Kiki Mordi

Nkiru "Kiki" Mordi jẹ akọroyin oniwadii ọmọ orilẹede Naijiria, okunrin oniroyin, onifiimu, onkowe ati otaja.

Kiki Mordi (ọjọ́-ìbí: ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹjọ ọdún 1991) jẹ́ oníròyìn, agbóhùnsáfẹ́fẹ́, Òṣèrébìnrin àti oǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó gbà ẹ̀bùn agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó tayọ julọ ni apá ìwọ gúúsù ní Nigerian Broadcasters Merit Awards ni ọdún 2016. [1]

Kiki Mordi
Ọjọ́ìbí12 Oṣù Kẹjọ 1991 (1991-08-12) (ọmọ ọdún 32)
Port Harcourt, Rivers State, Nigeria
Iṣẹ́Oniroyin,Agbóhùnsáfẹ́fẹ́, Òṣèrébìnrin àti Oǹkọ̀wé
WebsiteOfficial website

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Mordi sì ìlú Port Harcourt, Rivers State ní ìpínlè Nàìjíríà.[2] Lẹ́yìn ikú bàbá rè, ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of Nigeria, Nsukka láti kà ìwé imọ ogún ṣùgbọ́n ó kúrò láì parí nítorí ìyọnu ibalopo tí ó rí láti ọwọ ìkan lára àwọn olùkọ́ rẹ.[3][4]

Ìṣe àtúnṣe

Kiki jẹ́ oniroyin,agbóhùnsáfẹ́fẹ́, osere ati onkọ̀we ni ìlú Nàìjíríà. Òun sì ní ojú oniroyin fún BBC, òun pẹ̀lú sì ni olórí adari ètò fún WFM 91.7 . Ní ọdún 2017, ó bèèrè fún idà dúró iyanje àwọn Ọlọpa èyí tí ó wáyé leyin ìgbà tí àwọn Ọlọpa kò òhun àti olólùfẹ́ rè, tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn pé wọn ṣe ẹgbẹ́ òkùnkùn.[5]

Ní ọdún 2015, wọn fà kalẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yán tí ọjọ́ ọ̀la rẹ dára julọ fún àwọn ọ̀dọ́mọdẹ́ oniroyin ni Nigerian Broadcasters Merit Awards.[6] Ní ọdún 2016, ó gbà ẹ̀bùn agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó tayọ julọ ni ìwọ gúúsù ní Nigerian Broadcasters Merit Awards. Wọn fà kalẹ fún agbóhùnsáfẹ́fẹ́ obìnrin ni Scream All-Youth Awards.[7] Ní ọjọ́ kẹta oṣù kọkànlá ọdún 2019, wọn fà kalẹ fún Ẹ̀bùn ọjọ́ iwájú tí ilẹ́ Áfríkà fún àyè àwọn oniroyin.[8] Ó sé fíìmù Life at the Bay ni ìlú Èkó ni ọdún 2019.[9][10][11]

Ó tú àṣírí àwọn olùkọ́ tí wọn fi aiyẹé ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin lára ni ọjọ keje oṣù kẹwàá ọdún 2019. Ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of Lagos àti University of Ghana ni àwọn olùkọ́ yí wá.[12] Dr. Boniface Igbeneghu tí University of Lagos, Dr Ransford Gyampo àti Dr. Paul Kwame Butako tí University of Ghana ní àwọn olùkọ́ tí àṣírí wọn tú ni aworan tí Mordi ṣe.[13][14][15][16][17] Nípa àṣírí tí Mordi tú ni ó jẹ kí wọn lé Dr. Boniface kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of Lagos, wọn tún yọ kúrò nínú ipò àlùfáà ni ilé ìjọ tí Foursquare Gospel Church.[18][19] Àṣírí yí na ni ó fà tí wọn fi tí yàrá tútù ti o wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of Lagos.[20] Olórin gbajúmò kan tí orúkọ rẹ jẹ Adekunle Gold júbà ìṣe tí Mordi ṣe.[21][22] Igbá kejì adari orile Ede Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Atiku Abubakar gba àwọn ìjọba ni ìmọ̀ràn pé kí wọn ṣe amojuto àwọn ìwà ibajẹ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga.[23][24]

Nínú ọ̀rọ̀ tí Mordi sọ fún àwọn Sahara Reporters, ó ní wípé òun ti gba àwọn ìpè lọwọ àwọn ẹ̀yán tí wọn sì sọ wí pé àwọn má ṣé ìjàmbá fún leyin igba ti o tú àṣírí náà sì ìta.[25]

Ni ọjọ́ Kẹ̀sán oṣù Kẹ̀wá ọdún 2019, Mordi àti àwọn ẹ̀yán rẹ fi fíìmù tí ó wọ wákàtí kan kalẹ. Fíìmù yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí wọn béèrè fún ibalopo lọwọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ óbirin, èyí ló tún ṣe okùnfà tí wọn ṣe dá Dr. Samuel Oladipo dúró lénu iṣẹ́ ni University of Lagos.[26] Ọjọ yí náà ni ìjọba ṣe òfin tuntun tí ó lòdì sí ibalopo olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́.[27]


Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "BEHOLD! Winners at 6th Nigerian Broadcasters Merit Awards (NBMA)". Nigerian Voice. 29 February 2016. Retrieved 8 October 2019. 
  2. "Interesting 5 facts about Kiki Mordi the sex for grade undercover journalist". Daily Times Nigeria. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  3. "Seven things you should know about Kiki Mordi". The Nation Newspaper. 9 October 2019. Retrieved 10 October 2019. 
  4. "Kiki Mordi: BBC reporter dropped out of school over sexual harassment (Video)". Within Nigeria. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  5. "KIKI MORDI'S "END POLICE EXTORTION NOW"  PETITION GETS 1,000 SIGNATURES". Women of Rubies. 10 February 2017. Retrieved 8 October 2019. 
  6. "Here Are Nominees’ Numbers For Voting at NBMA 2015". Glamtush. 29 January 2016. Archived from the original on 8 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  7. "D'banj, Linda Ikeji, Don Jazzy grab Scream All Youth Awards 2016 nomination". Nigerian Entertainment Today. 13 October 2016. Retrieved 8 October 2019. 
  8. "D'banj, Linda Ikeji, Don Jazzy grab Scream All Youth Awards 2016 nomination". Nigerian Entertainment Today. 13 October 2016. Retrieved 8 October 2019. 
  9. "The Trailer For the documentary film ’Life at the Bay’ looks rather promising". YNaija. 18 February 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  10. "Documentary By Kiki Mordi And Nora Awolowo, "Life at the Bay" Selected By Real Time Film Festival". Station Magazine. 17 May 2019. Archived from the original on 8 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  11. "Here's the Full List of Films Selected for AFRIFF 2019". BellaNaija. 9 October 2019. Retrieved 11 October 2019. 
  12. "'Sex for grades': Undercover in West African universities". BBC News. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  13. "Sex For Marks: BBC Releases Faces Of Lecturers Sexually Harassing Students In UNILAG, Legon". Sahara Reporters. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  14. "UNILAG lecturer caught in sex-for-grade scandal". Punch Newspapers. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  15. "Nigerians react to BBC exposé on African lecturers in #SexForGrades". Pulse NG. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  16. "BBC Exposes Sexual Harassment at West African Universities". Organized Crime and Corruption Reporting Project. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  17. "#SexForGrades: Ghanaian lecturer threatens to sue". Punch Newspapers. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  18. "UNILAG suspends Dr Boniface, lecturer caught on video sexually harassing 'admission seeker'". Premium Times Nigeria. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  19. "UNILAG, Foursquare Suspend Lecturer Filmed Demanding Sex From Student". Sahara Reporters. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  20. "BREAKING: #SexForGrades: UNILAG shuts down 'Cold Room', where lecturers 'sexually harass' students". Premium Times Nigeria. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  21. "Simi & Adekunle Gold Hail BBC Journalist, Kiki Mordi For Exposing University Lecturers in New Documentary". tooXclusive. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  22. "Nigerians praise BBC reporter, Kiki Mordi, over #SexForGrades documentary". QED.NG. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  23. "Atiku Calls For Action Against Sexual Harassment in Universities". Sahara Reporters. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  24. "#SexForGrades: Revisit Sexual Harassment Bill, Saraki Urges Buhari, Senate". Sahara Reporters. 7 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  25. "EXCLUSIVE: Sex-for-grades: I Have Received Threats Since Undercover Investigation, Says BBC Journalist Kiki Mordi". Sahara Reporters. 7 October 2019. Archived from the original on 8 October 2019. Retrieved 8 October 2019. 
  26. "Sex-for-admission: UNILAG suspends another lecturer, Dr Oladipo, caught in BBC video". The Sun Nigeria. 8 October 2019. Retrieved 9 October 2019. 
  27. "Senate re-introduces anti-sexual harassment bill". Premium Times Nigeria. 9 October 2019. Retrieved 9 October 2019.