Lamu tàbí Ìlú Lamu jẹ́ ìlú kékeré ni erékùṣù Lamu, tí o jẹ́ apá kan lára Lamu Archipelago ni Kenya. Ó wà ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà 341 (212 mi) ní ojú ọ̀nà ilá-oòrùn àríwá tí Mombasa ó sì parí sí èbúté Mokowe, níbi tí a níláti gba ọ̀sà kọjá lọ sí Erékùṣù Lamu. Òun ni Olú iléeṣẹ́ àgbègbè Lamu àti Ibùdó Ohun Àjogúnbá Àgbáyé ti UNESCO.

Ilé agbára Lamu tó wá níwájú ọ̀sà tí wọ́n kọ lásìkò Fumo Madi Ibn Abi Bakr, Sultan ti Pate, tí wọ́n parí lẹ́yìn ikú rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ 1820s. Mọ́ṣáláṣí mẹ́tàlélógún, pẹ̀lú Mọ́ṣáláṣí Riyadha tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1900 àti ibùgbé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ló wà ní ìlú náà.

Ìtàn ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀

àtúnṣe

Ojúlówó orúkọ ìlú náà ni Amu, èyí tí àwọn Áráàbù pé ní Al - Amu tí àwọn Pọ́tugí pè ní "Lamon". Àwọn Pọ́tugíl lo orúkọ yìí fún àpapọ̀ erékùsù torí pé Amu ni olú ibùdó.

Ojúlówó orúkọ ìlú náà ni Amu, èyí tí àwọn Áráàbù pé ní Al - Amu tí àwọn Pọ́tugí pè ní "Lamon". Àwọn Pọ́tugíl lo orúkọ yìí fún àpapọ̀ erékùsù torí pé Amu ni olú ibùdó.

Ìlú Lamu ní erékùṣù Lamu ni ìlú Kenya tí ó tí wá tipẹ́, tí o sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ojúlówó ibùdó Swahili ni Ilà oòrùn Adúláwọ̀. A gbàgbọ́ pé wọ́n da sílẹ̀ ni 1370.

Lóde òní, Mùsùlùmí ni púpọ̀ nínú àwọn olùgbé Lamu.