Killie Campbell
Killie Campbell | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Margaret Roach Campbell 9 Oṣù Kẹ̀sán 1881 Mount Edgecombe |
Aláìsí | 28 September 1965 Durban | (ọmọ ọdún 84)
Iṣẹ́ | Collector of Africana |
Dokita Margaret Roach 'Killie' Campbell (tí wọ́n bí ní ọdún 1881 tó sì ṣàláìsí ní ọdún 1965) jẹ́ olùṣàtójọ àwọn ohun ìṣẹ̀m̀báyé ilẹ̀ Africa. Ó fún University of Natal ní awọn àkójọ rẹ̀, tó ti wá di Killie Campbell Africana Library báyìí.[1] Campbell jẹ́ ọmọbìnrin kejì ti olóṣèlú Natal àti Sir Marshall Campbell .
Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeÓ kàwé ní St. Anne's Diocesan College ní Hilton, KwaZulu-Natal àti ní St. Leonard's School ní ìlú Scotland.
Àwọn iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeNí ọdún 1939 Killie sọ ọ́ di mímọ̀ pẹ́, “Àkójọpọ̀ àwọn ohun ìṣẹ̀m̀báyé òun dá́ lórí àwọn ìwẹ́-ìrìn àjọ̀ ọjọ́ pípẹ́, ìwé lórí ìtàn, ìtàn ìgbésíayé àwọn ènìyàn, àti àwọn ìtàn àtijọ́.” Nígbà tí ó ń ṣe àpejúwe àwọn àkójọpọ̀ rẹ̀ nínú àyọkà tí wọ́n ṣàtẹ̀jáde ní oṣù kẹsàn-án ọdún 1945, ó kọ pé, “Yàrá ìkàwé náà ní tó ìwé ọ̀kẹ́ kan (20,000), mo sì ti ṣiṣẹ́ pàtàkì lórí ìtàn Bantu." [2]
Ìdá́lọ́lá àti àwọn àṣesílẹ̀ rẹ̀
àtúnṣeUniversity of Natal fún Campbell ní àmì-ẹ̀yẹ ní ọdún 1950, bẹ́ẹ̀ sì ni University of Witwatersrand fún ni àmì-ẹ̀yẹ ní ọdún 1954. Ó sì tún gba àmì-ẹ̀yẹ láti jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ ní South African Library Association ní ọdún 1958. City of Durban fun ní àmì-ẹ̀yẹ ní ọdún 1964. [2]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Campbell 2000, p. 269-.
- ↑ 2.0 2.1 Duggan 1981.