Laide Bakare
Laide Bakare tí wọ́n bí ní Ọjọ́ keje oṣù kẹwàá ọdún 1980 (7th October 1980) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré, olóòtú àti oníṣòwò ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [1]
Laide Bakare | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 7th October 1980 |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Ifáfitì Ìbàdàn |
Iṣẹ́ | òṣèré . olóòtú |
Ìgbà iṣẹ́ | 1999 - till present |
Notable work | Jẹjẹrẹ |
Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀
àtúnṣeGẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, Láídé Bákàrè jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní Nàìjíríà. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ gírámà rẹ̀, Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ Ìtàn àti ẹ̀kọ́ nípa ète (History and Strategic Studies) ní Ifáfitì ìjọba Àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú Èkó. Bákan náà, ó kàwé gbàwé ẹ̀rí Dípólómà nínú ìmọ̀ iṣẹ́ Tíátà ní Ifáfitì Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Iṣẹ́ tíátà rẹ̀
àtúnṣeLáídé bẹ̀rẹ̀ sí ní nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò nígbà tí àwọn oníṣẹ́ tíátà máa wá ń lo ilé ìtura bàbá rẹ̀ fún sinimá àgbéléwò. Bàbá rẹ̀ jẹ́ pàràkòyí oníṣòwò tí ó ní ilé-ìtura tó lẹ́wà. Láídé bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 1999 nígbà tí ó kópa nínú sinimá àgbéléwò kan tí Muka Ray kọ tí àkọ́lé rẹ̀ ń "Adéyẹmí". Lẹ́yìn ìgbà náà, ó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó ju àádọ́ta lọ.
Àtòjọ díè nínú àwọn sinimá-àgbéléwò tí ó ti kópa
àtúnṣe- Jẹjẹrẹ
- Ẹnu Ọpẹ́ mi
- Money Bag
- Orí owó
- Òkun ọmọ ìyá
- Ọrẹ mẹta
- Àṣírí owó [2]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Laide Bakare Biography: Age, Family & Pictures". 360dopes. 2018-07-10. Retrieved 2020-02-18.
- ↑ [/laide-bakare-biography-profile-fabwoman/ "Laide Bakare Biography - Profile"] Check
|url=
value (help). FabWoman | News, Style, Living Content For The Nigerian Woman. 2018-10-08. Retrieved 2020-02-18.