Lily Banda
Lily Banda (tí wọ́n bí ní 16 Oṣù Kẹẹ̀jọ, Ọdún 1990) jẹ́ òṣèrébìnrin àti akọrin ọmọ orílẹ̀-èdè Màláwì.
Lily Banda | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 16 Oṣù Kẹjọ 1990 |
Orílẹ̀-èdè | Malawian |
Orúkọ míràn | Alex |
Iṣẹ́ | Singer, actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2014-present |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeBanda jẹ́ eni tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ní ìfẹ́ sí orin kíkọ láti ìgbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin. Nígbà tí yóó fi pé ọmọ ọdún mẹ̀fa, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kọrin níbi àwọn ayẹyẹ ní ilé-ìwé rẹ̀. Banda bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìṣe rẹ̀ ní ọdún 2010 gẹ́gẹ́ òṣìṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣọ̀nù.[1] Ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀ lábẹ lílo Alex gẹ́gẹ́ bi orúkọ ìdí-iṣẹ́ rè.[2] Banda gbé àkọ́kọ́ àpapọ̀ àwọn orin rẹ̀ jáde ní Oṣù Kíní Ọdún 2014. Ní ọdún 2015, ó yí orúkọ ìdí-iṣẹ́ rẹ̀ padà sí Lily, èyítí n ṣe orúkọ àbísọ rẹ̀.[3] Ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti African Union kan ní ọdún 2015, ó sì tún rí yíyàn fún àwọn àmì-ẹ̀yẹ ti Afrima ní ọdún 2018.[4]
Ní ọdún 2019, ó kọ orin àdákọ kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Bad at Love". Wọ́n túmọ̀ orin náà sí èdè Swàhílì tó sì jẹ́ gbígbé jáde ní Oṣù Kíní Ọdún 2020. Banda ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Alfred Ochieng àti Aliza Were láti túmọ̀ orin náà.[5]
Ní ọdún 2019, Banda kópa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Boy Who Harnessed the Wind, èyítí ó dá lóri àkọsílẹ̀ William Kamkwamba. Ó tún kópa gẹ́gẹ́ bi Aicha Konate nínu abala ẹ̀kejì ti eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Deep State ní ọdún 2019.[6] Ó kópa gẹ̀gẹ̀ bi atúmọ̀-èdè ọmọ orílẹ̀-èdè Málì kan tí àwọn kan gbìmọ̀ láti dáa lọ́nà àti láti ṣekú paá.[7]
Banda maa n ri ara fun awọn ẹtọ awọn obinrin. O ngbe ni Lilongwe. [3]
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
àtúnṣe- 2019: The Boy Who Harnessed the Wind
- 2019: Deep State (TV series)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Malawian Influencers – Lily Banda". Visit Malawi. Archived from the original on 14 October 2020. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ "TEDxLilongwe". TEDx. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ 3.0 3.1 "From Alex to Lily: Singer explains name change". Archived from the original on 14 August 2021. https://web.archive.org/web/20210814130711/https://mbc.mw/news/entertainment/item/325-from-alex-to-lily-singer-explains-name-change. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ "Lily B". Music in Africa. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ "Lily Banda Pushing the African Dream". Stories Now. 20 January 2020. Archived from the original on 30 October 2020. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ "Lily Banda Pushing the African Dream". Stories Now. 20 January 2020. Archived from the original on 30 October 2020. Retrieved 13 October 2020.
- ↑ Mtawali, Desire Elizabeth. "Malawi’s Lilly Banda finds new Acting Role". Smash MW. Archived from the original on 14 October 2020. Retrieved 13 October 2020.