Levi Chibuike Ajuonuma
Levi Chibuike Ajuonuma (tí a bí ní ọjọ́ kejì oṣù kejìlá, ọdún 1959, tí ó sì kú ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹfà, ọdún 2012), tí a mọ̀ sí Livi, jẹ́ ọ̀mọ̀wé Naijiria. O fìgbà kan jẹ́ sọrọ̀sọ̀rọ̀ lórí rédíò àti lórí ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán. Ó sì gbajúgbajà fún ètò rẹ̀ ní alaalẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Open House Party" lórí Raypower 100.5FM. Ajuonuma tún ti ṣiṣẹ́ ní Nigerian Television Authority(NTA) àti àwọn ìkànní mìíràn, níbi tí ó ti jẹ́ olóòtú àti olùdarí The Sunday Show, Showtime àti Levi Ajuonuma Live . [1] [2]
Levi Chibuike Ajuonuma | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 2 Oṣù Kejìlá 1959 Enugu State |
Aláìsí | Lagos State |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Huntington College, Indiana University of Minnesota Plymouth State College |
Iṣẹ́ | Media professional, broadcaster |
Employer | NNPC |
Olólùfẹ́ | Josephine Ajuonuma |
Àwọn ọmọ | DJ Obi, Amy (MIMI), |
Ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeỌmọ bíbí ìlú Ideato South ní ipinle Imo ni Ajuonuma ti wá, ṣùgbọ́n ìlú Enugu ni wọ́n bí sí, ibẹ̀ ló sì wà títí tó fi dàgbà, tó sì ti kọ́ ẹ̀kọ́ alàkọ̀ọ́bẹ̀rẹ́. Ó lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1979 láti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì gboyè BA ní Ìbánisọ̀rọ̀ láti Huntington college, Indiana àti M. A pẹ̀lú PhD ni Mass Communications láti University of Minnesota ní ọdún 1983 àti 1987; ó sì tún gboyè MBA láti Plymouth State University ní ọdún 1989. [1]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeAjuonuma bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí rédíò ní ọdún 1977 pẹ̀lú Imo Broadcasting Service (IBS) ní Owerri Ipinle Imo. Ó kúrò ní Nàìjíríà láti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Mass Communications ní United States, níbi tó ti jáde pẹ̀lú BA, MA àti PhD. Ṣáájú kí ó tó padà sí Nàìjíríà, lẹ́yìn àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ìlú America, Ajuonuma ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́ ní ẹ̀ka ìwé-ìròyìn Keene State College of the University System of New Hampshire. [1] Ó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ rẹ̀ tesiwaju nínú ìgbéròyìnsáfẹ́fẹ́ àti olùgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní oríṣiríṣi àwọn ilé-iṣẹ́ rédíò àti tv ní Nàìjíríà. Lẹ́yìn náà, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi alákòóso gbogboogbò fún Corporate Affairs of the Nigerian National Petroleum Corporation (NNPC) níbi tó wà títí tó fi kú.
Igbesi aye ara ẹni
àtúnṣeAjuonuma ní ìyàwó, orúkọ rẹ̀ sì ni Josephine Ajuonuma tí wọ́n sì jọ bímọ méjì papọ̀. [3]
Ikú rẹ̀
àtúnṣeAjuonuma jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ NNPC mẹ́rin tó sọ ẹ̀mí wọ́n nù ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹfà ọdún 2012 nínú ìjàmbá oko ofurufu Dana Air 992 ní Iju-Ishaga ní ipinle Eko. [4] Minisita tó ń rí sí ọ̀rọ̀ epo ní Nàìjíríà nígbà kan rí, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́, Diezani Alison-Madueke wá síbi ayẹyẹ ìsìnkú tí wọ́n ṣe láti fi yẹ́ ẹ sí. [5] [3] Wọ́n sin Ajuonuma sí ìlú abínibí rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Imo. [3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 1.2 Obasi, Sebastine (3 June 2013). "Remembering Levi Ajuonuma". Vanguard Newspaper. https://www.vanguardngr.com/2013/06/remembering-levi-ajuonuma/. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; name "auto1" defined multiple times with different content - ↑ Owubokiri, John (3 July 2012). "DR. LEVI AJUONUMA: Last cocktails and a final OTC". Vanguard Newspaper. https://www.vanguardngr.com/2012/07/dr-levi-ajuonuma-last-cocktails-and-a-final-otc/.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 "The burial of Late Levi Ajuonuma". Channels TV (Channels TV). 9 September 2012. https://www.channelstv.com/2012/09/24/the-burial-ceremony-of-late-levi-ajuonuma/. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; name "auto4" defined multiple times with different content - ↑ "153 Passengers, 30 Residents Killed in Dana Airline Crash". Aviation Pros. https://www.aviationpros.com/home/news/10724980/153-passengers-30-residents-killed-in-dana-airline-crash.
- ↑ "Memorial Service for Levi Ajuonuma". https://issuu.com/thenation/docs/september_14__2012/6.