Lẹ́tà Àìgbẹ̀fẹ̀
Lẹ́tà àìgbẹ̀fẹ̀ ni oríṣi lẹ́tà kejì tí a ma ń kọ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ àdáni tàbí ti ìjọba, yálà nígbà tí a bá ń wáṣẹ́ tàbí fẹ́ gba ohun kan tàbí òmíràn ní ọwọ́ irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀. Ó fi han wípé irúfẹ́ ènìyàn yí kò ní ra ye láti ma ka ìtàn tàbí ka yẹ̀yẹ́ tàbí àwàdà èyíkéyí, nítorí iṣẹ́ wọ́n pọ̀ ju àwọn nka wọ̀nyí lọ. Fúndí èyí ṣókí lọbẹ̀ oge lọ̀rọ̀ inú lẹ́tà yí. . Àwọn ènìyàn yí lè jẹ́ Ọ̀gá àgbà, Olóòtú àgbà, ọ́gá Ọlọ́pá, Gómìnà, Ààrẹ orílẹ̀-èdè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. [1]
Àwọn ohun tí ó wà nínú lẹ́tà àìgbẹ̀fẹ̀ ni
àtúnṣeÀdírẹ́sì mèjì èyíọ̀kan la pa ọ̀tún, ọ̀kan lósì. Èyí tí yóò wà ní apá ọ̀tún yóò jẹ́ ti olùkọ lẹ́tà, tí èyí tí yòó wà ní apá òsì yóò jẹ́ àdírẹ́sì ẹni tí ó fẹ́ gba lẹtà ká. Àpẹẹrẹ:
Ojúlé Kẹwàá, Òpópónà Kalẹ̀jayé, Òṣogbo, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. 23 May,2017.[2]
Adarí Àgbà, Ilé-iṣẹ́ Ìkà lejò, Ojúlé Kejì, Ìpínlẹ̀ Èkó
Ọ̀gá Àgbà, --------- Ìkíni
Ìfáàrà : : Ìkọ̀wé wáṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alámòójútó ilé ónjẹ tàbí ÌKỌ̀WÉ WÁṢẸ́ GẸ́GẸ́ BÍ ALÁMÒÓJÚTÓ ILÉ ÓNJẸ
Lẹ́yìn Ìfáàrà ni olùkọ lẹ́ta yóò sè bí ó ti jẹ́ tí yóò sì ṣàlàyé ohun tí ó torí rẹ̀ kọ lẹ́tà náà ní ṣókí. Lẹ́yìn èyí ni ó kan ìkádí tí ó dúro fún opin lẹ́tà rẹ̀. Oní lẹ́tà yóò kádí rẹ̀ báyí:
Ẹ ṣeun pọ́pọ̀, Lódodo, tàbí temi ni ti yin tòó tọ́, Dáre Amújó.
Yóò wá sign sí abẹ́ orúkọ rẹ̀.
Àwọn àkíyèsí pàtàkì
àtúnṣeLẹ́tà àìgbẹ̀fẹ̀ ní àdírẹ́sì méjì, àdírẹ́sì Olóòró ni a gbọ́dò lò'. Gbogbo ìparí ọ̀rọ̀ nínú àdírẹ́sì ni ó gbọ́dọ̀ àwọn àmì ìdánu dúro diẹ̀ àti ìdáná-dúro pátá pátá. Ìfáàrà tí ó ń tọ́ka ohun tí a fẹ́ kí wọ́n ṣe fún wa gbọdọ̀ dá dúro.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Example of a formal letter". Speak English. Retrieved 2020-02-07.
- ↑ ENGLISH<, SPM; Gill, Jugdeep Kaur (1970-01-01). "Writing a formal letter". The Star Online. Retrieved 2020-02-07.
- ↑ Lab, Purdue Writing (2018-11-02). "The Basic Business Letter // Purdue Writing Lab". Purdue Writing Lab. Retrieved 2020-02-07.