Lítíréso alohun
Litireso alóhùn
Litireso alóhùn ni àwọn ewì atenudenu tí a jogun láti enu àwọn bàbà ńlá wa.
Ohùn ẹnu ni a fi ń gbé litireso jáde, a kii kọ sílẹ̀ rara.
Litireso alohun kún fún ọgbọ́n ìmò àti òye àgbà , nígbà tí ìmọ mọọ - kọ mọọ - ka kò tíì dé ilẹ̀ wa, oun ni àwọn baba ńlá wa ń lò.
Litireso alohun pin si ona meta
a. Ewì
b. Ọ̀rọ̀ geere
D. Ere Oníṣe.
awon ewi alohun Yoruba ni,
- Ofo
- Oriki
- Ese-ifa
- Ayajo
- Ogede abbl.
Ewi je akojopo oro ijinle ti o kun fun ogbon, imo ati oye.
Ese-ifa: O je amu fun ogbon, imo ati oye awon Yoruba. Ọrunmila ni orisa awon onifa.
Ofo: Ofo je awon oro ti a n so jade ti a fi n segba leyin oogun tabi ti a n pe lati mu ero okan wa se.
Ayajo: inu ese-ifa ni a ti mu ayajo jade. Oro enu lasan ni ko nilo oogun bii ti ofo.
Ogede: Ohun enu ti o lagbara ju ohun enu lo ni ogede. Eni ti o ba fe pe ogede gbodo bii ero ki o to le pe ogede bee ni yoo ni ohun ti yoo to le bi o be ti pee tan.
Oriki: Yorùbá n lo oriki fun iwin a ni oriki oruko, oriki orike, oriki boro kinni, oriki idile abbl.