rẹ́, yóò sì di ṣíṣe. Orísìírísìí ẹ̀yà Kenkey ló wà, gẹ́gẹ́ bí Kenkey ti Ga àti Fante.[6] Kenkey ti Ga wọ́pọ̀ dáadáa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè Ghana.
Kenkey ti Ice jẹ́ oúnjẹ tí a ṣe láti ara Kenkey tí a pò pọ̀ pẹ̀lú omi, súgà, mílíìkì, àti yìnyín.
Àwọn àwòrán
àtúnṣe-
Ghana kenkey
-
Ga kenkey pẹ̀lú edé
-
Ga kenkey pẹ̀lú ata àti ẹ̀wà
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Atter, Amy; Ofori, Hayford; Anyebuno, George Anabila; Amoo-Gyasi, Michael; Amoa-Awua, Wisdom Kofi (2015). "Safety of a street vended traditional maize beverage, ice-kenkey, in Ghana". Food Control 55: 200–205. doi:10.1016/j.foodcont.2015.02.043.
- ↑ "Ghana: Kenkey". 196 flavors (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-06-21. Retrieved 2020-06-04.
- ↑ "Trinidad Paime: A Favourite Christmas Treat". SimplyTriniCooking.com. Retrieved 2024-05-19.
- ↑ Jamaican Cooking: 140 Roadside and Homestyle Recipes. Macmillan USA. 1997. ISBN 9780028610016. https://books.google.com/books?id=BIBjAAAAMAAJ&q=Dokunoo.
- ↑ "Regional Dishes". touringghana. Archived from the original on 10 August 2013. Retrieved 9 August 2013. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "KENKEY". Ghanaweb. Retrieved 9 August 2013.