Lér̀e Pàímọ́, OFR ni wọ́n bí ní oṣu November, ọdún 1939. Ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti òṣèré orí-ìtàgé, olù-kọ̀tàn eré orí-ìtàgé àti adarí eré orí-ìtàgé.[1]

Lérè Pàímọ́
Ọjọ́ìbí(1939-11-19)19 Oṣù Kọkànlá 1939
Ògbómọ̀ṣọ́, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Nàìjíríà.
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Orúkọ mírànẸ̀dá Onílé-Ọlá
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́
  • Òṣèré
  • Olùgbéré-jáde
  • producer
  • Alásopọ̀ eré
Ìgbà iṣẹ́1960–present
AwardsMFR

Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Lérè Pàímọ́ ní ọdùn  1939 ní ìlú Ògbómọ̀sọ́, tí ó jẹ́ ìlú ńlá kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ilẹ̀ Nàìjíríà.[2]

Ìṣẹ́ rẹ̀ gẹ̀gẹ̀ bí Òṣẹ̀ré àtúnṣe

 Ó bẹ̀rẹ̀ ere orí-̀tàgé ní ọdún  1960 nígbà tí ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré Oyin Adéjọbí, iye egbe osere ti Pa Oyin Adejobi  dá sílẹ̀ ṣáájú kí ó tó tún dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré lẹ́yìn Dúró Ládípọ̀ ní bi tí ó ti kópa nínú eré "Ọbamoro"  gẹ́gẹ́ bí  "Olóyè Basà".[3]  Ó di ìlú mọ̀ọ́kà nígbà tí ó kópa gẹ́gẹ́ bí olú ẹ̀dá ìtàn nínú eré ìtàgé Ògbórí Ẹlẹ́mọ̀ṣó gẹ́gẹ́ bí " Ṣ̀oún Ogunọlá" , eré yìí ni ó sọọ́ di gbajú-gbajà òṣèré orí-ìtàgé ní àwùjọ àwọn òṣèré Yorùbá . lẹ́yìn èyí, ó ti kópa nínú onírúurú eré sinimá lóríṣi riṣi, bakan naa ni ó ti gbé eré oríṣi ríṣi jáde tí ó sì tún ti darí ọ̀pọ̀ eré tí ó di sininmá àgbélé wò lóǹìi ní ilẹ̀ Nàìjíríà. .[4] Ní ọdún 2005, Ààrẹ Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ fi àmì ẹ̀yẹ ìdáni lọ́là ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kan dáa lọ́lá tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́  Member of the Federal Republic fún iṣé takun tatun rẹ̀ ní àwùjọ àwọn òṣèré ilẹ̀ Nàìjíŕíà òun pẹ̀lú elòmíràn tí ó ń jẹ́ Zeb Ejiro .[5][6] Ní May  2013,wọ́n jábò rẹ̀ wípé ọ̀gḅ́eni Lérè Pàímọ́ ní àrùn rọpá-rọsè kékéré kan tí ó sì ti gbádùn lẹ́yìn àìsàn adánigúnlẹ̀ ọ̀hún .[7] Ní oṣù April 2014,Ó jẹ ẹ̀bùn Mílíọ́nù kan Náírà nínú ìdíje orí ẹ̀rọ àgbélé-wò tí a mọ̀ sí "Who Wants To Be A Millionaire"[8]

Awon itoka si àtúnṣe