KWERE

Kuwere

ÀÀYÈ WỌN

	Wọ́n wà ní apa ìwọ-oòrun ààrin gbuǹgbùn Tanzania.

IYE WỌN

Wọn lè ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́ta eǹìyàn

ÈDÈ WỌN

Èdè kikwer (ti Bàǹtú ni wọ́n ń sọ

ALÁBÀÁGBÉ

Zaramọ, Doe, Zingna, Luguru àti Swahili.

ÌTAǸ WỌN

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣẹ́yìn ni baba ńlá Kwere de láti Mozanbique.Nínú ìrìn-àjò wọn ni wọ́n ti bá àwọn eǹìyaǹ Swahili tí wọn di mùslùmí pàdé wọn fìdí tì sí ibẹ̀ pẹ̀lu àwọn alábàágbè wọn bí Zeramo ati Doe

ÌṢẸ̀LÚ WỌN

Àwọn Kwere ò ni ìjọba àpapọ̀ Ijọba ìletò,ijọba abúlé àti ìjọba ìlú-síluń ní wọ́n ní Àgbà àdúgbò ló ń fi olórí jẹ. Olórí ló ní aṣẹ ilè ìran. Òun si ni ètùtù ìlu wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Ọkúnrin ni olórí sáábà ń jẹ́. òun ló ń pàrí ìjà láàrin ẹbi. Agbára ńlá, ọwọ́ rẹ̀ ló wà . Òun náà ló ni agbára tí a fi ń bá èmi àìrí sọ̀rọ̀.

ỌRỌ̀ AJÉ WỌN

Àgbẹ̀ paraku ni wọ́n. Wọ́n ń gbinsu, gbìngẹ̀, gbìngbàdo. Wọ́n ń gbin òwú àti tábá. wọ́n ń sin ẹranko àti ẹyẹ wọn a sì tún máa ṣe ọ̀sin eja.

IṢẸ̀ ỌNA WỌN

	Awọn KWERE máa ń gbéji rèbété. 

Ẹ̀sìn WỌN

Kwere gba ọlọ́run ńla (MuLUNGU) gbọ́ ọlọ́run ỳí ló ń ròjò ìdíle kọ̀ọ̀kan ló ní òrìṣà tí wọn ń kè pè. Wọ́n gbà pé ọlọ́run nla] ń ran àrùn àti òfò sí wọn. Òkú ọ̀run ló ń gbè ẹ̀bẹ̀ wọn lọ aí ọ̀dọ̀ ọlọ́run ńlá wọn. Òrìṣà-ló ń wo ọjọ́ iwájú fún wọṅ ni MGANGA. Òun ní í sọ ọ̀nà abayọ sí àdánwò tó bà dé bá wọn.