Khasso tàbí Xaaso jẹ́ ìjọba kan ní Ìwọòrùn Áfíríkà láàrin ọdún ṣẹ́ńtúrì kẹtàdínlógún sí ọ̀kàndínlógún, ó wà níbi tí Senegal àti agbègbè Kayes ti Mali nísinsìnyí. Ní bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, ó jẹ́ apá àgbègbè Serer.[1] Láàrin ṣẹ́ńtúrì kẹtàdínlógún sí ọ̀kàndínlógún, Òun ni Olú-ìlú Medina títí di ìgbà tí wọ́n fi ṣubú.

Ó wà ní ẹgbẹ́ Odò Senegal, àwọn Fulas[2] tún wà ní ara àwọn ìjọba Khasso local Malinké àti Soninké. Séga Doua (ó jọba láàrin 1681 sí 1725) ni Fankamala (ọba) Khasso àkọ́kọ́. Nítorí ogun abẹ́lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn ọmọ rẹ̀ Dibba Samballa àti Demba Maddy, ìjọba náà pín sí márùn-ún, èyí tó lágbára jù láàrin wọn ni Dembaya lábẹ́ ìjọba Hawa Demba Diallo (ó jọba láàrín ọdún 1810 sí 1833).


Ní ọdún 1857, Toucouleur El Hadj Umar Tall kógún wọ Khasso gẹ́gẹ́ bi ara jihad, ṣùgbọ́n wọ́n dojú ogun padà ko wọ́n ní Medina Fort pẹ̀lú àwọn Fransi, pàápàá jùlọ Louis Faidherbe. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n sì ń kógún wọ Khasso títí tí wọ́n fi wọ́n fi borí àwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n sì dà wọ́n pò mọ́ French Sudan ní ọdún 1880.

Àwọn tí ó ń gbé ní ibẹ̀ láyé ìsinsìnyí ń pe ara wọn ní Khassonké.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Gravrand, Henry, "La Civilisation Sereer - Pangool", vol.2, Les Nouvelles Editions Africaines du Senegal, 1990. p 10, ISBN 2-7236-1055-1
  2. In Faransé: Peuls; in Àdàkọ:Lang-ff.