Letitia Michelle Wright (tí a bí ní ọjọ́ kàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹ̀wá ọdún 1993) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Guyana mọ́ Britain. Ó bẹ̀rẹ̀ isẹ́ òṣèré pẹ̀lú àwọn fíìmù bi Top Boy, Coming Up, Chasing Shadows, Humans, Doctor Who, àti Black Mirror. Wọ́n yàn sí ara àwọn tí ó tó sí àmì-ẹ̀yẹ Primetime Emmy Award. Ó di gbajúmọ̀ nígbà tí ó ṣeré nínú fíìmù Urban Hymn tí ó jáde ní ọdún 2015,[1] èyí tí ó sì gba àmì ẹyẹ British Academy of Film and Television Arts (BAFTA) fún.

Letitia Wright
Wright ní ayẹyẹ ìsí fíìmù Black Panther: Wakanda Forever ní ọdún 2022
Ọjọ́ìbíLetitia Michelle Wright
31 Oṣù Kẹ̀wá 1993 (1993-10-31) (ọmọ ọdún 31)
Georgetown, Guyana
Ẹ̀kọ́Northumberland Park Community School
Identity School of Acting
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́2011–present
Notable workBlack Panther (2018)

Ní ọdún 2018, ó di gbajúmọ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè nígbà tí ó kó ipa Shuri nínú fíìmù Marvel Cinematic Universe, Black Panther, èyí tí ó sì gba àmì ẹyẹ NAACP Image Award àti SAG Award fún. Ó tún kó ipa náà nínú fíìmù Avengers: Infinity War (2018), Avengers: Endgame (2019), àti Black Panther: Wakanda Forever (2022). Ní ọdún 2019, ó gba àmì-ẹ̀yẹ BAFTA Rising Star Award. Ó tún kó ipa nínú Small Axe, èyí tí ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ Satellite Award fún.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "BAFTA and Burberry Reveal 2015 Breakthrough Brits" Archived 29 June 2018 at the Wayback Machine.. BAFTA.org, 10 November 2015. Retrieved 22 February 2018.