Kwaito
Kwaito jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà orin tó jáde láti Soweto, Johannesburg, ní South Africa, láàárín ọdún 1980 àti 1990. Ó jẹ́ orin tí ó máa ń ní àdàpọ̀ orin ilẹ̀ Africa, tí ó sì máa ń lo àọn ohun èlò orin ilè Africa. Àwọn orin Kwaito máa ń lọ wérẹ́wẹ́rẹ́ ni.
Orísun
àtúnṣeKwaito jẹyọ láti inú "kwaai," tó jẹ́ àṣamọ̀ ilẹ̀ South Africa, tó túmọ̀ sí "wọ́rọ́rọ́" tàbí "burúkú". "Kwaai" fúnra rẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ Afrikaans, tí ó túmọ̀ sí "ìbínú" tàbí "ìgbóná." Àmọ́, ìlò rẹ̀ yàtọ̀ gedegbe sí tí àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ South Africa.[1][2]
Ìtàn
àtúnṣeKwaito jẹyọ láti South Africa gẹ́gẹ́ bí i irúfẹ́ orin kíkọ ní òpin ọdún 1980 wọ ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1990,[3] tí ó sì tàn kálẹ̀ ilẹ̀ náà. Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ní àwọn ìlú kéréje ò ní àǹfàànih láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀kọ́ orin, èyí tó máa jẹ́ kí ìgbẹ̀kọ́ wọn yàtọ̀, tí ó sì ma fún àọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní irírí orin kíkọ. Kòpẹ́ rẹ̀ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní gba irinṣẹ́ lóríṣiríṣi láti maa fi kọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ àọn irinṣẹ́ yìí ò tó rárá, èyí sì jẹ́ ìpènija gidi fún wọn.
Àwọn agbátẹrù orin àti títa orin
àtúnṣeÀwọn agabátẹru orin kó ipa ribiribi nínú ìlọsíwájú ẹ̀yá orin yìí, lára wọn ni M'du, Arthur Mafokate, Spikiri, Don Laka, Sandy B, Oskido, Rudeboy Paul, Dope, Sanza àti Sello Chicco Twala. Spikiri, ṣe àtúnṣe bí kwaito ṣe ń dún létí, nípa fífí àwọn irinṣẹ́ ìgbàlódé kún orin náà. Sello Chicco Twala, ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olórin kwaito. Mdu Masilela bákan náà kọ ipa, látàrí àhunpọ̀ orin aládùn mọ́ orin kwaito.[4][5] Lásìkò tí orin náà bẹ̀rẹ̀, kwaito tan kálẹ̀ káàkiri ilẹ̀ South Africa. Àwọn olórin bí i Mandoza, Arthur Mafokate, and àti Boom Shaka rí àwọn àwo-orin wọn ta gan-an, èyí tó tún mú kí èyà orin náà túnbọ̀ gbajúmọ̀ si.[6][7][8]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Anonymous (2011-03-22). "Kwaito". South African History Online. http://www.sahistory.org.za/article/kwaito.
- ↑ "Kwaito woeker tog te lekker met Afrikaans" (in en). Netwerk24. https://www.netwerk24.com/Nuus/Algemeen/kwaito-woeker-tog-te-lekker-met-afrikaans-20171008.
- ↑ Steingo, Gavin (2008). "Historicizing Kwaito". University of Rhodes (International Library of African Music) 8 (2): 76–91. JSTOR 30250016. https://www.jstor.org/stable/30250016. Retrieved 14 December 2023.
- ↑ "Kwaito pioneers to be honoured". 13 April 2015. https://www.herald.co.zw/kwaito-pioneers-to-be-honoured/.
- ↑ Steingo, Gavin (2016-06-15) (in en). Kwaito's Promise: Music and the Aesthetics of Freedom in South Africa. University of Chicago Press. ISBN 978-0-226-36268-7.
- ↑ (in en) Billboard. Nielsen Business Media, Inc.. 1998-04-04. https://books.google.com/books?id=ug4EAAAAMBAJ&dq=kwaito+record+sales&pg=PA33. Retrieved 8 August 2024.
- ↑ Steingo, Gavin (2016-06-15) (in en). Kwaito's Promise: Music and the Aesthetics of Freedom in South Africa. University of Chicago Press. ISBN 978-0-226-36254-0.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:0