Kikelomo Longe
Kíkẹ́lọmọ Longẹ ni Kọmíṣánna fún Oko-owo àti Ile Iṣẹ́ ni akoko yii ní Ipinle Ogun . [1]
Ìbẹ̀rẹ̀ Igbesi ayé àti ẹ̀kọ́
àtúnṣeKíkẹ́lọmọ Longẹ jẹ́ ọmọ bíbí ìjọba ibilẹ Gusu Abeokuta. Ó kẹkọ nipa Isiro Owo ni ile ẹkọ giga Yunifasiti Ìlú Eko. Ó si di Komiṣana fun Oko-owo ati Ile Iṣẹ ni ipinlẹ Ogun nigbati Gomina Dapo Abiodun pe e wale lati Ilu Ọba (United Kingdom)[2]
Iṣẹ
àtúnṣeKíkẹ́lọmọ Longẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ olórí ẹ̀ka ti o n bojuto idokowo ati àkóso inawo ni ile iṣẹ African Capital Alliance (ACA)[3]. O darapọ mó ile iṣẹ naa ni ọdun 1999 o si ni igbega titi o fi di igbakeji Aare. Oun ni o ni ojuṣe fun ohun gbogbo ti o jẹ mo itaja, ikowojo ati idokowo ni ile iṣẹ naa